Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ ó yẹ kẹ́nì kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ síbi ìgbéyàwó ìbátan tàbí ojúlùmọ̀ kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí?
Nǹkan ayọ̀ ni ìgbéyàwó jẹ́, kò sì sóhun tó burú tí Kristẹni kan bá lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó láti bá wọn yọ̀. Tí wọ́n bá pe àwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì lè dá pinnu síbi ìgbéyàwó kan, wọ́n gbọ́dọ̀ gbàṣẹ lọ́dọ̀ àwọn òbí tàbí alágbàtọ́ wọn, àwọn òbí tàbí alágbàtọ́ wọn sì ló máa pinnu bóyá kí wọ́n lọ tàbí kí wọ́n má lọ. (Éfésù 6:1-3) Àmọ́, tí ọkọ kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá sọ fún ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí pé káwọn jọ lọ síbi ìgbéyàwó kan tí wọ́n máa ṣe ní ṣọ́ọ̀ṣì ńkọ́? Tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá gbà á láyé, ó lè pinnu láti lọ kó sì wà níbẹ̀ láìbá wọn dá sí èyíkéyìí lára ààtò ìsìn tí wọ́n máa ṣe níbi ìgbéyàwó náà.
Lọ́rọ̀ kan ṣá, kálukú ló máa pinnu bóyá kóun lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tàbí kóun má lọ. Àmọ́, ó yẹ ká mọ̀ pé Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa jíhìn fún Jèhófà, ó sì yẹ ká ronú lórí àwọn ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nígbà tẹ́nìkan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá pè wá síbi ìgbéyàwó kan.
Ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì lójú ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni ni bá a ṣe máa ṣohun tínú Ọlọ́run dùn sí. Jésù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe àmúlùmálà ìgbàgbọ́ wọn pẹ̀lú ẹ̀sìn mìíràn nípasẹ̀ àdúrà gbígbà, ààtò ìsìn tàbí àwọn ayẹyẹ tó tako àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì.— 2 Kọ́ríńtì 6:14-17.
Ẹni tó bá jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ìpinnu yòówù tóun bá ṣe lè nípa lórí àwọn ẹlòmíì. Bó o bá pinnu pé wàá lọ síbi ìgbéyàwó kan, ṣáwọn ìbátan rẹ ò ní bínú pé oò bá wọn dá sáwọn ayẹyẹ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀? Ó yẹ kó o tún ronú lórí ipa tó ṣeé ṣe kí ìpinnu rẹ ní lórí àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (Róòmù 14:13) Ká tiẹ̀ wá sọ pé ìwọ tàbí àwọn aráalé rẹ gbà pé kò burú tẹ́ ẹ bá lọ síbi ìgbéyàwó ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, àmọ́ ṣé kò lè nípa tó burú lórí àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ? Ṣé kò sì ní pa ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì lára?
Ìṣòro ló máa ń jẹ́ tí ìgbéyàwó bá dà wá pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìbátan wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Tí wọ́n bá ní kó o wá bá wọn ṣe ọ̀rẹ́ ọkọ tàbí ọ̀rẹ́ ìyàwó ńkọ́? Tó o bá ní aya tàbí ọkọ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, tó sì fẹ́ kópa nínú gbogbo ètò ìgbéyàwó náà ńkọ́? Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ìjọba ni wọ́n ti fẹ́ ṣe ìgbéyàwó náà, tó sì jẹ́ pé adájọ́ tàbí òṣìṣẹ́ ìjọba kan ló máa darí rẹ̀, tó o bá lọ síbi ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀, kò burú, torí ńṣe ló kàn dà bí ìgbà téèyàn bá lọ sílé ẹjọ́ láti lọ wo bí wọ́n ṣe máa gbọ́ ẹjọ́ ẹnì kan.
Àmọ́, ó gba ìrònú gidigidi tó bá jẹ́ pé inú ilé ìjọsìn kan ni wọ́n ti fẹ́ ṣe ìgbéyàwó náà, tàbí pé àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan ló fẹ́ so ọkọ àtìyàwó pọ̀. Dípò tí wàá fi ṣohun tí kò bá ẹ̀rí ọkàn rẹ tó o ti fi Bíbélì kọ́ mu tàbí kó o ṣohun tó lòdì sí ohun tó o gbà gbọ́ tàbí kó o wá lọ ṣohun tó máa dójú ti àwọn tó ń ṣègbéyàwó, á dáa kó o kúkú má lọ síbi ìgbéyàwó náà. (Òwe 22:3) Kàkà tí wàá fi kó ara rẹ àtàwọn ìbátan rẹ sínú wàhálà, ńṣe ni kó o ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ tó dá lórí Bíbélì fún wọn ṣáájú ọjọ́ ìgbéyàwó náà, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìwọ̀n tó o lè ṣe nínú ìgbéyàwó náà tàbí kó o dábàá ohun míì tí wàá fẹ́ ṣe nínú ayẹyẹ ìgbéyàwó náà.
Lẹ́yìn táwọn Kristẹni kan bá ti fara balẹ̀ ronú lórí àwọn kókó tá a ti jíròrò yìí, wọ́n lè pinnu pé kò burú táwọn bá lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, níwọ̀n ìgbà táwọn ò bá ti lọ́wọ́ sí ààtò ìsìn èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe níbẹ̀. Àmọ́, tí Kristẹni kan bá wò ó pé lílọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà lè mù kóun ṣàwọn nǹkan tó máa tako àwọn ìlànà Ọlọ́run, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè wá rí i pé àkóbá tí lílọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà á ṣe fóun á ju àǹfààní tó ṣeé ṣe kóun jẹ níbẹ̀ lọ. Ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni sì lè yàn láti má lọ síbi ìgbéyàwó náà, àmọ́ tó bá fẹ́ lọ síbi àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu tí wọ́n máa ṣe lẹ́yìn ìgbéyàwó náà, kó ṣáà rí i pé òun “ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 10:31) Tó o bá fẹ́ pinnu ohun tí wàá ṣe, má gbàgbé pé “olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5) Ìpinnu yòówù kó o ṣe, máa rántí pé, ó ṣe pàtàkì pé ká ní ẹ̀rí ọkàn tó dáa lójú Jèhófà Ọlọ́run nígbà gbogbo.