“Kí Ni Kí N Ṣe?”
1 Gẹ́gẹ́ bí èwe kan tó ti ń dàgbà, o lè béèrè pé, ‘Kí ni kí n fi ìgbésí ayé mi ṣe?’ Àwọn èwe Kristẹni máa ń fẹ́ láti mú isẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n báwo lo ṣe fẹ́ ṣe èyí bóo ti ń ṣe àwọn ohun tó yẹ kẹ́ni tó ń dàgbà ṣe, èyí tó ní gbígbọ́ bùkátà ara rẹ nínú? Rírí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí lè má rọrùn.
2 Àwọn èwe kan máa ń ṣàníyàn nígbà tí wọ́n bá wo sàkun ipò ọrọ̀ ajé ayé, tí wọ́n sì tún ronú nípa bí ọ̀la yóò ṣe rí. Wọ́n máa ń kọminú pé: ‘Ṣé kí n kàwé sí i ni? Àbí kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lójú ẹsẹ̀ ni?’ Láti lè ṣe ìpinnu tó tọ́, onítọ̀hún ní láti dáhùn ìbéèrè yìí láìṣàbòsí, ‘Kí ló wù mí jù lọ láyè yìí?’ Ó gbọ́dọ̀ gbé àwọn góńgó rẹ̀ yẹ̀ wò.
3 Kí lo ti fi ṣolórí àníyàn rẹ nígbà èwe rẹ? Ṣé ibi tí owó yóò ti jáde nìkan ló gbà ẹ́ lọ́kàn ni, àbí ṣe lo fẹ́ lo ìgbésí ayé ẹ fún mímú ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú? Pé ẹnì kan gboyè jáde ní yunifásítì kò túmọ̀ sí pé yóò ríṣẹ́ tó ní láárí ṣe. Dípò èyí, ọ̀pọ̀ ti níṣẹ́ tó dáa lọ́wọ́ nípa lílọ kọ́ irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn mìíràn lọ sílé ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́, àwọn mìíràn lọ kàwé onígbà kúkúrú ní kọ́lẹ́ẹ̀jì, irú ìwọ̀nyí kò sì ní wàhálà títí lọ nínú.
4 Gbà Pé Awímáyẹhùn ni Jèhófà: Kókó pàtàkì kan tó yẹ ká ronú lé lórí ni ìlérí tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe pé òun yóò pèsè fún àwọn tó bá fi ire Ìjọba náà sípò kìíní nínú ìgbésí ayé wọn. (Mát. 6:33) Èyí kì í màá ṣe ìlérí lásán. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin tí wọ́n ti wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ló gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́, iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe jẹun kí wọ́n tó wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́? Àwọn díẹ̀ lára wọn ló jẹ́ pé iṣẹ́ tí wọ́n kọ́ ní yunifásítì gan-an ni wọ́n ń ṣe jẹun. Ọ̀pọ̀ ló ń ṣiṣẹ́ abánitún-nǹkan-ṣe, wọ́n sì ń gbọ́ bùkátà ara wọn bí wọ́n ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà. Nípa mímú ìgbòkègbodò wọn gbòòrò sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, wọ́n ń rí ìbùkún tó kọjá ohunkóhun tí owó lè mú wá gbà.
5 Láti pinnu ohun tí wàá ṣe lẹ́yìn tóo bá parí ìwé mẹ́wàá, gbé gbogbo ohun tó wé mọ́ ọn yẹ̀ wò, kí o sì ronú jinlẹ̀ lórí góńgó rẹ. Láti lè ní èrò tí kò fì síbì kan nípa ohun tóo lè yàn, gbé irú ìsọfúnni tó jáde nínú Jí! ti March 8, 1998, ojú ìwé 19 sí 21, yẹ̀ wò. Fikùn lukùn pẹ̀lú àwọn òbí rẹ, àwọn alàgbà, alábòójútó àyíká rẹ, àti àwọn aṣáájú ọ̀nà tó ti ṣàṣeyọrí lágbègbè rẹ. Ìyẹn yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nípa ohun tóo lè fi ìgbésí ayé rẹ ṣe.—Oníw. 12:1, 13.