O Ha Ní Iye Ìwé Ìròyìn Pàtó Tí O Ń Gbà Bí?
1 Ǹjẹ́ o ti lọ sí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá rí tí o wá rí i pé o kò ní ìwé ìròyìn kankan nínú àpò tí o ń gbé lọ sí òde ẹ̀rí? Kò burú, rántí ohun tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1996 tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ.” Ó sọ fún wa pé kí a “ní ìṣètò gúnmọ́ fún gbígba ìwé ìròyìn,” ní sísọ pé: “Forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìròyìn fún gbígba iye ẹ̀dà gúnmọ́ nínú ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan. Ní ọ̀nà yìí, ìwọ àti ìdílé rẹ yóò ní ìpèsè ìwé ìròyìn tí ó ṣe déédéé tí ó sì tó.” Ṣé o ti ṣe bẹ́ẹ̀?
2 Kí ló dé tí o kò forúkọ sílẹ̀ fún iye ìwé ìròyìn tí wàá máa gbà déédéé? Ìwọ yóò fẹ́ láti ṣe ojúṣe rẹ lọ́nà tí ó túbọ̀ ga sí i ní pípín ìwé ìròyìn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ìwọ yóò sì ní ayọ̀ kíkún sí i ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Bí o bá ti ní iye pàtó tí o ń gbà, o tún lè ṣàyẹ̀wò rẹ̀ láti mọ̀ bóyá o ń gba èyí tí ó tó láti lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún oṣù kọ̀ọ̀kan ní ìpíndọ́gba. Láìsí àní-àní, ẹ jẹ́ kí a fi ìṣòtítọ́ wa hàn ní gbígba àwọn ìwé ìròyìn wa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kí a sì mọ̀ pé ó pọndandan fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí o bá fẹ́ fi ìjọ sílẹ̀ fún àkókò pípẹ́, jẹ́ kí ẹni tí ń bójú tó ìwé ìròyìn mọ̀ bí òun yóò ba máa kó ìwé ìròyìn rẹ fún ẹlòmíràn kí o tó dé.
3 Àkìbọnú kan náà tí a ṣàyọlò rẹ̀ lókè tún sọ pé a gbọ́dọ̀ “ṣètò fún ọjọ́ ìwé ìròyìn tí ó ṣe déédéé.” Ǹjẹ́ o lè ṣe ìtìlẹ́yìn fún Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀? Gbogbo ọjọ́ Saturday tó wà nínú ọdún ni a óò máa ṣe èyí, bí a ti fi hàn nínú 1999 Calendar of Jehovah’s Witnesses! Má ṣe fojú kéré ìjẹ́pàtàkì pípín Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tí a bá sapá láti kópa kíkún nínú ìgbòkègbodò ìwé ìròyìn, a “ń mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù” lọ fún àwọn aládùúgbò wa.—Aísá. 52:7.