ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp20 No. 1 ojú ìwé 3-5
  • Ibo La Ti Lè Rí Òtítọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo La Ti Lè Rí Òtítọ́?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ṢÉ O LÈ RÍ ÒTÍTỌ́?
  • BÓ O ṢE LÈ MỌ ÒTÍTỌ́
  • ÌWÉ ÒTÍTỌ́ TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀
  • Kí Ló Dé Tí N Kò Lè Kẹ́kọ̀ọ́?
    Jí!—1996
  • Fífarawé Ọlọ́run Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Èéṣe Tí A Fi Ń Wá Òtítọ́ Kiri?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Òtítọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
wp20 No. 1 ojú ìwé 3-5
Ọkùnrin kan ń wo ibi ìkówèésí tí oríṣiríṣi ìwé wà níbẹ̀

Ibo La Ti Lè Rí Òtítọ́?

Tá a bá mọ òtítọ́, ó lè gba ẹ̀mí wa là. Bí àpẹẹrẹ, wo ìbéèrè kan tó kan ìgbésí ayé wa. Ìbéèrè náà ni, báwo ni àrùn tó ń ranni ṣe ń tàn kálẹ̀?

Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún làwọn èèyàn ò ti mọ ìdáhùn ìbéèrè yẹn, tí wọ́n bá mọ ìdáhùn ẹ̀ ni, àjàkálẹ̀ àrùn ì bá má gbẹ̀mí àìmọye èèyàn. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì wá mọ ìdáhùn ìbéèrè yẹn. Ìwàdìí tí wọ́n ṣe fi hàn pé kòkòrò àrùn ló ń fa àìsàn tó ń ranni. Bí wọ́n ṣe mọ òtítọ́ pàtàkì yẹn jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti dènà àrùn, kí wọ́n sì tọ́jú oríṣiríṣi àìsàn. Èyí tún ti mú kí ìlera àìmọye èèyàn dáa sí i lónìí, kí ẹ̀mí wọn sì gùn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Àmọ́, báwo la ṣe lè mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tó kù? Àǹfààní wo lo rò pé wàá rí tó o bá mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí?

  • Ta ni Ọlọ́run?

  • Ta ni Jésù Kristi?

  • Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

  • Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

Àìmọye èèyàn ti mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yẹn, ìyẹn sì ti jẹ́ kí ayé wọn dáa sí i. Ìwọ náà lè jàǹfààní látinú ìdáhùn tí wọ́n rí.

ṢÉ O LÈ RÍ ÒTÍTỌ́?

O lè máa rò ó pé, ‘Ṣé òtítọ́ wà ṣá?’ Ó ṣe tán, ó túbọ̀ ń ṣòro gan-an láti mọ òtítọ́ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan lónìí. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ò fọkàn tán ìjọba àtàwọn oníṣòwò tàbí ohun táwọn oníròyìn ń gbé jáde. Ó ṣòro fún wọn láti mọ̀ bóyá òótọ́ lẹnì kan ń sọ àbí ó kàn ń sọ èrò tiẹ̀, bóyá irọ́ díẹ̀ òótọ́ díẹ̀ ni àbí irọ́ tiẹ̀ ni gbogbo ẹ̀. Bó ṣe jẹ́ pé àwọn èèyàn ò fọkàn tán ara wọn, tó sì jẹ́ pé ìsọfúnni tó ń ṣini lọ́nà ló wà káàkiri, àwọn èèyàn ò mọ ohun tó jóòótọ́ gangan, wọn ò sì mọ̀ pé ó léwu tí wọn ò bá mọ òtítọ́.

Láìka ìṣòro yìí sí, a lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tá à ń béèrè. Báwo la ṣe lè ṣe é? Ohun tá a máa ṣe ò yàtọ̀ sí ohun tá a máa ń ṣe tá a bá fẹ́ ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan kéékèèké míì.

BÓ O ṢE LÈ MỌ ÒTÍTỌ́

Ohun kan ni pé ojoojúmọ́ la máa ń wá òtítọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ti obìnrin kan tó ń jẹ́ Jessica. Ó sọ pé: “Ẹ̀pà máa ń fa àìlera fún ọmọbìnrin mi, ó le débi pé tó bá ṣèèṣì jẹ ohun tó ní ẹ̀pà nínú, wàhálà ni.” Jessica máa ń wádìí dáadáa nípa oúnjẹ tí ọmọ ẹ̀ fẹ́ jẹ láti mọ̀ bóyá ó lè ṣàkóbá fún ìlera ọmọ rẹ̀. Ó ní: “Ohun àkọ́kọ́ tí mo máa ń ṣe ni pé màá fara balẹ̀ wo àkọlé ara oúnjẹ náà kí n lè mọ èròjà tí wọ́n fi ṣe é. Lẹ́yìn ìyẹn, màá ṣàwọn ìwádìí kan kí n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kàn sí iléeṣẹ́ tó ṣe oúnjẹ náà láti mọ̀ bóyá wọn ò ṣèèṣì fi ẹ̀pà kún èròjà oúnjẹ náà. Mo tún máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé iléeṣẹ́ tó ṣe oúnjẹ náà ṣeé gbára lé.”

Ọkùnrin yìí kan náà tún ń wo ìwé kan tó mú níbẹ̀, ó sì ń fi ohun tó wà nínú rẹ̀ wé ohun tó wà lórí tablet rẹ̀

Àwọn ìbéèrè tó ò ń wá ìdáhùn rẹ̀ lójoojúmọ́ lè má ṣe pàtàkì tó ti Jessica, síbẹ̀ o lè lo àwọn àbá mẹ́ta tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè rẹ:

  • Ka ìsọfúnni nípa ohun náà.

  • Ṣèwádìí sí i.

  • Rí i dájú pé o lo àwọn ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé.

Tó o bá lo àwọn àbá mẹ́ta yìí, wàá rí ìdáhùn tó jóòótọ́ sáwọn ìbéèrè pàtàkì. Lọ́nà wo?

ÌWÉ ÒTÍTỌ́ TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀

Nígbà tí Jessica fẹ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì, ohun tó ṣe nígbà tó ń wádìí nípa oúnjẹ tó ń fa àìlera fún ọmọ rẹ̀ náà ló ṣe. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń fara balẹ̀ ka ìsọfúnni tí mo sì ń ṣèwádìí ti jẹ́ kí n rí òtítọ́ látinú Bíbélì.” Àìmọye èèyàn bíi Jessica ló ti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbéèrè bíi:

  • Kí nìdí tá a fi wà láyé?

  • Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?

  • Kí nìdí tá a fi ń jìyà?

  • Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí ìyà?

  • Báwo la ṣe lè ní ìdílé aláyọ̀?

Ọkùnrin yẹn tún ń ka Bíbélì, ó sì ṣí kọ̀ńpútà rẹ̀ sílẹ̀

Wàá rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn míì tó o bá ń ka Bíbélì tó o sì ń ṣèwádìí lórí ìkànnì www.jw.org.

Ilé Ìṣọ́ yìí máa jẹ́ ká rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè bíi:

  • Ta ni Ọlọ́run?

  • Ta ni Jésù Kristi?

  • Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

  • Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdí tá a fi lè sọ pé inú Bíbélì la ti lè rí òtítọ́ to ṣeé gbára lé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́