Ǹjẹ́ O Ń Fara Dà Á?
1 “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, . . . pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòh. 4) Ìfaradà tí àwọn ọmọ Jòhánù nípa tẹ̀mí ní mú inú rẹ̀ dùn jọjọ. Ẹ wo bí inú Baba wa ọ̀run yóò ti dùn tó láti rí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí yóò di ọmọ rẹ̀ kí wọ́n máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́”!—Òwe 23:15, 16; 27:11.
2 Nígbà tó jẹ́ pé àwọn ènìyàn Ọlọ́run lápapọ̀ ń tẹra mọ́ ìgbòkègbodò onítara ti Kristẹni, àwọn kan ti dẹwọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn yìí ti lè jẹ́ alágbára nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, bí ọdún ti ń gorí ọdún, wọ́n ti wá sọ ọ́ di àṣà láti máa ṣe ìwọ̀nba kín-ún nínú iṣẹ́ sísọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn, àwọn kan sì ń ṣe é ní ìdákúrekú.
3 Ó yéni pé, àwọn kan lè ti dẹwọ́ nítorí àìlera àti bí ara ṣe ń dara àgbà. Síbẹ̀, ó yẹ kí a gbóríyìn fún wọn fún ìfaradà wọn. Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe ni wọ́n ń ṣe. Ṣùgbọ́n, ó yẹ kí olúkúlùkù ẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé mo ti fi ara jin lílépa àwọn nǹkan ti ara tó fi wá jẹ́ pé ipa díẹ̀ ni ire Ìjọba náà ń kó nínú ìgbésí ayé mi? Ṣé kì í ṣe pé mo ti “lọ́wọ́ọ́wọ́” bákan ṣáá, àbí mo ṣì ń tiraka “tokuntokun”?’ (Ìṣí. 3:15, 16; Lúùkù 13:24) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa kún fún àdúrà bí a ti ń ronú nípa àwọn ohun tí a ń ṣe, kí a sì máa ṣe àtúnṣe tó bá yẹ, kí a máa fi sọ́kàn pé Jèhófà ṣèlérí láti pèsè “ògo àti ọlá àti àlàáfíà fún gbogbo ẹni tí ń ṣe ohun rere.”—Róòmù 2:10.
4 Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á: Kí ló mú kí Jésù lè fara dà á? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” (Héb. 12:1-3) Ìdùnnú tí a gbé ka iwájú Jésù ju àwọn àdánwò ìgbà díẹ̀ tí ó ní láti kojú lọ fíìfíì. Fífi ìdùnnú tí a gbé ka iwájú wa sọ́kàn lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á pẹ̀lú. (Ìṣí. 21:4, 7; 22:12) Bí a bá ń wo Jèhófà pé kí ó fún wa lókun nípa dídá kẹ́kọ̀ọ́, lílọ sí ìpàdé déédéé, àti gbígbàdúrà léraléra, yóò ṣeé ṣe fún wa láti máa bá iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́ nìṣó.
5 Inú Jèhófà máa ń dùn sí ìfaradà àwọn adúróṣinṣin rẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa mú ìdùnnú rẹ̀ pọ̀ sí i nípa bíbá a nìṣó ní “rírìn nínú òtítọ́.”