ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/00 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 14
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 21
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 28
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 4
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 8/00 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 14

Orin 114

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá oṣù April lórílẹ̀-èdè yìí àti níjọ yín. Òpin ọ̀sẹ̀ méjì péré ló kù nínú oṣù August, nítorí náà, fún gbogbo akéde níṣìírí pé kí wọ́n kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ kí oṣù tó parí. Ṣàyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tí ẹ ṣètò fún òpin ọ̀sẹ̀.

15 min: “Ja Ìjà Àtàtà ti Ìgbàgbọ́.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé kún un látinú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 44 àti 45, lórí bí àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ṣe lè ṣètò ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá fún àwùjọ wọn, kí wọ́n sì fún àwọn tó bá nílò ìrànwọ́ ní àfiyèsí láti lè máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí wọ́n sì máa ròyìn déédéé.

18 min: Bí O Ṣe Lè Jàǹfààní Nípa Lílọ sí Ilé Ẹ̀kọ́. Bàbá kan ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ kí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ìdí tí ẹ̀kọ́ ìwé fi ṣàǹfààní. (Wo ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè, ojú ìwé 133 sí 139.) Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ronú pé lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ jẹ́ ìpèníjà gidi nínú àwùjọ tó ti ya ewèlè lóde òní. Ọ̀ràn ti sú wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ń parí èrò sí pé ohun tí àwọn bá kọ́ kò ní fi bẹ́ẹ̀ wúlò. Bàbá ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó fi bọ́gbọ́n mu láti kọ́ ẹ̀kọ́ ìwé tí ó tó. Ó fún àwọn ọmọ rẹ̀ níṣìírí pé kí wọ́n gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ wọn, kí wọ́n sì máa fetí sílẹ̀ ní kíláàsì.

Orin 127 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 21

Orin 143

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn iṣẹ́ ìsìn pápá tí a fi dánra wò dáadáa, tó fi hàn bí a ṣe lè dáhùn ìbéèrè tó sọ pé: “Èé ṣe tí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ fi jẹ́ kí ìjìyà máa bá a nìṣó fún àkókò gígùn bẹ́ẹ̀?” (Ìwé Reasoning, ojú ìwé 395 àti 396) Fún gbogbo akéde níṣìírí pé kí wọ́n kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lópin ọ̀sẹ̀ yìí.

8 min: Àkókò Wa Jẹ́ Àrà Ọ̀tọ̀. Àsọyé tí alàgbà sọ, tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, November 15, 1996, ojú ìwé 22 àti 23.

25 min: “Ǹjẹ́ O Ń Ṣe Ara Rẹ Láǹfààní?” Ìbéèrè àti ìdáhùn.

Orin 152 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 28

Orin 165

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù August sílẹ̀. Kí àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ béèrè ìròyìn lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó wà nínú àwùjọ wọn kí a lè kó gbogbo ìròyìn jọ ní September 6.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Ìpàdé Máa Ń Ṣe Àwọn Ọ̀dọ́ Láǹfààní.” Ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn tí alàgbà darí. Nígbà tí o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 8, ṣàyẹ̀wò àwọn ohun kan tó gbéṣẹ́ tó máa ń jẹ́ kí ènìyàn túbọ̀ pọkàn pọ̀, kí èèyàn sì túbọ̀ fetí sílẹ̀ ní àwọn ìpàdé. (Wo Jí!, October 8, 1998, ojú ìwé 24 àti 25.) Fún àwọn òbí níṣìírí pé kí wọ́n máa rí i dájú pé àwọn ò fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú àwọn ọmọ wọn nínú lílọ sí gbogbo ìpàdé déédéé.—Wo ìrírí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́, September 1, 1997, ojú ìwé 25.

Orin 176 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 4

Orin 196

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: “Máa Fúnrúgbìn ní Yanturu, Ṣùgbọ́n Lo Ìfòyemọ̀.” Ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ àwọn gbólóhùn tó yẹ ní pàtàkì ní ìpínlẹ̀ yín. Kí ẹ ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá wọ̀nyí ní àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tí ẹ óò ṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí.

25 min: “Ǹjẹ́ O Ń Fara Dà Á?” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n ronú nípa àṣeyọrí tí olúkúlùkù wọn ti ṣe ní fífi ìfaradà hàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Bí a bá rí i pé ó fẹ́ máa rẹ̀ wá, ó yẹ kí a fún ara wa lókun nípa tẹ̀mí. Fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́, October 1, 1999, ojú ìwé 20 àti 21, ìpínrọ̀ 17 sí 21. Sọ pé kí àwọn akéde méjì tàbí mẹ́ta, tí wọ́n ti fi ìṣòtítọ́ fara dà á fún ọ̀pọ̀ ọdún, sọ ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa bá a nìṣó.

Orin 206 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́