“Ja Ìjà Àtàtà ti Ìgbàgbọ́”
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣí Tímótì létí pé kí ó “ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́.” (1 Tím. 6:12) Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ gbé ìgbé ayé rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ohun tó sọ yìí. Nígbà tó ku díẹ̀ kó parí ìgbésí ayé rẹ̀, ó fi ìdánilójú sọ pé òun gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ti ja ìjà àtàtà. (2 Tím. 4:6-8) Ní gbogbo ọ̀nà, ó fi àìṣojo, ìgboyà, àti ìfaradà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀, àwa náà lè ní irú ìdánilójú yẹn nínú ọkàn wa pé gbogbo ohun tí a lè ṣe ni a ń ṣe nínú ìjà ìgbàgbọ́ Kristẹni wa.
2 Sa Gbogbo Ipá Tó Bá Yẹ: Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà láṣekára. (1 Kọ́r. 15:10) Bẹ́ẹ̀ làwa náà ń ṣe bí a ti ń wá gbogbo ẹni yíyẹ kiri ní ìpínlẹ̀ wa. (Mát. 10:11) Láti dé ọ̀dọ̀ àwọn kan lára wọn, ó lè gba pé ká tètè jí ní kùtùkùtù láti lọ jẹ́rìí fún àwọn tí a bá rí ní òpópónà. Tàbí kẹ̀ kí á lọ ní ọwọ́ ọ̀sán tàbí ìrọ̀lẹ́ kí a lè bá àwọn èèyàn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti padà sí ilé wọn.
3 Ó gba fífọwọ́ gidi múra ẹni àti wíwéwèé dáadáa kí a lè dé lákòókò nígbà tí a bá fẹ́ pé jọ pẹ̀lú àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wa fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Bí àpẹẹrẹ, ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀, àwọn kan lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa ń rin ìrìn àjò fún nǹkan bíi wákàtí kan láti dé ìjọ tí a yàn wọ́n sí kí wọ́n lè kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Síwájú sí i, ó yẹ ká yin àwọn akéde kan àti àwọn ìdílé kan nínú ìjọ wa tí ọ̀nà wọn jìn díẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n máa ń dé lákòókò. Ó yẹ kí a máa fara wé irú àwọn àpẹẹrẹ ti jíjẹ́ aláápọn àti mímètòóṣe lọ́nà yìí.
4 Ó yẹ kí a sún wa láti padà lọ síbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn. Kódà nígbà tí a bá ń fi ìwé lọni ní òpópónà tàbí nígbà tí a bá ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà, ó yẹ kí a sapá láti gba àdírẹ́sì tàbí nọ́ńbà tẹlifóònù irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn náà, a lè kàn sí wọn láti mú kí ìfẹ́ yẹn gbèrú sí i, kí a sì sakun láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
5 Máa Ṣe Déédéé Nínú Iṣẹ́ Ìsìn: Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ ìwàásù déédéé, ó sì ṣe é kúnnákúnná. (Róòmù 15:19) Ìwọ ńkọ́? Ṣé o máa ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ déédéé? Ǹjẹ́ o tíì kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣù yìí? Àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ fẹ́ láti rí i pé gbogbo àwọn tó wà ní àwùjọ àwọn ni yóò kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní oṣù August. Wọn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
6 Títẹ̀lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù nípa ṣíṣètìlẹyìn fún ìhìn rere ní kíkún, yóò mú kí a máa bá a nìṣó láti “ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́.”