Ǹjẹ́ O Mọrírì Sùúrù Jèhófà?
1 Ká ní Jèhófà kò ti ní sùúrù fún ọdún mẹ́wàá, ogún ọdún, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sẹ́yìn, kó sì fàyè gba jíjẹ́rìí lọ́nà gbígbòòrò, ṣé ìwọ ì bá ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? A kún fún ìmoore pé ó fàyè gba àwọn èèyàn púpọ̀ sí i láti “wá sí ìrònúpìwàdà.” Síbẹ̀, ọjọ́ ńlá Jèhófà, nígbà tí yóò ṣèdájọ́ “yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè.” (2 Pét. 3:9, 10) Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ ṣi sùúrù Ọlọ́run lóye pé ṣe ló ń fi mímú òpin dé bá ètò àwọn nǹkan yìí falẹ̀.—Háb. 2:3.
2 Jẹ́ Kí Àánú Àwọn Èèyàn Máa Ṣe Ọ́: Kò ṣeé ṣe fún wa rárá láti lóye bí ìpamọ́ra Jèhófà ṣe pọ̀ tó. A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé ète rẹ̀. (Jónà 4:1-4, 11) Jèhófà rí ipò tí ń ṣeni láàánú tí aráyé wà, ó sì ní ìyọ́nú fún wọn. Jésù pẹ̀lú tún ní ìyọ́nú fún wọn. Níwọ̀n bí ó ti ní àánú fún àwọn èrò tó ń wàásù fún, ó fẹ́ kí iṣẹ́ ìjíhìnrere gbòòrò kí àwọn mìíràn lè láǹfààní láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—Mát. 9:35-38.
3 Nígbà tí ọ̀ràn ìbànújẹ́ àti jàǹbá bá ṣẹlẹ̀, ǹjẹ́ àánú àwọn tí kò mọ òtítọ́ kì í ṣe wá? Lónìí, ṣe làwọn èèyàn dà bí “àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn” bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti kojú àwọn ìdàrúdàpọ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé, kí wọ́n sì lóye wọn. (Máàkù 6:34) Nípa fífi ìtara wàásù ìhìn rere, a ń tu àwọn tó ní ọkàn-àyà títọ́ nínú, a sì ń fi hàn pé a mọrírì sùúrù Jèhófà.—Ìṣe 13:48.
4 Iṣẹ́ Wa Jẹ́ Kánjúkánjú: Lọ́dún tó kọjá, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́tàlélógún, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mọ́kàndínlógójì [323,439] ló ṣe batisí, ó sì ju mílíọ̀nù mẹ́rìnlá tó wá sí Ìṣe Ìrántí. Ẹ ò rí i pé ó ṣeé ṣe kí èèyàn púpọ̀ sí i bọ́ lọ́wọ́ ìparun ètò búburú yìí! Bí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yóò ṣe pọ̀ tó la ò mọ̀. (Ìṣí. 7:9) A ò mọ bí iṣẹ́ ìwàásù tí a gbé lé wa lọ́wọ́ yóò ṣe máa bá a lọ pẹ́ tó. Ṣùgbọ́n Jèhófà mọ̀ ọ́n. A ó sì wàásù ìhìn rere náà débi tó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn dé, “nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mát. 24:14.
5 Àkókò tó ṣẹ́ kù kò tó nǹkan, ọjọ́ Ọlọ́run sì ti sún mọ́lé. (1 Kọ́r. 7:29a; Héb. 10:37) Láìsí iyèméjì, “ìgbàlà wa sún mọ́lé . . . ju ìgbà tí a di onígbàgbọ́.” (Róòmù 13:11) Ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣàìlóye ète tí Ọlọ́run fi ní sùúrù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa fi ìjẹ́kánjúkánjú wàásù kí púpọ̀ sí i nínú àwọn tí ń yán hànhàn fún òdodo lè rí àánú ńlá Jèhófà.