ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/00 ojú ìwé 4
  • Ṣé O Máa Ń Tijú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé O Máa Ń Tijú?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Dé Tí N Kì Í Túra Ká?
    Jí!—1999
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Tijú Mọ́?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Túra Ká?
    Jí!—1999
  • Jèhófà Máa Fún Ẹ Lókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 7/00 ojú ìwé 4

Ṣé O Máa Ń Tijú?

1 Kì í yà wá lẹ́nu nígbà tí ọmọ kékeré kan bá rọra ń yọjú wò wá láti ẹ̀yìn ìyá tàbí bàbá rẹ̀. Ìwà ẹ̀dá ni pé kí èèyàn máa tijú nígbà tí a bá wà lọ́mọdé. Ọ̀pọ̀ ló tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí wọ́n di àgbà pàápàá, ojú ṣì máa ń tì wọ́n díẹ̀díẹ̀. Bí ìtìjú bá ń ní ipa lórí bí o ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí lo lè ṣe?

2 Bíborí Ìtìjú: Ó ṣe pàtàkì pé kí o fún “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà” ní àfiyèsí. (1 Pét. 3:4) Mú kí ìfẹ́ tí o ní sí Jèhófà àti sí ọmọnìkejì túbọ̀ lágbára sí i. Jẹ́ kó dá ọ lójú ṣáká pé ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù tí a pa láṣẹ ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó dára jù lọ láti fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn. Ṣe ètò tó dáa fún dídákẹ́kọ̀ọ́ àti lílọ sí àwọn ìpàdé kí o sì máa tẹ̀ lé e. Máa gbàdúrà déédéé, kí o sì bẹ̀bẹ̀ fún ìrànwọ́ Jèhófà ní pàtó. Níní ìgbàgbọ́ lílágbára nínú rẹ̀ àti gbígbẹ́kẹ̀lé e yóò mú kí o ní ìgbọ́kànlé, yóò sì pèsè “ìgboyà púpọ̀ sí i . . . láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù.”—Fílí. 1:14.

3 Bá ìmọ̀lára àìkúnjú ìwọ̀n jìjàkadì. Ó dà bíi pé ohun tí Tímótì ṣe nìyí. Pọ́ọ̀lù fún Tímótì níṣìírí pé kí ó “má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fojú tẹ́ńbẹ́lú èwe [rẹ̀] láé,” ó rán an létí pé “kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára.” (1 Tím. 4:12; 2 Tím. 1:7) Jèhófà lo Tímótì dáadáa, yóò sì tún lò ọ́ bí o bá ń sapá láti máa tẹ̀ síwájú, tí o sì gbọ́kàn lé E pátápátá.—Sm. 56:11.

4 Ríronú lórí ẹsẹ Bíbélì kan, bíi Mátíù 10:37, ran arábìnrin kan lọ́wọ́, ẹni tí àìnígboyà rẹ̀ máa ń jẹ́ kí ẹ̀rù ọkọ rẹ̀ tí ń ṣàtakò bà á. Bó ṣe ń forí tì í, iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà túbọ̀ rọrùn fún un, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ọkọ rẹ̀, ìyá rẹ̀, àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́!

5 Ṣe Kókó: Ìgbọ́kànlé tí o ní yóò túbọ̀ pọ̀ sí i nígbà tí o bá múra sílẹ̀ dáadáa fún iṣẹ́ òjíṣẹ́. Wá ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó rọrùn látinú ìwé Reasoning tàbí látinú àwọn ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ti kọjá, kà á, kí o sì fi dánra wò. Dípò tí wàá fi máa ṣojora lọ́nà tí kò yẹ, ronú pé nǹkan yóò ṣẹnuure. Jẹ́ kí ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn fún ọ nígboyà. Fi sọ́kàn pé ọ̀pọ̀ àwọn tí wàá bá pàdé làwọn náà kò gbóyà bíi tìẹ. Gbogbo èèyàn ló yẹ kó gbọ́ ìhìn Ìjọba náà.

6 Bí o bá ń tijú, má ṣe sọ̀rètí nù. Bí o ti ń sapá, Jèhófà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti di oníwàásù ìhìn rere tó dáńgájíá. Nígbà náà, ìwọ yóò máa ní ìdùnnú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.—Òwe 10:22.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́