ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/02 ojú ìwé 1
  • Fífi Tayọ̀tayọ̀ Wà Níṣọ̀kan Pẹ̀lú Jèhófà àti Ọmọ Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Tayọ̀tayọ̀ Wà Níṣọ̀kan Pẹ̀lú Jèhófà àti Ọmọ Rẹ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tá A Fi Ń Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Máa Fi Ìmọrírì Ronú Lórí Ìràpadà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Wa Tá A Bá Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • “Ẹ Máa Ṣe Èyí Ní Ìrántí Mi”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 3/02 ojú ìwé 1

Fífi Tayọ̀tayọ̀ Wà Níṣọ̀kan Pẹ̀lú Jèhófà àti Ọmọ Rẹ̀

Ayẹyẹ Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ọdún Yóò Wáyé ní March 28

1 Nípa ṣíṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní March 28, 2002, a óò fi hàn pé tayọ̀tayọ̀ la wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. Lásìkò ayẹyẹ àkànṣe yìí, àwọn àṣẹ́kù Kristẹni ẹni àmì òróró yóò nírìírí àkànṣe “àjọpín” tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn ajùmọ̀jogún Ìjọba, pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀. (1 Jòh. 1:3; Éfé. 1:11, 12) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn “àgùntàn mìíràn” yóò ronú jinlẹ̀ lórí àǹfààní àgbàyanu tí wọ́n ní láti lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, tí ìmọ̀ wọn sì ṣọ̀kan bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run!—Jòh. 10:16.

2 Wọ́n Ní Àjọṣe Tímọ́tímọ́ Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣiṣẹ́ Pa Pọ̀: Ìgbà gbogbo ni Jèhófà àti Jésù máa ń fi tayọ̀tayọ̀ wà níṣọ̀kan. Wọ́n ti gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ fún àìmọye ọdún ṣáájú kí wọ́n tó dá ènìyàn. (Míkà 5:2) Èyí ló mú kí ìdè ìfẹ́ alọ́májàá wà láàárín àwọn méjèèjì. Gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ bí ènìyàn, ó ṣeé ṣe fún àkọ́bí Ọlọ́run yìí láti sọ ohun kan tó sọ kó tó wá sílé ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn. Ó sọ pé: “Mo wá . . . jẹ́ ẹni tí [Jèhófà] ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” (Òwe 8:30) Bíbá Orísun ìfẹ́ kẹ́gbẹ́ pọ̀ tímọ́tímọ́ fún àìlóǹkà ọdún ti ní ipa tó bùáyà lórí Ọmọ Ọlọ́run!—1 Jòh. 4:8.

3 Níwọ̀n bí Jèhófà ti mọ̀ pé ìran ènìyàn nílò ìràpadà, ó yan Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwa ẹ̀dá èèyàn gan-an, láti wá pèsè ẹbọ ìràpadà fún wa, èyí tó fún wa ní ìrètí kan ṣoṣo tá a ní. (Òwe 8:31) Bí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ṣe wà níṣọ̀kan bí wọ́n ti ń mú ète kan ṣoṣo ṣẹ́, bẹ́ẹ̀ làwa náà wà níṣọ̀kan pẹ̀lú wọn àti pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kínní kejì nínú ìdè ìfẹ́ tó lágbára, tá a sì ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tayọ̀tayọ̀.

4 Fífi Ìmọrírì Àtọkànwá Wa Hàn: Tá a bá pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí tá a sì fetí sílẹ̀ dáadáa, a óò fi hàn pé a ní ojúlówó ìmọrírì fún ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa àti ẹbọ tí Ọmọ rẹ̀ fi ara rẹ̀ rú nítorí wa. Ìpàdé náà yóò tẹnu mọ́ àpẹẹrẹ onífẹ̀ẹ́ tí Jésù fi lélẹ̀, bí ó ti jẹ́ olùṣòtítọ́ títí dé ojú ikú kí ó bàa lè pèsè ìràpadà náà, ìṣàkóso rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀, àti àwọn ìbùkún tí Ìjọba náà yóò mú wá bá ìran ènìyàn. A óò tún rán wa létí pé ó ṣe pàtàkì ká máa bá a nìṣó ní fífi ìgbàgbọ́ wa hàn ní gbangba, ká sì máa ṣiṣẹ́ tìtaratìtara ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.”—3 Jòh. 8; Ják. 2:17.

5 Ríran Àwọn Mìíràn Lọ́wọ́ Láti Bá Wa Pésẹ̀: Kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà sapá lákànṣe láti fún gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ ní ìpínlẹ̀ wọn níṣìírí láti wá síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. (Mát. 18:12, 13) Kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ orúkọ àwọn tí wọ́n máa kàn sí lẹ́nìkọ̀ọ̀kan, kí wọ́n má bàa gbójú fo ẹnikẹ́ni dá, kó sì lè ṣeé ṣe láti ké sí gbogbo wọn.

6 Ṣé o mọ àwọn ẹlòmíràn tó ṣeé ṣe kó wá síbi Ìṣe Ìrántí? Lo ìdánúṣe nígbà tó o bá ń ké sí wọn kí wọ́n bàa lè mọyì ayẹyẹ yìí. Ké sí wọn tọ̀yàyàtọ̀yàyà, kí wọ́n lè mọ̀ pé a fẹ́ kí wọ́n wá. Ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, àwọn ẹlòmíràn tó ń fìfẹ́ hàn, àwọn tó wà nínú ìdílé wa àti àwọn ojúlùmọ̀ wa, kí gbogbo wọn lè wá síbi ayẹyẹ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún yìí. Àwọn àǹfààní ìràpadà náà ṣì wà ní sẹpẹ́ fún gbogbo àwọn tó bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa “ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù.” (Fílí. 3:8) Àwọn tí ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Kristi lè ní ìrètí tó dájú nípa ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 3:16.

7 Má ṣe fojú kéré ipa tí Ìṣe Ìrántí náà lè ní lórí àwọn olóòótọ́ ọkàn. Lọ́dún méjì sẹ́yìn, lórílẹ̀-èdè Papua tó jẹ́ erékùṣù, àwọn olùfìfẹ́hàn mọ́kànlá rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan fún wákàtí mẹ́tàdínlógún nínú ìjì tó ń jà burúkú burúkú kí wọ́n lè lọ síbi Ìṣe Ìrántí. Kí ló mú kí wọ́n fẹ̀mí wọn wewu? Wọ́n sọ pé: “Ó wù wá láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí Kristi pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn Jèhófà ẹlẹgbẹ́ wa; nítorí náà, ìrìn àjò ọ̀hún tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Ìtara tí àwọn olùfìfẹ́hàn wọ̀nyẹn fi hàn àti ìmọrírì tí wọ́n ní fún fífi tayọ̀tayọ̀ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Jèhófà, pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀, àti pẹ̀lú àwọn Kristẹni arákùnrin wọn mà bùáyà o!

8 Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ gbogbo àwọn tó bá fìfẹ́ hàn. Fún wọn níṣìírí láti máa lọ sí ìpàdé ìjọ déédéé kí wọ́n sì máa jíròrò òtítọ́ Bíbélì tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa “rìn nínú ìmọ́lẹ̀” kí wọ́n sì máa “fi òtítọ́ ṣe ìwà hù” nípa fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn. (1 Jòh. 1:6, 7) Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì máa bá a nìṣó láti mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ìṣọ̀kan.

9 Àǹfààní àgbàyanu ló mà jẹ́ o, láti fi tayọ̀tayọ̀ wà ní ìṣọ̀kan “nínú ẹ̀mí kan, pẹ̀lú ọkàn kan tí [à] ń làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ fún ìgbàgbọ́ ìhìn rere”! (Fílí. 1:27, 28) Ẹ jẹ́ ká máa wọ̀nà fún ìbákẹ́gbẹ́ ọlọ́yàyà tá a máa gbádùn níbi Ìṣe Ìrántí ní March 28, bá a ti ń dúpẹ́ tá a sì ń tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀!—Lúùkù 22:19.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́