ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/02 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 11
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 18
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 25
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 1
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 3/02 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 11

Orin 2

13 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ewé 8, ṣe àwọn àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ March 15 àti Jí! April 8 lọni. Lo ìdámọ̀ràn àkọ́kọ́ tí o bá ń fi Jí! April 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí o fi hàn bí a ṣe lè fèsì sí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń pani lẹ́nu mọ́, irú bíi, “Mi ò fẹ́ gbọ́.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ewé 8.

12 min: Pípa Àìdásí Tọ̀tún Tòsì Wa Mọ́ Gẹ́gẹ́ Bí Kristẹni. Àsọyé tí alàgbà tó dáńgájíá kan yóò sọ. Fífi ẹ̀mí ìfọkànsìn fún orílẹ̀-èdè ẹni hàn ti wá wọ́pọ̀ gan-an báyìí ní ilé ẹ̀kọ́, níbi iṣẹ́ àti ní àdúgbò. Láwọn ilẹ̀ kan, ńṣe làwọn tó ń lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò wọ̀nyí rò pé ọ̀nà táwọn lè fi pàrònú rẹ́ nìyẹn, táwọn ò sì ní máa banú jẹ́ nítorí àwọn ìṣòro tó wà lórílẹ̀-èdè wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tá à ń rí tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ò dùn mọ́ àwa náà nínú, a mọ̀ pé ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ àgbáyé ló ṣe pàtàkì jù lọ, ìhìn rere Ìjọba náà sì ń tù wá nínú. Nígbà tá a bá ń fọgbọ́n ṣàlàyé fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìdí tí a kò fi ń lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò tó ń fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni hàn, ó yẹ ká tún sọ fún wọn nípa ìtùnú àti ìrètí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́, ṣàlàyé ìdí tí a kì í fi í lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ ìfọkànsìn orílẹ̀-èdè, ní ojú ewé 20 sí 24, lábẹ́ àkòrí kékeré náà, “Kíkí Àsíá.” Jíròrò àwọn kókó inú ìpínrọ̀ náà, kó o sì fún àwọn òbí níṣìírí láti fara balẹ̀ ṣàtúnyẹ̀wò ìsọfúnni yìí pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Sọ ìrírí tó wà ní ojú ewé 20 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, àti èyí tó wà ní ojú ewé 31 nínú ìtẹ̀jáde Jí! January 8, 1996. Tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì láti fún Jèhófà ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe, lẹ́sẹ̀ kan náà kí a sì máa bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ.

20 min: “Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà.”a Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o. Rọ gbogbo àwọn ará láti kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ní March 28. Ṣàlàyé bí a ṣe lè lo àwọn ìwé ìkésíni tá a tẹ̀ lọ́nà tó máa wúlò jù lọ. Sọ pé kí àwọn akéde sọ bí wọ́n ṣe mú kí àwọn ìbátan wọn, àwọn aládùúgbò, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àtàwọn olùfìfẹ́hàn mìíràn wá síbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́dún tó kọjá, kí wọ́n sì sọ ayọ̀ tí èyí ti mú wá fún wọn. Fún gbogbo àwọn tó bá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ níṣìírí láti ṣe bẹ́ẹ̀ lóṣù April kí wọ́n sì gba fọ́ọ̀mù ìforúkọsílẹ̀ lẹ́yìn ìpàdé.

Orin 82 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 18

Orin 7

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Jíròrò “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Rántí Nípa Ìṣe Ìrántí.” Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti tẹ̀ lé ètò Bíbélì Kíkà fún Ìṣe Ìrántí tí a ṣe láti March 23 sí 28, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2002.

15 min: “Fífi Tayọ̀tayọ̀ Wà Níṣọ̀kan Pẹ̀lú Jèhófà àti Ọmọ Rẹ̀.” Kí alàgbà kan sọ àsọyé yìí, kí ó sì lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà tí ń tani jí. Fún olúkúlùkù níṣìírí pé kí wọ́n túbọ̀ sapá láti ìsinsìnyí lọ títí di March 28 ní kíké sí àwọn èèyàn púpọ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó láti wá bá wa ṣe Ìṣe Ìrántí.

20 min: “Máa Bá A Nìṣó Nínú Iṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà.”b Kí alàgbà kan bójú tó o. Yóò dára tó bá jẹ́ aṣáájú ọ̀nà ni. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3 sí 5, fọ̀rọ̀ wá aṣáájú ọ̀nà kan lẹ́nu wò, ẹni tó ti fara da ọ̀pọ̀ nǹkan kó bàa lè máa bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, kí o sì tẹnu mọ́ àǹfààní tí ìforítì ti mú wá fún un.

Orin 45 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 25

Orin 12

14 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ṣàlàyé pé kò tíì pẹ́ jù láti forúkọ sílẹ̀ fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ewé 8, jẹ́ kí àgbàlagbà kan ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ April 1 lọni, kí ọ̀dọ́ kan sì fi hàn bí a ṣe lè fi Jí! April 8 lọni. Lo ìdámọ̀ràn kejì tí o bá ń fi Jí! April 8 lọni. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, mẹ́nu kan àwọn apá tó lè ṣeni láǹfààní nínú ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

16 min: Lo àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ Láti Fúnni Níṣìírí. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Gbogbo wa la nílò ìṣírí onífẹ̀ẹ́ látìgbàdégbà. Nítorí náà, ó yẹ kí gbogbo wa mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú” fún àwọn ẹlòmíràn, títí kan àwọn tí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò tá à ń bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. (1 Tẹs. 5:14) Nípa lílo àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ tí ó bá a mu [irú bí, w01-YR 2/1 ojú ewé 22; w01-YR 5/1 ojú ewé 8 sí 13; w00-YR 1/1 ojú ewé 30 sí 31; w00-YR 3/1 ojú ewé 5 sí 7], ké sí àwùjọ láti mẹ́nu kan àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí látinú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè lò láti fún ẹnì kan tó ní ìṣòro níṣìírí. Dámọ̀ràn pé kí olúkúlùkù gbìyànjú láti fún ẹnì kan níṣìírí nígbàkigbà tí wọ́n bá ti rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.—Gál. 6:10.

Orin 131 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 1

Orin 27

7 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù March sílẹ̀.

18 min: “‘Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ó Jẹ́ Ènìyàn’ Ń Fi Tinútinú Bójú Tó Agbo Ọlọ́run.” Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ. Ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí. Fi hàn bí àwọn ìrírí tó ń fúnni níṣìírí ṣe máa ń jẹ yọ nígbà táwọn alàgbà bá ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ àti nígbà tí wọ́n bá ran àwọn aláìlera lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí agbára wọ́n bá ká. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ máa ń fi ìmọrírì hàn fún gbogbo ìsapá àtọkànwá tí àwọn ará ń ṣe láti lè máa bá iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà lọ ní pẹrẹu.

20 min: “Jẹ́ Kí Ayọ̀ Tí Ò Ń Ní Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù Pọ̀ Sí I.”c Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, sọ pé kí àwọn ará sọ àwọn àbá tó gbéṣẹ́, tó sì lè wúlò gan-an fún iṣẹ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ ìjọ. Ṣàṣefihàn àpẹẹrẹ kan tàbí méjì nípa bí a ṣe lè lo ìdánúṣe láti lọ bá ẹnì kan kí a sì jẹ́rìí fún un ní ṣókí. Fún àwọn ará níṣìírí láti wá àyè láti jẹ́rìí lọ́sẹ̀ yìí.

Orin 15 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́