Báwo Làwọn Ìdílé Kristẹni Ṣe Lè Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí?
1 A gbóríyìn fún àwọn ìdílé Kristẹni fún bí wọ́n ṣe ń ‘fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe ìwà hù nínú agbo ilé wọn.’ (1 Tím. 5:4) Àmọ́ ṣá o, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan búburú tó lè sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ ti wà yí wa ká, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ìdílé sapá gidigidi láti dúró sán-ún nípa tẹ̀mí. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe èyí?
2 Lílo Ipò Orí Bíi Ti Kristi: Ó yẹ kí àwọn olórí ìdílé fara wé Jésù Kristi nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe ojúṣe wọn láti fún agbo ìdílé wọn lókun. Láfikún sí bí Jésù ṣe fi ìfẹ́ tó ní sí wa hàn nípa kíkú ikú ìrúbọ fún wa, ìgbà gbogbo ni ó ń ‘bọ́ ìjọ tí ó sì ń ṣìkẹ́ rẹ̀.’ (Éfé. 5:25-29) Àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ ń tẹ̀ lé irú àpẹẹrẹ ìtọ́jú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jésù fi lélẹ̀ yìí nípa bíbójútó àwọn nǹkan tẹ̀mí tí ìdílé wọn nílò lójoojúmọ́. Èyí kan dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, jíjíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí lọ́nà tó jinlẹ̀ nígbàkigbà tó bá ti ṣeé ṣe, àti bíbójútó àwọn ìṣòro bí wọ́n bá ṣe ń yọjú.—Diu. 6:6, 7.
3 Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá: Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé mọ̀ pé jíjẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn nípa Jèhófà àti àwọn ète rẹ̀ jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ìjọsìn wọn. (Aísá. 43:10-12) Bí ẹ̀yin òbí bá fẹ́ kí àwọn ọmọ yín di olóòótọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹ gbọ́dọ̀ tètè bẹ̀rẹ̀ sí múra ọkàn wọn sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ẹ bá wọn jíròrò ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìjẹ́pàtàkì kíkópa nínú rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Mát. 22:37-39) Lẹ́yìn náà, ẹ ṣètò bí wọ́n á ṣe máa jáde òde ẹ̀rí déédéé pẹ̀lú yín.
4 Ẹ ran ìdílé yín lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọyì ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ ìwàásù nípa yíya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, láti fi múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tó gbéṣẹ́ sílẹ̀ kẹ́ ẹ sì fi dánra wò. Ẹ fún ọmọ kọ̀ọ̀kan ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó máa wúlò fún un nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kẹ́ ẹ sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ síwájú níbàámu pẹ̀lú ọjọ́ orí àti agbára kálukú wọn. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jọ nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ẹ fọ̀rọ̀ wérọ̀ kẹ́ ẹ sì jẹ́ kí wọ́n sọ bí àwọn fúnra wọn ṣe mọyì oore Jèhófà. Ẹ sọ àwọn ìrírí afúngbàgbọ́lókun fún wọn. Bí àwọn ìdílé bá ti ń “tọ́ ọ wò pé onínúrere ni Olúwa” tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe máa sún mọ́ Jèhófà tó, èyí ló sì máa fún wọn lágbára láti dènà “gbogbo ìwà búburú.”—1 Pét. 2:1-3.
5 Ní Ìpàdé Ìjọ: Ó mà dáa o pé kí gbogbo ìdílé lápapọ̀ máa ran ara wọn lọ́wọ́ láti pésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé ìjọ, àgàgà nígbà tó bá rẹ ọ̀kan nínú wọn, tí ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí tí gbogbo nǹkan tojú sú u! Arábìnrin ọ̀dọ́ kan sọ pé: “Ó ti máa ń rẹ bàbá mi bó bá fi máa dé láti ibi iṣẹ́, àmọ́ mo máa ń sọ kókó pàtàkì kan tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípàdé lọ́jọ́ náà fún un, ìyẹn sì máa ń fún un níṣìírí láti lọ. Bó bá sì jẹ́ pé èmi ló rẹ̀, ó máa ń fún èmi náà níṣìírí láti lọ.”—Héb. 10:24, 25.
6 Ṣíṣe Àwọn Nǹkan Pa Pọ̀: Ó yẹ kí àwọn ìdílé máa ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀, irú bíi jíjọ ṣe iṣẹ́ ilé. Ó tún yẹ kí wọ́n ṣètò àkókò láti máa ṣe eré ìnàjú tó bójú mu. Nínajú lọ láti ṣe fàájì, ṣíṣeré ìdárayá, àti ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ìbátan àtàwọn ọ̀rẹ́ máa ń múnú ẹni dùn, ó sì máa ń wúni lórí béèyàn bá rántí.—Oníw. 3:4.
7 Àwọn ìdílé Kristẹni tó dúró sán-ún nípa tẹ̀mí máa ń borí àwọn ìpèníjà ojoojúmọ́ tó lè ba ipò tẹ̀mí wọn jẹ́. Nípa títúbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, wọ́n á lè máa rí agbára tó ń pèsè gbà.—Éfé. 6:10.