ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/06 ojú ìwé 3-6
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2007

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2007
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Ìtọ́ni
  • ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 10/06 ojú ìwé 3-6

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2007

Ìtọ́ni

Ní ọdún 2007, ìtọ́ni tó tẹ̀ lé e yìí la ó lò bá a bá ń darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 2007.

IBI TÁ A TI MÚṢẸ́ JÁDE: Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [bi12-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run [be-YR] àti Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò (Ìtẹ̀jáde 1998) [td-YR].

Kí ilé ẹ̀kọ́ yìí máa bẹ̀rẹ̀ LÁKÒÓKÒ pẹ̀lú orin, àdúrà àti ọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀, ká sì máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nísàlẹ̀ yìí. Lẹ́yìn iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa pe ẹni tí iṣẹ́ kàn sórí pèpéle.

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, olùrànlọ́wọ́ agbaninímọ̀ràn tàbí alàgbà mìíràn tó tóótun ni kó máa sọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, èyí tá a mú látinú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Láwọn ìjọ tí alàgbà ò bá ti pọ̀ tó, a lè lo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun.)

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí, kó sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ látinú Ilé Ìṣọ́ tàbí ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kó fi ìṣẹ́jú mẹ́wàá sọ ọ̀rọ̀ ìtọ́ni yìí. Kì í ṣe pé kí asọ̀rọ̀ náà kàn sọ̀rọ̀ lórí ibi tá a yàn fún un nìkan ni, ṣùgbọ́n ní pàtàkì, ó yẹ kó sọ ìwúlò kókó tó ń sọ̀rọ̀ lé lórí, kó sì tẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ni kó lò. A retí pé káwọn arákùnrin tó bá máa ṣe iṣẹ́ yìí rí i dájú pé àwọn ò kọjá àkókò tó yẹ kí wọ́n lò. A lè fún wọn nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́ bó bá yẹ.

ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTINÚ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Fún ìṣẹ́jú márùn-ún àkọ́kọ́, kí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ títóótun, tó máa ṣiṣẹ́ náà, ṣàlàyé bí Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ náà ṣe wúlò sí fún ìjọ. Ó lè sọ̀rọ̀ lórí apá èyíkéyìí lára Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ náà. Kì í wulẹ̀ ṣe pé kó kàn ṣe àkópọ̀ ibi tá a ní kó kà o. Ohun tí iṣẹ́ yìí wà fún ni láti jẹ́ kí àwùjọ lóye ìdí tí ọ̀rọ̀ tó ń sọ fi wúlò àti bó ṣe wúlò sí fún wọn. Kí asọ̀rọ̀ náà rí i dájú pé àlàyé òun kò kọjá ìṣẹ́jú márùn-ún. Kó wá lo ìṣẹ́jú márùn-ún tó kù láti fi gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwùjọ. Kó sọ pé kí àwùjọ sọ̀rọ̀ ṣókí (ní ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀) lórí ohun tí wọ́n gbádùn nínú Bíbélì kíkà náà àtàwọn àǹfààní rẹ̀. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sọ pé káwọn akẹ́kọ̀ọ́ tá a yàn sí kíláàsì mìíràn máa lọ síbẹ̀.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KEJÌ: Ìṣẹ́jú mẹ́rin tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Arákùnrin ni ká máa jẹ́ kó ka ìwé náà. Kí akẹ́kọ̀ọ́ ka ibi tá a yàn fún un láìsí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ àsọparí. Ohun tó yẹ kó jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lógún jù lọ ni bó ṣe máa ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti kàwé dáadáa nípa ṣíṣe àwọn ohun wọ̀nyí: kíkàwé lọ́nà tó yéni yékéyéké, jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ni lẹ́nu, títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ, yíyí ohùn padà nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dídánudúró bó ṣe yẹ àti sísọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dáni.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸTA: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Arábìnrin ni ká máa yan iṣẹ́ yìí fún. A lè yan ìgbékalẹ̀ kan fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tá a fún ní iṣẹ́ yìí tàbí kí wọ́n fúnra wọn yan ọ̀kan lára ìgbékalẹ̀ tá a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ìwé 82 nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí akẹ́kọ̀ọ́ lo ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a yàn fún un, kó sì lò ó lọ́nà tó máa bá apá kan nínú iṣẹ́ ìsìn pápá tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù wa mu tó sì wúlò níbẹ̀. Bí a kò bá kọ inú ìwé tá a ti mú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí jáde síwájú iṣẹ́ náà, kí akẹ́kọ̀ọ́ lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa láti lè mọ ohun tó máa sọ. Àwọn iṣẹ́ tá a kọ ibi tá a ti mú wọn jáde sí ni kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ilé ẹ̀kọ́. Ohun tó yẹ kó jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lógún jù lọ ni ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ rẹ̀, bó ṣe mú kí onílé ronú lórí Ìwé Mímọ́ àti bó ṣe mú kó lóye àwọn kókó pàtàkì inú iṣẹ́ rẹ̀. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò yan olùrànlọ́wọ́ kan fún akẹ́kọ̀ọ́ náà.

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸRIN: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Kí akẹ́kọ̀ọ́ tá a yan iṣẹ́ yìí fún sọ̀rọ̀ lórí kókó tá a yàn fún un. Bá ò bá kọ ibi tá a ti mú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí jáde síwájú iṣẹ́ náà, kí akẹ́kọ̀ọ́ lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye pèsè láti lè mọ ohun tó máa sọ. Bá a bá yàn án fún arákùnrin, kó sọ ọ́ bí àsọyé nípa dídarí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwùjọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó bá jẹ́ arábìnrin ni yóò bójú tó o, kó tẹ̀ lé ìtọ́ni tá a pèsè fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lè gbé Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin fún arákùnrin nígbàkigbà tó bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí i pé, bá a bá sàmì yìí (*) síwájú ẹṣin ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, àwọn arákùnrin ni ká yàn án fún kí wọ́n lè sọ ọ́ bí àsọyé.

ÌMỌ̀RÀN: Ìṣẹ́jú kan. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ò ní í sọ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí akẹ́kọ̀ọ́ máa ṣiṣẹ́ lé lórí fún àwùjọ. Lẹ́yìn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kejì, kẹta àti ìkẹrin, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró lórí ohun kan nínú iṣẹ́ náà tó kíyè sí pé ó dára gan-an. Kì í ṣe pé kó kàn kí akẹ́kọ̀ọ́ pé “ó ṣeun,” kàkà bẹ́ẹ̀, kó ṣàlàyé àwọn ìdí pàtó tí ohun tó kíyè sí nínú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà fi wúlò. Bó bá kíyè sí i pé iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan kù síbì kan, lẹ́yìn ìpàdé tàbí nígbà mìíràn, ó tún lè fún un nímọ̀ràn tó máa mú kó tẹ̀ síwájú.

ÀKÓKÒ: Kí akẹ́kọ̀ọ́ kankan má ṣe kọjá àkókò, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ náà má sì ṣe sọ̀rọ̀ kọjá àkókò. Ká fi ọgbọ́n dá Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kejì sí Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin dúró bí àkókò wọn bá ti pé. Bí àwọn arákùnrin tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ níbẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́, ìyẹn ọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kìíní tàbí àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà bá kọjá àkókò, ká fún wọn nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́. Kí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ rí i pé àwọn ò kọjá àkókò. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ yìí látòkèdélẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta [45] láìka orin àti àdúrà mọ́ ọn.

ÌWÉ ÌMỌ̀RÀN Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Èyí wà nínú ìwé tá à ń lò fún ilé ẹ̀kọ́.

OLÙRÀNLỌ́WỌ́ AGBANI-NÍMỌ̀RÀN: Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lè yan alàgbà kan tó tóótun, bó bá wà, láfikún sí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Bí àwọn alàgbà bá pọ̀ nínú ìjọ, a lè máa lo alàgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó tóótun lọ́dọọdún láti ṣe iṣẹ́ yìí. Ojúṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn ni láti máa fún àwọn arákùnrin tó ń bójú tó Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kìíní àti kókó pàtàkì látinú Bíbélì nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́, bó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Kò pọn dandan kó jẹ́ pé gbogbo ìgbà táwọn alàgbà bíi tiẹ̀ àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá bójú tó àwọn iṣẹ́ yìí ni yóò máa gbà wọ́n nímọ̀ràn.

ÀTÚNYẸ̀WÒ ALÁFẸNUSỌ: Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Ní oṣù méjì-méjì, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò máa darí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ. Ṣáájú èyí, a óò gbọ́ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àti àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà, bá a ṣe ṣàlàyé lókè. Àwọn kókó tá a jíròrò nínú ilé ẹ̀kọ́ láàárín oṣù méjì tó ṣáájú, títí kan ti ọ̀sẹ̀ yẹn gan-an ni àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ náà yóò dá lé. Bí àpéjọ àyíká yín bá bọ́ sí ọ̀sẹ̀ àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ, ẹ sún àtúnyẹ̀wò náà (àti ìyókù nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sẹ̀ yẹn) sí ọ̀sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé àpéjọ àyíká yín. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọ̀sẹ̀ yẹn ni kẹ́ ẹ lò ní àpéjọ àyíká. Bí alábòójútó àyíká yóò bá bẹ ìjọ yín wò ní ọ̀sẹ̀ tí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ bọ́ sí, orin, ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àti àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì tó wà fún ọ̀sẹ̀ yẹn ni kẹ́ ẹ lò. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìtọ́ni (tó máa tẹ̀ lé ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ) tó wà fún ọ̀sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e ni kẹ́ ẹ sọ. Ní ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò yẹn, ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àtàwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì tó wà fún ọ̀sẹ̀ yẹn lẹ máa gbọ́, lẹ́yìn náà lẹ ó wá ṣe àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ.

ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ

Jan. 1 Bíbélì kíkà: Aísáyà 24 sí 28 Orin 33

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jẹ́ Kí Wọ́n Rí Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò (be-YR ojú ìwé 158 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Bí Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣe Lè Múra Iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 43 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 44 ìpínrọ̀ 3)

No. 2: Aísáyà 26:1-18

No. 3: td 22A Ìdí Tí Ọlọ́run Ò Fi Fọwọ́ sí Ìjọsìn Àwọn Baba Ńlá

No. 4: Báwo La Ṣe Lè “Gbé Olúwa Jésù Kristi Wọ̀”? (Róòmù 13:14)

Jan. 8 Bíbélì kíkà: Aísáyà 29 sí 33 Orin 42

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jíjẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Bí Ọ̀rọ̀ Náà Ṣe Wúlò (be-YR ojú ìwé 159 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 1: Mímúra Iṣẹ́ Tó Ní Ẹṣin Ọ̀rọ̀ àti Ìgbékalẹ̀ (be-YR ojú ìwé 44 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 46 ìpínrọ̀ 2)

No. 2: Aísáyà 30:1-14

No. 3: td 22B A Lè Bọlá fún Èèyàn, àmọ́ Ọlọ́run Nìkan La Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn

No. 4: Bá A Ṣe Mọ̀ Pé Jèhófà Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọmọdé

Jan. 15 Bíbélì kíkà: Aísáyà 34 sí 37 Orin 222

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Èdè Tó Dára (be-YR ojú ìwé 160 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Máa Ní Irú Èrò Tí Jésù Ní Nípa Ohun Tó Tọ́ Àtèyí Tí Kò Tọ́ (w05-YR 1/1 ojú ìwé 9 àti 10 ìpínrọ̀ 11 sí 15)

No. 2: Aísáyà 34:1-15

No. 3: Ọ̀nà Téèyàn Lè Gbà Nífẹ̀ẹ́ Tó Dénú

No. 4: td 4A Amágẹ́dọ́nì—Ogun Tó Máa Fòpin sí Ìwà Burúkú

Jan. 22 Bíbélì kíkà: Aísáyà 38 sí 42 Orin 61

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Èdè Tó Tètè Ń Yéni (be-YR ojú ìwé 161 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 1: Má Ṣe Jẹ́ Kí Àtakò Dí Ọ Lọ́wọ́ (w05-YR 1/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 16 sí 18)

No. 2: Aísáyà 38:9-22

No. 3: td 4B Ìdí Tí Amágẹ́dọ́nì Fi Jẹ́ Àmì Ìfẹ́ Tí Ọlọ́run Ní sí Wa

No. 4: Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Fura Òdì Sáwọn Èèyàn

Jan. 29 Bíbélì kíkà: Aísáyà 43 sí 46 Orin 113

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Oríṣiríṣi Ọ̀rọ̀ Tó Bá a Mu Rẹ́gí (be-YR ojú ìwé 161 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 162 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Àwọn Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Fara Mọ́ Àwọn Ìdájọ́ Tí Jèhófà Ṣe (w05-YR 2/1 ojú ìwé 23 àti 24 ìpínrọ̀ 4 sí 9)

No. 2: Aísáyà 45:1-14

No. 3: td 17A Ìbatisí—Ohun Kan Tí A Ń Béèrè Lọ́wọ́ Kristẹni

No. 4: a Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí Kristẹni Máa Bá Àwọn Ẹlòmíì Figẹ̀ Wọngẹ̀

Feb. 5 Bíbélì kíkà: Aísáyà 47 sí 51 Orin 79

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ọ̀rọ̀ Tó Ń Tani Jí, Ọ̀rọ̀ Tó Ń Fi Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára Hàn, àti Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlé (be-YR ojú ìwé 163 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 164 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Mú Ká Jẹ́ Ẹni Tó Mọ́, Ó Sì Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Jẹ́ Olóòótọ́ (w05-YR 4/15 ojú ìwé 11 àti 12 ìpínrọ̀ 5 sí 11)

No. 2: Aísáyà 50:1-11

No. 3: td 17B Ìbatisí Kì Í Wẹ Ẹ̀ṣẹ̀ Nù

No. 4: Ǹjẹ́ Bíbélì Ka Fífúnni Lẹ́bùn Léèwọ̀?

Feb. 12 Bíbélì kíkà: Aísáyà 52 sí 57 Orin 139

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Lọ́nà Tó Bá Òfin Gírámà Èdè Mu (be-YR ojú ìwé 164 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 165 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Fún Wa Ní Ìgboyà (w05 4/15-YR ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 12 sí 14)

No. 2: Aísáyà 55:1-13

No. 3: Ìgbé Ayé Rere Lẹni Tó Ń Fi Ọjọ́ Ayé Ẹ̀ Ṣoore Fáwọn Ẹlòmíì Ń Gbé

No. 4: td 8A Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ní Ìmísí

Feb. 19 Bíbélì kíkà: Aísáyà 58 sí 62 Orin 189

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìlapa Èrò (be-YR ojú ìwé 166 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: b Ìgbàlà Fáwọn Tó Yan Ìmọ́lẹ̀ (w03-YR 3/1 ojú ìwé 17 sí 22)

No. 2: Aísáyà 60:1-14

No. 3: Ìdí Tó Fi Yẹ Kó Máa Wu Èèyàn Láti Sìnrú fún Ọlọ́run?

No. 4: td 8B Bíbélì—Ó Jẹ́ Amọ̀nà Wíwúlò fún Ọjọ́ Wa

Feb. 26 Bíbélì kíkà: Aísáyà 63 sí 66 Orin 141

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: To Èrò Rẹ Lẹ́sẹẹsẹ (be-YR ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 168 ìpínrọ̀ 2)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

Mar. 5 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 1 sí 4 Orin 70

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìlapa Èrò Rẹ Lọ́jú Pọ̀ (be-YR ojú ìwé 168 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 169 ìpínrọ̀ 5)

No. 1: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Jeremáyà Lókun (w04-YR 5/1 ojú ìwé 8 àti 9 ìpínrọ̀ 5 sí 7)

No. 2: Jeremáyà 3:1-13

No. 3: Kí Ló Máa Ń Jẹ́ Kéèyàn Ní Ayọ̀ Gidi?

No. 4: td 8D Bíbélì—Ìwé Kan Tó Wà fún Gbogbo Èèyàn?

Mar. 12 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 5 sí 7 Orin 159

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣíṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Lẹ́sẹẹsẹ (be-YR ojú ìwé 170 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 171 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Mímúra Ọ̀rọ̀ Tó O Máa Sọ fún Ìjọ Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 47 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 49 ìpínrọ̀ 1)

No. 2: Jeremáyà 2:1-14

No. 3: td 11A Gbígba Ẹ̀jẹ̀ Sára Rú Òfin Ìjẹ́mímọ́ Ẹ̀jẹ̀

No. 4: Bá A Ṣe Lè Lo Ẹ̀kọ́ Tó Wà Nínú Ẹ́kísódù 14:11, ní Àkókò Tá A Wà Yìí

Mar. 19 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 8 sí 11 Orin 182

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Gbé Ìsọfúnni Jáde Lẹ́sẹẹsẹ (be-YR ojú ìwé 171 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 172 ìpínrọ̀ 5)

No. 1: Bá A Ṣe Lè Múra Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Àtàwọn Àsọyé Mìíràn Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 49 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 51 ìpínrọ̀ 2)

No. 2: Jeremáyà 10:1-16

No. 3: Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Ábúráhámù, Jóòbù àti Dáníẹ́lì Gbà Gbọ́ Nínú Àjíǹde?

No. 4: td 11B Ṣé Ọ̀nà Èyíkéyìí Lèèyàn Lè Gbà Wá Bó Ṣe Máa Gba Ẹ̀mí Ẹ̀ Là?

Mar. 26 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 12 sí 16 Orin 205

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Kìkì Ọ̀rọ̀ Tó Bá Yẹ Nìkan Ni Kó O Lò (be-YR ojú ìwé 173 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 1: Ìràpadà Túbọ̀ Fi Òdodo Ọlọ́run Hàn (w05-YR 11/1 ojú ìwé 13 àti 14)

No. 2: Jeremáyà 12:1-13

No. 3: td 30A Ìgbà Wo Ni Àkókò Àwọn Kèfèrí Dópin?

No. 4: Kí Ló Yẹ Kó Jẹ́ Ìdùnnú Kristẹni?

Apr. 2 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 17 sí 21 Orin 30

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Láìgbáralé Àkọsílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 174 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 175 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Mímúra Àsọyé Fún Gbogbo Ènìyàn Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 52 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 54 ìpínrọ̀ 1)

No. 2: Jeremáyà 20:1-13

No. 3: td 43A Kí Ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni?

No. 4: c Ojú Wo Ló Yẹ Ká Máa Fi Wo Ìbáwí?

Apr. 9 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 22 sí 24 Orin 184

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Yàgò fún Ọ̀fìn Tó Wà Nínú Sísọ̀rọ̀ Láìgbáralé Àkọsílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 175 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 177 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Àwọn Ìpinnu Tí Alásọyé Yóò Ṣe (be-YR ojú ìwé 54 ìpínrọ̀ 2 sí 4; àpótí tó wà lójú ìwé 55)

No. 2: Jeremáyà 23:1-14

No. 3: Ìdí Tá A Fi Máa Ń Láyọ̀ Nígbà Tá A Bá Kópa Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa

No. 4: td 43B Ṣé Pétérù Ni “Àpáta Ràbàtà” Náà?

Apr. 16 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 25 sí 28 Orin 27

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Nígbà Táwọn Èèyàn Bá Ní Ká Ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 177 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 178 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: Kọ́ Bá A Ṣe Ń Jẹ́ Olùkọ́ Tó Múná Dóko (be-YR ojú ìwé 56 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 57 ìpínrọ̀ 2)

No. 2: Jeremáyà 26:1-15

No. 3: td 29A Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Tòótọ́ Ti Àkọsílẹ̀ Bíbélì Nípa Ìṣẹ̀dá Lẹ́yìn

No. 4: Kí Ni Bí Ọlọ́run Ṣe Gégùn-ún fún Ilẹ̀ Túmọ̀ Sí? (Jẹ́n. 3:17)

Apr. 23 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 29 sí 31 Orin 148

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ bí Ẹní Ń Báni Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ (be-YR ojú ìwé 179 àti 180)

No. 1: “Fi Ìyàtọ̀” Hàn (be-YR ojú ìwé 57 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 58 ìpínrọ̀ 2)

No. 2: Jeremáyà 31:1-14

No. 3: Kí Nìdí Tí Títóbi Jèhófà Ò Fi Láfiwé?

No. 4: td 29B Ṣé Ọjọ́ Oníwákàtí Mẹ́rìnlélógún Ni Ọjọ́ Ìṣẹ̀dá?

Apr. 30 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 32 sí 34 Orin 100

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìró Ohùn (be-YR ojú ìwé 181 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

May 7 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 35 sí 38 Orin 165

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Darí Afẹ́fẹ́ Tó Ò Ń Mí Sínú Sóde Bó Ṣe Tọ́ (be-YR ojú ìwé 181 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 184 ìpínrọ̀ 1; àpótí tó wà lójú ìwé 182)

No. 1: Mú Kí Àwọn Olùgbọ́ Rẹ Ronú (be-YR ojú ìwé 58 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 59 ìpínrọ̀ 3)

No. 2: Jeremáyà 36:1-13

No. 3: td 2A Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú Sí?

No. 4: Báwo Làwọn Kristẹni Ṣe Lè Kojú Iyèméjì

May 14 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 39 sí 43 Orin 56

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Dẹ Àwọn Iṣan Ara Tó Le (be-YR ojú ìwé 184 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 185 ìpínrọ̀ 2; àpótí tó wà lójú ìwé 184)

No. 1: Sọ Bí Wọ́n Á Ṣe Lò Ó, Kó O sì Fi Àpẹẹrẹ Rere Lélẹ̀ (be-YR ojú ìwé 60 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 61 ìpínrọ̀ 3)

No. 2: Jeremáyà 39:1-14

No. 3: td 2B Ṣó Tọ́ Káwọn Kristẹni Máa Jọ́sìn Àgbélébùú?

No. 4: d Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Fi Ní Láti Jẹ́ Kí Ìfẹ́sọ́nà Wọn Wà Láìlábààwọ́n?

May 21 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 44 sí 48 Orin 122

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bó O Ṣe Lè Fi Hàn Pé Ire Àwọn Ẹlòmíràn Ń Jẹ Ọ́ Lógún (be-YR ojú ìwé 186 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 1: Bá A Ṣe Lè Mú Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ Sunwọ̀n Sí I (be-YR ojú ìwé 62 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 64 ìpínrọ̀ 1)

No. 2: Jeremáyà 46:1-17

No. 3: Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Tan Ara Ẹ̀ Jẹ, Kí La sì Lè Ṣe Tá A Ò Fi Ní Í Máa Tan Ara Wa Jẹ?

No. 4: td 24A Kí Ni Okùnfà Ikú?

May 28 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 49 àti 50 Orin 95

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Máa Tẹ́tí Sílẹ̀ Bẹ̀lẹ̀jẹ́ (be-YR ojú ìwé 187 ìpínrọ̀ 1 sí 5)

No. 1: Bá A Ṣe Lè Máa Bá Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Lọ (be-YR ojú ìwé 64 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 65 ìpínrọ̀ 4)

No. 2: Jeremáyà 49:14-27.

No. 3: td 24B Ṣé Àwọn Òkú Lè Pa Ọ́ Lára?

No. 4: Kí Nìdí Táwọn Òbí Fi Gbọ́dọ̀ Máa Kàwé sí Ọmọ Wọn Létí?

June 4 Bíbélì kíkà: Jeremáyà 51 àti 52 Orin 166

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Tẹ̀ Síwájú (be-YR ojú ìwé 187 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 188 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: Ẹ Máa Mú Sùúrù Bíi Ti Jeremáyà (w06-YR 2/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 14 sí 16)

No. 2: Jeremáyà 52:1-16

No. 3: Òmùgọ̀ Lẹni Tí Ò Bá Fi Ti Ọlọ́run Ṣe

No. 4: td 24D Ṣé Èèyàn Lè Bá Mọ̀lẹ́bí Rẹ̀ Tó Ti Kú Sọ̀rọ̀?

June 11 Bíbélì kíkà: Ìdárò 1 àti 2 Orin 129

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣèrànwọ́ fún Wọn Nípa Ti Ara (be-YR ojú ìwé 188 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 189 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Jèhófà Ń Fúnni Ní Ìrètí Láàárín Ìkárísọ—Apá 1 (w88-YR 9/1 ojú ìwé 26)

No. 2: Ìdárò 2:1-10

No. 3: td 10A Ṣé Èṣù Wà Lóòótọ́?

No. 4: Inúure Tòótọ́ Kì Í Ṣe Ìwà Òmùgọ̀

June 18 Bíbélì kíkà: Ìdárò 3 sí 5 Orin 140

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bíbọ̀wọ̀fúnni (be-YR ojú ìwé 190 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 1: Jèhófà Ń Fúnni Ní Ìrètí Láàárín Ìkárísọ—Apá 2 (w88-YR 9/1 ojú ìwé 27)

No. 2: Ìdárò 4:1-13

No. 3: td 10B Èṣù Ni Ẹni Tá Ò Lè Rí Tó Ń Ṣàkóso Ayé

No. 4: e Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Fi Í Ṣòṣèlú

June 25 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 1 sí 5 Orin 1

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Yíyẹ́nisí (be-YR ojú ìwé 191 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 192 ìpínrọ̀ 1)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

July 2 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 6 sí 10 Orin 26

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fífi Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Bá Àwùjọ Sọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 192 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 193 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: f “Fi Ọkàn-àyà Rẹ sí” Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run! (w99-YR 3/1 ojú ìwé 8 sí 13)

No. 2: Ìsíkíẹ́lì 7:1-13

No. 3: Ọ̀nà Wo Lèèyàn Lè Gbà Sún Mọ́ Jèhófà? (Ják. 4:8)

No. 4: td 10D Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì Tó Ṣọ̀tẹ̀

July 9 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 11 sí 14 Orin 112

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fífi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 194 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 195 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Nínú Ṣíṣe Ohun Tó Dára (w05-YR 6/1 ojú ìwé 29 àti 30)

No. 2: Ìsíkíẹ́lì 11:1-13

No. 3: td 25A Ọlọ́run Dá Ilẹ̀ Ayé Láti Di Párádísè

No. 4: Kí Ni Ìtumọ̀ Ìṣípayá 17:9-11?

July 16 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 15 sí 17 Orin 29

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí A Ṣe Ń Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Dáni Lójú (be-YR ojú ìwé 195 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 196 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Má Ṣe Fàyè Gba Èrò Òdì! (w05-YR 9/15 ojú ìwé 26 sí 28)

No. 2: Ìsíkíẹ́lì 16:1-13

No. 3: Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Afọgbọ́nhùwà? (Òwe 13:16)

No. 4: td 25B Ohun Alààyè Kò Ní Í Tán Lórí Ilẹ̀ Ayé

July 23 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 18 sí 20 Orin 193

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lo Ọgbọ́n Inú Síbẹ̀ Dúró Lórí Òtítọ́ (be-YR ojú ìwé 197 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Fòye Mọ Èrò Ọkàn Ẹni Tó Béèrè Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 66 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 68 ìpínrọ̀ 1)

No. 2: Ìsíkíẹ́lì 18:19-29

No. 3: td 44A Ṣó O Lè Dá Àwọn Wòlíì Èké Mọ̀?

No. 4: Ẹ̀rí Pé Ìjọba Ọlọ́run Máa Dé Dandan

July 30 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 21 sí 23 Orin 35

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ọgbọ́n Inú Nígbà Tá A Bá Ń Wàásù (be-YR ojú ìwé 197 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 199 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Mọ Bó Ṣe Yẹ Kó O Dáhùn (be-YR ojú ìwé 68 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 70 ìpínrọ̀ 3)

No. 2: Ìsíkíẹ́lì 23:1-17

No. 3: td 32A Àǹfààní Wo Ló Wà Nínú Ìwòsàn Tẹ̀mí?

No. 4: Ojú Wo Ló Yẹ Kéèyàn Máa Fi Wo Ipò Ọlá?

Aug. 6 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 24 sí 27 Orin 37

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ọ̀rọ̀ Tó Tọ́ Lásìkò Tó Yẹ (be-YR ojú ìwé 199 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 200 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Fífi Lẹ́tà Báni Sọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 71 sí 73)

No. 2: Ìsíkíẹ́lì 24:1-14

No. 3: Àwọn Ọ̀nà Wo Ni Mósè Gbà Jẹ́ Àpẹẹrẹ Tó Dára Gan-an Fáwọn Kristẹni?

No. 4: td 32B Ìjọba Ọlọ́run Ni Yóò Mú Ìwòsàn Ti Ara Wíwàpẹ́títí Wá

Aug. 13 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 28 sí 31 Orin 123

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ọgbọ́n Inú Nígbà Tá A bá Wà Pẹ̀lú Àwọn Mìíràn (be-YR ojú ìwé 200 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 201 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Máa Tẹ̀ Síwájú (be-YR ojú ìwé 74 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 75 ìpínrọ̀ 3)

No. 2: Ìsíkíẹ́lì 28:1-16

No. 3: td 32D Ìgbàgbọ́ Wò-Ó-Sàn Òde Òní Kò Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

No. 4: Kí Ni Ìwé Mímọ́ Pè Ní “Ìkórìíra?”

Aug. 20 Bíbélì kíkà: Ísíkíẹ́lì 32 sí 34 Orin 215

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sọ Ohun Tó Ń gbéni Ró Tó sì Ṣàǹfààní (be-YR ojú ìwé 202 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 203 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Lo Ẹ̀bùn Rẹ̀ (be-YR ojú ìwé 75 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 77 ìpínrọ̀ 2)

No. 2: Ísíkíẹ́lì 34:1-14

No. 3: Báwo Ni Ẹ̀mí Ọlọ́run Ṣe Lè Ràn Wá Lọ́wọ́?

No. 4: td 32E Ṣé Sísọ̀rọ̀ ní Àwọn Ahọ́n Àjèjì Ni Ẹ̀rí Pé Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gba Ìjọsìn Ẹni?

Aug. 27 Bíbélì kíkà: Ísíkíẹ́lì 35 sí 38 Orin 94

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sọ̀rọ̀ Lọ́nà Tí Wọ́n Yóò Fi Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ (be-YR ojú ìwé 203 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 204 ìpínrọ̀ 1)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

Sept. 3 Bíbélì kíkà: Ísíkíẹ́lì 39 sí 41 Orin 194

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Nígbà Tá A bá Ń Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Onígbàgbọ́ Ẹlẹgbẹ́ Wa (be-YR ojú ìwé 204 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 205 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (w05-YR 4/15 ojú ìwé 15 àti 16 ìpínrọ̀ 3 sí 6)

No. 2: Ísíkíẹ́lì 40:1-15

No. 3: Ṣó Ṣeé Ṣe Kéèyàn Múnú Ọlọ́run Dùn?

No. 4: td 41A Àwọn Wo Ló Ń Lọ Sọ́run?

Sept. 10 Bíbélì kíkà: Ísíkíẹ́lì 42 sí 45 Orin 77

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ Àsọtúnsọ Láti Tẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 206 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 1: Ohun Tó Ń Mú Kí Ọjọ́ Ogbó Jẹ́ “Adé Ẹwà” (w05-YR 1/15 ojú ìwé 8 àti 9)

No. 2: Ísíkíẹ́lì 43:1-12

No. 3: td 16A Hẹ́ẹ̀lì Kì Í Ṣe Ibi Ìdálóró

No. 4: g Báwo La Ṣe Lè Dá “Ohùn Àwọn Àjèjì” Mọ̀? (John 10:5)

Sept. 17 Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 46 sí 48 Orin 164

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ Àsọtúnsọ Lóde Ẹ̀rí àti Nígbà Tó O Bá Ń Sọ Àsọyé (be-YR ojú ìwé 207 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 208 ìpínrọ̀ 3)

No. 1: h Ìbùkún Jèhófà Lórí “Ilẹ̀” Wa (w99-YR 3/1 ojú ìwé 18 sí 23)

No. 2: Ísíkíẹ́lì 47:1-14

No. 3: td 16B Ìparun Yán-án yán-án Ni Iná Ṣàpẹẹrẹ

No. 4: i Kí Nìdí Tó Fi Jẹ́ Pé Ogún Tẹ̀mí Ni Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Lọ Táwọn Òbí Lè fún Àwọn Ọmọ Wọn

Sept. 24 Bíbélì kíkà: Dáníẹ́lì 1 sí 3 Orin 179

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣíṣàlàyé Ẹṣin Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 209 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: j Nígbà Tí Jèhófà Kọ́ Àwọn Ọba-Olùṣàkóso Ní Àwọn Ẹ̀kọ́-Àríkọ́gbọ́n (w88-YR 12/1 ojú ìwé 10 sí 14)

No. 2: Dáníẹ́lì 2:1-16

No. 3: Kí Nìdí Tá A Fi Lè Sọ Pé Nọ́ńbà Gidi Ni Ọ̀kẹ́ Méje Ó Lé Ẹgbàajì? (Ìṣí. 7:4)

No. 4: td 16D Ìròyìn Nípa Ọkùnrin Ọlọ́rọ̀ àti Lásárù Kì Í Ṣe Ẹ̀rí Ìdálóró Ayérayé

Oct. 1 Bíbélì kíkà: Dáníẹ́lì 4 sí 6 Orin 14

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: LíLo Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Tó Bá A Mu (be-YR ojú ìwé 210 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 211 ìpínrọ̀ 1 àti àpótí tó wà lójú ìwé 211)

No. 1: Ìgbà Wo Ló Yẹ Kéèyàn Bínú? (w05-YR 8/1 ojú ìwé 13 sí 15)

No. 2: Dáníẹ́lì 4:1-17

No. 3: Ọ̀nà Wo La Lè Gbà Fara Wé Ànímọ́ Rere Tí Mefibóṣẹ́tì Ní?

No. 4: td 38A Ojú ìwòye Kristẹni Nípa Àwọn Àjọ̀dún

Oct. 8 Bíbélì kíkà: Dáníẹ́lì 7 sí 9 Orin 34

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Mú Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere (be-YR ojú ìwé 212 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 213 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Jẹ́ Kí “Àsọjáde” Jèhófà Máa Ṣọ́ Ọ (w05-YR 9/1 ojú ìwé 28 sí 31)

No. 2: Dáníẹ́lì 7:1-12

No. 3: td 9A Lílo Ère Jẹ́ Rírín Ọlọ́run Fín

No. 4: Ayọ̀ Tí Ò Lẹ́gbẹ́ Wo Ló Wà Nínú Kéèyàn Máa Kópa Déédéé Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Pápá?

Oct. 15 Bíbélì kíkà: Dáníẹ́lì 10 sí 12 Orin 210

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Má Ṣe Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Rẹ Pọ̀ Jù (be-YR ojú ìwé 213 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 214 ìpínrọ̀ 5)

No. 1: k Jèhófà Ń San –Èrè Ẹ̀san fún Ìgbàgbọ́ àti Ìgboyà (w88-YR 12/1 ojú ìwé 14 sí 20)

No. 2: Dáníẹ́lì 11:1-14

No. 3: Bí Ìrẹ̀lẹ̀ Ṣe Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Borí Àìgbọ́ra-Ẹni-Yé

No. 4: td 9B Àwọn Ohun Tí Ìjọsìn Ère Máa Ń Fà

Oct. 22 Bíbélì kíkà: Hóséà 1 sí 7 Orin 66

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 215 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 216 ìpínrọ̀ 5)

No. 1: Jèhófà Ọlọ́run Wa Jẹ́ Aláàánú (w89-YR 3/1 ojú ìwé 14 àti 15)

No. 2: Hóséà 5:1-15

No. 3: td 9D Ọlọ́run Nìkan Ṣoṣo La Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn

No. 4: Àwọn Ọ̀nà Tí Kristẹni Kan Lè Gbà Fi Hàn Pé Òun ní Sùúrù

Oct. 29 Bíbélì kíkà: Hóséà 8 sí 14 Orin 59

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí O Ṣe Lè Gba Àfiyèsí Àwọn Èèyàn Lóde Ẹ̀rí (be-YR ojú ìwé 217 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

Nov. 5 Bíbélì kíkà: Jóẹ́lì 1 sí 3 Orin 166

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Níbẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ Ni Kó O Ti Sọ Kókó Tó O Fẹ́ Sọ̀rọ̀ Lé Lórí (be-YR ojú ìwé 217 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 219 ìpínrọ̀ 2)

No. 1: Ké Pe Orúkọ Jèhófà Kí O sì Sálà Láìséwu! (w89-YR 3/15 ojú ìwé 30 àti 31)

No. 2: Jóẹ́lì 2:1-14

No. 3: Ohun Tó Túmọ̀ sí Láti ní “Ìfẹ́ Pípé” (1 Jòh. 4:18)

No. 4: l td 5B Ṣé Gbogbo Ìsìn Ló Dárá?

Nov. 12 Bíbélì kíkà: Ámósì 1 sí 9 Orin 211

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìparí Ọ̀rọ̀ Múná Dóko (be-YR ojú ìwé 220 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Ìyámútù Orílẹ̀-Èdè Kan (w89-YR 4/1 ojú ìwé 22 sí 23)

No. 2: Ámósì 2:1-16

No. 3: Ìdí Tí Kì Í Fi Í Ṣòótọ́ Pé Bí Kò Ṣeni A Kì Í Gbọ́n

No. 4: td 34A Àwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Máa Lo Orúkọ Tí Ọlọ́run Ń Jẹ́

Nov. 19 Bíbélì kíkà: Ọbadáyà 1 sí Jónà 4 Orin 220

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Àwọn Kókó Tó Yẹ Kó O Fi Sọ́kàn (be-YR ojú ìwé 220 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 221 ìpínrọ̀ 4)

No. 1: Àwọn Ìkìlọ Àtọrunwá Tí Ó Kàn Ọ́ (w89-YR 4/15 ojú ìwé 30 sí 31)

No. 2: Jónà 1:1-17

No. 3: td 34B Òtítọ́ Nípa Wíwà Ọlọ́run

No. 4: Ìdí Tí Párádísè Tẹ̀mí Fi Gbọ́dọ̀ Ṣíwájú Párádísè Ilẹ̀ Ayé?

Nov. 26 Bíbélì kíkà: Míkà 1 sí 7 Orin 18

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lóde Ẹ̀rí (be-YR ojú ìwé 221 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 222 ìpínrọ̀ 6)

No. 1: A Gbé Ìdájọ́-Òdodo àti Orúkọ Jèhófà Ga (w89-YR 5/1 ojú ìwé 14 àti 15)

No. 2: Míkà 2:1-13

No. 3: Ohun Tó Túmọ̀ sí Láti Jẹ́ Oníwà Tútù

No. 4: td 34D #Bá A Ṣe Lè Dá Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run Mọ̀

Dec. 3 Bíbélì kíkà: Náhúmù 1 sí Hábákúkù 3 Orin 137

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ọ̀rọ̀ Tó Jóòótọ́ Délẹ̀ (be-YR ojú ìwé 223 ìpínrọ̀ 1 sí 5)

No. 1: Ìgbàlà Ṣeé Ṣe Nígbà Tí Ọlọ́run Bá Gbẹ̀san (w89-YR 5/15 ojú ìwé 24 sí 25)

No. 2: Hábákúkù 1:1-17

No. 3: td 34E Kì Í Ṣe Gbogbo Èèyàn Ló Ń Sin Ọlọ́run Kan Náà

No. 4: Ìdí Tí Ìyè Àìnípẹ̀kun Ò Fi Ní Súni

Dec. 10 Bíbélì kíkà: Sefanáyà 1 sí Hágáì 2 Orin 78

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: “Ẹni Tó Ń Di Ọ̀rọ̀ Ṣíṣeégbíyèlé Mú Ṣinṣin” (be-YR ojú ìwé 224 ìpínrọ̀ 1 sí 4)

No. 1: Wá Jèhófà Kí O Sì Ṣiṣẹ́sìn Ín Tọkàntara (w89-YR 6/1 ojú ìwé 30 àti 31)

No. 2: Sefanáyà 3:1-17

No. 3: td 12A Ṣe Ẹ̀sìn Tuntun Ni Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

No. 4: a Oore Wo Ló Máa Ṣe Àwọn Tọkọtaya Kan Bí Wọ́n Bá Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run?

Dec. 17 Bíbélì kíkà: Sekaráyà 1 sí 8 Orin 209

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣíṣèwádìí bí Ìsọfúnni Tó O Rí Ṣe Jóòótọ́ Sí (be-YR ojú ìwé 225 ìpínrọ̀ 1 sí 3)

No. 1: Jèhófà Ru Ẹ̀mí Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Sókè (w89-YR 6/15 ojú ìwé 30 àti 31)

No. 2: Sekaráyà 7:1-14

No. 3: Ọ̀nà Wo Ni Ìran Ológo Gbà Nímùúṣẹ?

No. 4: td 35A Jésù Kristi—Ọmọ Ọlọ́run àti Ọba Tí A Yàn

Dec. 24 Bíbélì kíkà: Sekaráyà 9 sí 14 Orin 202

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jẹ́ Kí Àlàyé Ọ̀rọ̀ Rẹ Yéni (be-YR ojú ìwé 226 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 227 ìpínrọ̀ 1)

No. 1: Olúwa Tòótọ́ Náà Dé fún Ìdájọ́ (w89-YR 7/1 ojú ìwé 30 àti 31)

No. 2: Sekaráyà 10:1-12

No. 3: td 35B Ìdí Tí Gbígbàgbọ́ Nínú Jésù Fi Ṣe Kókó fún Ìgbàlà

No. 4: Ọ̀nà Wo La Lè Gbà Múra Sílẹ̀ de Inúnibíni?

Dec. 31 Bible reading: Málákì 1 sí 4 Orin 118

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣàlàyé Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Ò Bá Yé Àwùjọ (be-YR ojú ìwé 227 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 228 ìpínrọ̀ 1)

Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yàn án fún.

b Mú àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu látinú ibi tá a ti múṣẹ́ jáde.

c Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yàn án fún.

d Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yàn án fún.

e Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yàn án fún.

f Mú àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu látinú ibi tá a ti múṣẹ́ jáde.

g Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yàn án fún.

h Mú àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu látinú ibi tá a ti múṣẹ́ jáde.

i Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yàn án fún.

j Mú àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu látinú ibi tá a ti múṣẹ́ jáde.

k Mú àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu látinú ibi tá a ti múṣẹ́ jáde.

l Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yàn án fún.

a Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yàn án fún.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́