Máa Lo Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tó Gbéṣẹ́
1. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú bí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe máa ń lo onírúurú ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀?
1 Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní wàásù fún àwọn èèyàn tí àṣà àti ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra. (Kól. 1:23) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run kan náà ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, onírúurú ọ̀nà ni wọ́n gbà ń gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀, èyí sinmi lórí àwọn ẹni tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Pétérù ń bá àwọn Júù kan tí wọ́n ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ wòlíì Jóẹ́lì ló fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Ìṣe 2:14-17) Àmọ́, kíyè sí bí Pọ́ọ̀lù ṣe ronú jinlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ará ìlú Gíríìsì bó ṣe wà nínú ìwé Ìṣe 17:22-31. Lóde òní, àwọn èèyàn kan láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wa máa ń ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ìwé Mímọ́, èyí mú kó rọrùn fún wa láti máa ka Bíbélì fún wọn bá a ti ń lọ láti ilé dé ilé. Àmọ́ ṣá o, ó máa gba pé ká túbọ̀ lo ìfòyemọ̀ nígbà tá a bá ń bá àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì sọ̀rọ̀ tàbí àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn àtàwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristi.
2. Báwo la ṣe lè lo ìwé tá a fi ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí láti ran àwọn tó mọyì Bíbélì àtàwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì lọ́wọ́?
2 Máa Lo Àwọn Ìwé Tá A Fi Ń Ṣiṣẹ́ Lọ́nà Tó Dára: Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn yìí, oṣù méjì-méjì ni a ó máa yí ìwé tí a fi ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí pa dà, àwọn ìwé ìròyìn wa, ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé pẹlẹbẹ sì máa wà lára àwọn ìwé náà. Bí àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa kò bá tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, a ṣì lè bá wọn sọ ohun tó máa fà wọ́n lọ́kàn mọ́ra. Bí a kò bá tiẹ̀ ka Bíbélì tàbí ká sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ ẹni náà wò, bí ẹni náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ tí a bá a sọ, a lè pa dà lọ láti ràn án lọ́wọ́ kó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìgbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá àti Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. Àmọ́ ṣá o, tó bá jẹ́ pé ibi táwọn èèyàn ti mọyì Bíbélì la ti ń wàásù, a lè lo àwọn ìwé wa, ká sì tún fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Bíbélì. Kódà, a lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, nígbàkigbà tá a bá rí i pé ó yẹ, bí kì í bá tiẹ̀ ṣe àwọn ìwé yìí la fi ń ṣiṣẹ́ ní òde ẹ̀rí lóṣù náà. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká máa gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ lọ́nà tá a mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
3. Ọ̀nà wo ni ọkàn àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa gbà dà bí ilẹ̀ tí àgbẹ̀ máa ń gbin nǹkan sí?
3 Tún Ojú Ilẹ̀ Ṣe: A lè fi ọkàn àwọn èèyàn wé ilẹ̀ tí àgbẹ̀ máa ń gbin nǹkan sí. (Máàkù 4:26) Àwọn ilẹ̀ kan máa ń nílò àtúnṣe tó pọ̀ ju àwọn ilẹ̀ míì lọ, kí irúgbìn ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì tó lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ níbẹ̀ kó sì máa dàgbà. Àwọn tó wàásù ìhìn rere ní ọ̀rúndún kìíní gbin irúgbìn òtítọ́ sí onírúurú ilẹ̀, wọ́n sì ṣàṣeyọrí, èyí jẹ́ kí wọ́n ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. (Ìṣe 13:48, 52) Àwa náà lè ṣàṣeyọrí bíi tiwọn tá a bá ń fiyè sí bá a ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀.