Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 17
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 17
Orin 49 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 26 ìpínrọ̀ 16 sí 22, àti àpótí tó wà lójú ìwé 209 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 46-48 (10 min.)
No. 1: Ìsíkíẹ́lì 48:1-14 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Aláìlábòsí Nínú Ohun Gbogbo—Éfé. 4:25, 28; 5:1 (5 min.)
No. 3: Àwọn Àdúrà Tí Ọlọ́run Ń Gbọ́—td 1A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
30 min: “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? (Apá Kìíní)” Ìbéèrè àti ìdáhùn tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 2010, ojú ìwé 12. Ní ṣókí, lo ìsọfúnni tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú Ìṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí láti nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Kó o wá lo àwọn ìbéèrè tó wà ní ìpínrọ̀ 1 sí 11 nínú ìwé ìròyìn náà láti darí ìjíròrò yìí. Lẹ́yìn náà, kó o fi ìsọfúnni tó wà ní ìpínrọ̀ kejì nínú Ìṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa kádìí ọ̀rọ̀ rẹ.
Orin 88 àti Àdúrà