Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? (Apá Kìíní)
Bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń di àgbàlagbà, wọ́n ní láti ṣe àwọn ìpinnu kan tó ṣe pàtàkì. Bíbélì dà bí ìwé atọ́nà tó lè jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ mọ ọ̀nà tí wọ́n máa tọ̀. (Òwe 3:5, 6) Bí àwọn ọ̀dọ́ bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wọn bó ṣe yẹ, èyí máa ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an ní ti pé kò ní jẹ́ kí wọ́n yà bàrá kúrò lójú ọ̀nà ìyè. (Róòmù 2:15) Yóò sì máa tọ́ wọn sọ́nà. Bí wọ́n bá ṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́, èyí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe?” nínú Ilé Ìṣọ́ November 15, 2010, èyí á túbọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì. Wò ó ná bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà fún ìpínrọ̀ 1 sí 11 nínú àpilẹ̀kọ náà.
À rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ ṣàyẹ̀wò àwọn ìpínrọ̀ yòókù nínú àpilẹ̀kọ náà, kẹ́ ẹ sì múra sílẹ̀ láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀ nígbà tá a bá ń jíròrò rẹ̀ nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. A tún rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ ka ìwé àṣàrò kúkúrú tá a pe àkòrí rẹ̀ ní Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? Kẹ́ ẹ sì wo fídíò wa tó dá lórí ohun táwọn ọ̀dọ́ lè fi ìgbésí ayé wọn ṣe, ìyẹn Youths—What Will You Do With Your Life? Àwọn ìsọfúnni tó wúlò gan-an fún àwọn ọ̀dọ̀ ló wà nínú fídíò àti ìwé àṣàrò kúkúrú náà.