Báwo Lo Ṣe Máa Lo Ìgbésí Ayé Ẹ?
1 Ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń bi àwọn ọmọdé ni pé, “Iṣẹ́ wo lo fẹ́ ṣe bó o bá dàgbà?” Bó bá jẹ́ ọkùnrin ni ẹ́, iṣẹ́ wo lo sọ pó wù ẹ́? Ṣé iṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù ni, iṣẹ́ dókítà àbí iṣẹ́ alábòójútó àyíká? Bó bá sì jẹ́ obìnrin ni ẹ́, ṣe iṣẹ́ olùkọ́ lo sọ pó wù ẹ́, ṣé iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ni, àbí iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì? Ní báyìí tó o ti wá dàgbà sí i, ó yẹ kó o bi ara ẹ ní ìbéèrè míì pé, ‘Kí ni màá fi ayé mi ṣe?’ Ṣó o ti ṣe tán láti pinnu báyìí?
2 Kó o bàa lè ṣe ìpinnu tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ jù lọ, ètò Jèhófà ti ṣe awo DVD kan tí wọ́n pè ní Young People Ask—What Will I Do With My Life? Jọ̀wọ́, rí i pé o wò ó kó o sì ronú le ohun tó o bá wò níbẹ̀ dáadáa, ì báà jẹ́ àwòkẹ́kọ̀ọ́, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tàbí àwọn àlàyé tá a fi ṣe àfikún sí i. Àwọn nǹkan tó o lè rí wò nínú àwo DVD náà wà níbi tí wọ́n kọ “Main Menu” sí.
3 Àwòkẹ́kọ̀ọ́: Bó o ṣe ń wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, máa ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí: (1) Àwọn nǹkan wo ló mú kí ọ̀rọ̀ Tímótì, tí Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jọ ti Andre? (Ìṣe 16:1; 1 Tím. 4:8; 2 Tím. 1:5) (2) Báwo ni wọ́n ṣe fúngun mọ́ Andre kó bàa lè di gbajúgbajà nídìí eré sísá, àwọn wo ló sì ń fúngun mọ́ ọn? (3) Ta ló ran Tímótì àti Andre lọ́wọ́ táwọn méjèèjì fi lè ṣe ìpinnu tó dáa, láwọn ọ̀nà wo sì ni? (4) Ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Mátíù 6:24 àti Fílípì 3:8 gbà kan Andre, ọ̀nà wo ló sì gbà kan ìwọ náà?
4 Àwọn Ìran Tí Wàá Tún Wò: Bó o bá ti wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà tán látòkèdélẹ̀, tún àwọn ìran wọ̀nyí wò kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. “Paul and Timothy” (Pọ́ọ̀lù àti Tímótì): Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ni Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì kẹ́yìn? (2 Tím. 4:5) “Giving Jehovah Your Best” (Fi Gbogbo Ayé Rẹ fún Jèhófà): Èwo lo yàn láti ṣe lára àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wà? “Taking a Stand for Jehovah” (Bó O Ṣe Lè Pinnu Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà): Ibo lèèyàn ti lè rí ojúlówó ayọ̀? “Grandmother’s Advice” (Ìmọ̀ràn Ìyá Àgbà): Kí ló burú nínú kéèyàn fẹ́ di gbajúgbajà nínú ayé Sátánì yìí? (Mát. 4:9) “No Regrets” (Mi Ò Kábàámọ̀): Kí ni wọ́n wá mọ̀ níkẹyìn tó lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe yẹ kó o lo ìgbésí ayé ẹ?—Òwe 10:22.
5 Interviews (Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò): Bó o ṣe ń wo ìsọ̀rí wọ̀nyí níkọ̀ọ̀kan, kí lo rí tó yẹ kó o ṣe bó o bá fẹ́ fi gbogbo ayé ẹ fún Jèhófà? (1) “Dedication to Vain Pursuits or to God?” (Ṣé Ohun Asán Lo Fẹ́ Máa Lépa àbí Wàá Fara Ẹ fún Ọlọ́run?) (1 Jòh. 2:17); (2) “Learning to Enjoy Your Ministry” (Bó O Ṣe Lè Gbádùn Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ) (Sm. 27:14); àti (3) “An Open Door to Service.” (Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tó Wà)—Mát. 6:33.
6 Looking Back (Níníran Ìgbà Tó Ti Kọjá): Ṣó o lè dáhùn? (1) Báwo làwọn ará tó o rí nínú àwo DVD yìí ṣe gbé ìgbé ayé wọn nígbà kan rí, kí ló sì fà á tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? (2) Ǹjẹ́ wọ́n ṣe àṣeyọrí lóòótọ́? (3) Kí ló mú kí kálukú wọn pinnu láti yí bó ṣe ń gbé ìgbé ayé ẹ̀ padà? (2 Kọ́r. 5:15) (4) Èwo lára àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ni wọ́n fi rọ́pò ohun tí wọ́n ń ṣe nígbà kan rí, kí ló sì mú kí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní lè ṣe méjèèjì pa pọ̀? (5) Ǹjẹ́ wọ́n kábàámọ̀ pé àwọn yí báwọn ṣe ń gbé ìgbé ayé àwọn tẹ́lẹ̀ padà? (6) Kí lohun tí wọ́n sọ tó yẹ kó mú kíwọ náà ronú lórí ọ̀nà tí wàá gbà lo ìgbésí ayé ẹ?
7 Supplementary Interviews (Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Síwájú Sí I): Kí lo ti rí kọ́ tó lè jẹ́ kó o túbọ̀ tẹra mọ́ bó o ṣe ń sin Jèhófà látinú àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yìí? (1) “The Value of Personal Study,” (Àǹfààní Ìdákẹ́kọ̀ọ́) (2) “Alternative Witnessing,” (Ìwàásù Àìjẹ́-bí-Àṣà) (3) “Bethel Service,” (Iṣẹ́ Ìsìn Bẹ́tẹ́lì) (4) “Ministerial Training School.” (Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́)—Jíròrò atọ́ka àwọn ibi tá a ti lè rí àlàyé síwájú sí i nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìyẹn “Index to Published Information on Related Subjects,” kó o sì kà nípa èyí tó bá wù ọ́ jù.
8 Níbi tá a dé yìí, ṣó o ti pinnu bó o ṣe máa lo ayé ẹ? Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tím. 4:15) A rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣe ohun tó wà níbàámu pẹ̀lú ohun tó o ti rí àtèyí tó o ti gbọ́ nínú àwo DVD yìí. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe ìpinnu tó máa mú ẹ láyọ̀ tó sì máa jẹ́ kó o lè fi ìgbésí ayé ẹ ṣe ohun tó máa múnú ẹ dùn, bákan náà, kí ìpinnu tó o máa ṣe jẹ́ èyí tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní nísinsìnyí tó sì máa jẹ́ kí ọjọ́ iwájú rẹ dùn bí oyin.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
MAIN MENU (Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Àwo DVD)
Play Drama (Wo Àwòkẹ́kọ̀ọ́)
Scenes (Ìran: Ìsọ̀rí Mọ́kànlá)
Interviews (Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò)
Play All (Wo Gbogbo Ẹ̀)
Sections (Ìsọ̀rí: Mẹ́ta)
Looking Back (Níníran Ìgbà Tó Ti Kọjá)
Supplementary Material (Àlàyé Síwájú Sí I)
Supplementary Interviews (Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Síwájú Sí I)
Atọ́ka àwọn ibi tá a ti lè rí àlàyé síwájú sí i, ìyẹn Index to Published Information on Related Subjects
Subtitles (Ka Ọ̀rọ̀ Inú Eré)
Hearing Impaired (Mi Ò Gbọ́ràn Dáadáa)
None (Mi Ò Fẹ́)
Bó o bá fẹ́ yan èyíkéyìí lára àwọn nǹkan tó wà nínú àwo DVD yìí, tẹ Next (Òmíràn) ▶, ◀ Back (Padà Sẹ́yìn) àti Main Menu.