Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? (Apá Kejì)
Ìwé Oníwàásù 12:1 rọ ẹ̀yin ọ̀dọ́ pé: “Ranti ẹlẹda rẹ nisinsinyìí ni ọjọ èwe rẹ.” (Bibeli Yoruba Atọ́ka) Dájúdájú, ọ̀nà tó dára jù lọ tó o lè gbà lo ìgbésí ayé rẹ ni pé kó o fi ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, ó yẹ kó o kọ́kọ́ kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè kó o tó lè ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Báwo lo ṣe lè kúnjú ìwọ̀n? Kí ni lílo ìgbésí ayé ẹni lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run wé mọ́? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú apá tó ṣẹ́ kù tá a fẹ́ jíròrò báyìí látinú àpilẹ̀kọ tá a gbé yẹ̀ wò lọ́sẹ̀ tó kọjá.
Nígbà míì, àìsàn, ọ̀ràn àtijẹ àtimu tàbí ojúṣe ẹni nínú ìdílé kì í jẹ́ ká lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Síbẹ̀, gbogbo Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ ló gbọ́dọ̀ pa àṣẹ Bíbélì mọ́, pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Jèhófà ń béèrè pé bó bá ti lè ṣeé ṣe fún ẹ tó, kó o ṣe gbogbo ohun tí agbára rẹ bá gbé. Nítorí náà, ipò yòówù kó o wà, jẹ́ kí ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà jẹ́ ohun àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ. Fi àwọn ohun kan tí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ṣe àfojúsùn rẹ. Ó dájú pé tó o bá “ranti ẹlẹda rẹ nisinsinyìí ni ọjọ èwe rẹ,” wàá rí ìbùkún gbà títí láé!