Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 24
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 24
Orin 45 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 27 ìpínrọ̀ 1 sí 9 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Dáníẹ́lì 1-3 (10 min.)
No. 1: Dáníẹ́lì 2:17-30 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí Ọlọ́run Kì Í Fi Í Dáhùn Àwọn Àdúrà Kan—td 1B (5 min.)
No. 3: Báwo La Ṣe Lè Yẹra fún Kíkó Ẹ̀dùn Ọkàn Bá Ẹ̀mí Mímọ́?—Éfé. 4:30 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
30 min: “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? (Apá Kejì)” Ìbéèrè àti ìdáhùn tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 2010, ojú ìwé 14. Ní ṣókí, lo ìsọfúnni tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú Ìṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí láti nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Kó o wá lo àwọn ìbéèrè tó wà ní ìpínrọ̀ 12 sí 20 nínú ìwé ìròyìn náà láti darí ìjíròrò yìí. Lẹ́yìn náà, fi ìsọfúnni tó wà ní ìpínrọ̀ kejì nínú Ìṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa kádìí ọ̀rọ̀ rẹ.
Orin 91 àti Àdúrà