Orin 130
Ìyanu Ni Ìwàláàyè Jẹ́
1. Ọmọ jòjòló, Ọ̀wààrà òjò,
Ìtànṣán oòrùn tí ńtàn, Irè oko,
Gbogbo wọn ló jẹ́ Ẹ̀bùn Ọlọ́run.
Iṣẹ́ àrà rẹ̀ ńgbé wa ró lójoojúmọ́.
(ÈGBÈ)
Kí la ò bá fẹ̀bùn tó ṣọ̀wọ́n yìí ṣe?
Ká tọ́jú ọmọnìkejì wa,
ká nífẹ̀ẹ́ wọn.
Kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe wa Laó fi lè ní ìyè.
Ẹ̀bùn ni ẹ̀mí, Ẹ̀bùn ni títí láé.
Kí la ò bá fẹ̀bùn tó ṣọ̀wọ́n yìí ṣe?
Ká tọ́jú rẹ̀, ká sì nífẹ̀ẹ́
Ẹni tó fún wa.
Kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe wa Laó fi lè ní ìyè.
Ẹ̀bùn ni ẹ̀mí, Ẹ̀bùn ni títí láé.
2. Bó sú àwọn kan, Wọ́n lè sọ̀rọ̀ bí
Aya Jóòbù: “Bú Ọlọ́run kóo sì kú.”
A kò dà bí wọn. A ńyin Ọlọ́run.
A ńdúpẹ́ pé ó dá ẹ̀mí wa sí dòní.
(ÈGBÈ)
Kí la ò bá fẹ̀bùn tó ṣọ̀wọ́n yìí ṣe?
Ká tọ́jú ọmọnìkejì wa,
ká nífẹ̀ẹ́ wọn.
Kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe wa Laó fi lè ní ìyè.
Ẹ̀bùn ni ẹ̀mí, Ẹ̀bùn ni títí láé.
(Tún wo Jóòbù 2:9; Sm. 34:12; Oníw. 8:15; Mát. 22:37-40; Róòmù 6:23.)