Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 22
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 22
Orin 9 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 13 ìpínrọ̀ 11 sí 18 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 30-32 (10 min.)
No. 1: Númérì 32:16-30 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Iye Àwọn Tó Máa Jogún Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé Kò Láàlà—td 33D (5 min.)
No. 3: Kí Ni Yóò Ṣẹlẹ̀ Bí A Bá Kú?—lr orí 34 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Ìgbésí Ayé Àwọn Míṣọ́nnárì Ládùn Gan-an. (Òwe 10:22) Ìjíròrò tá a gbé ka Ìwé Ọdọọdún 2014, ojú ìwé 123, ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 127, ìpínrọ̀ 3 àti ojú ìwé 169. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
15 min: “Máa Lo Ìkànnì jw.org Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ.” Ìjíròrò. Ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà ní ìpínrọ̀ 2. Lẹ́yìn náà, kó o wá bi àwọn ará láwọn ìbéèrè yìí: Àǹfààní wo ló wà níbẹ̀ tí a bá wa fídíò náà jáde tá a sì gbé e sórí ẹ̀rọ alágbèéká wa? Kí nìdí tó fi dáa pé ká tan fídíò náà fún onílé láì ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ̀rọ̀ tó gùn láti fi nasẹ̀ rẹ̀ tàbí ká máa bi onílé pé ṣé ká fi fídíò náà hàn-án? Àwọn ìrírí wo lo ní nígbà tó o lo fídíò yìí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n dojúlùmọ̀ onírúurú apá tí Ìkànnì jw.org ní, kí wọ́n sì máa lò ó lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.
Orin 84 àti Àdúrà