ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 169
  • Orílẹ̀-Èdè Sierra Leone Di Àrímáleèlọ fún Mi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Orílẹ̀-Èdè Sierra Leone Di Àrímáleèlọ fún Mi
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Nípa Lórí Ìgbésí Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • A Pinnu Pé A Ó Máa Sin Jèhófà
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ohun Tó Dára Ju Dáyámọ́ǹdì Lọ
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Jèhófà Dáàbò Bò Mí Torí Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé E
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 169

SIERRA LEONE ÀTI GUINEA

Orílẹ̀-Èdè Sierra Leone Di Àrímáleèlọ fún Mi

Cindy McIntire

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1960

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1974

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó jẹ́ míṣọ́nnárì láti ọdún 1992. Ó ti sìn ní orílẹ̀-èdè Guinea àti Senegal, ó sì ń sìn ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone báyìí.

KÒ JU ọ̀sẹ̀ méjì péré tí mo dé orílẹ̀-èdè Sierra Leone tó fi di ibi àrímáleèlọ fún mi. Ẹnu yà mí báwọn èèyàn ṣe máa ń pàǹtèté ẹrù tó wúwo sórí. Èrò pọ̀ gan-an láàárín ìgboro. Àwọn ọmọdé ń ṣeré kiri, wọ́n ń jó fàlàlà láàárín ìgboro, wọ́n ń pàtẹ́wọ́, wọ́n sì ń fẹsẹ̀ janlẹ̀ pa pọ̀ lọ́nà tó dùn mọ́ni. Oríṣiríṣi nǹkan ẹlẹ́wà àtàwọn tó ń lọ tó ń bọ̀ ni mò ń rí, mo sì ń gbọ́ àwọn orin aládùn.

Àmọ́ ohun tí mo gbádùn jù níbí ni iṣẹ́ ìwàásù tí mò ń ṣe. Àwọn ará ilẹ̀ Sierra Leone kà á sí ohun iyì láti gba èèyàn lálejò tọwọ́ tẹsẹ̀. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún Bíbélì gan-an, wọ́n sì máa ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n máa ń sọ pé kí n wọlé jókòó. Tí mo bá ń lọ, àwọn míì á tún sìn mí síwájú dáadáa kí wọ́n tó pa dà. Àwọn ìwà tó wuni yìí kò jẹ́ kí ìnira pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bí àìsí omi àti iná mànàmáná tó ń ṣe ségesège ni mí lára púpọ̀ jù.

Torí pé mi ò lọ́kọ, nígbà míì àwọn èèyàn máa ń bi mí bóyá ó tiẹ̀ máa ń ṣe mí bíi pé mo dá nìkan wà. Ká sòótọ́, ọwọ́ mi dí débi pé mi ò tiẹ̀ ráyè láti máa ronú pé mo dá wà àbí mi ò dá wà. Mo ní ọ̀pọ̀ nǹkan alárinrin tí mo ń fayé mi ṣe.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́