Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ December 1
“A wá ṣe ìbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ yín láti sọ òtítọ́ nípa èrò kan tí kò tọ́ tí àwọn kan ní nípa Bíbélì. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ọba ìwé ni Bíbélì, àmọ́ wọ́n rò pé ó ṣòro lóye. Kí lèrò yín nípa rẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹ wo ọ̀kan lára àwọn ìdí tó fi yẹ kó máa wù wá láti lóye Bíbélì. [Ka Róòmù 15:4.] Ìwé ìròyìn yìí sọ bá a ṣe mọ̀ pé wọ́n kọ Bíbélì lọ́nà tá a fi lè lóye rẹ̀. Ó sì tún sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe ká lè lóye rẹ̀.”
Ji! November–December
“A wá ṣe ìbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn aládùúgbò wa ká lè bá wọn sọ̀rọ̀ kan tó máa ṣe wọ́n láǹfààní. Èrò tó yàtọ̀ síra ni ọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe tí èèyàn wọn kan bá ń ṣàìsàn. Ẹ jọ̀wọ́, kí lèrò yín nípa rẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹ ṣeun gan-an fún bí ẹ ṣe sọ èrò yín nípa rẹ̀. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí ẹni tí kì í ṣàìsàn. Àmọ́, Bíbélì sọ ohun tá a lè ṣe tí èèyàn wa kan bá ń ṣàìsàn. [Ka Òwe 17:17.] Ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an tí ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí kan bá wà pẹ̀lú aláìsàn náà. Kódà, ó lè gba ẹ̀mí ẹni náà là. Bákan náà, ìwé ìròyìn yìí sọ onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà ṣèrànwọ́ fún èèyàn wa kan tó ń ṣàìsàn bóyá nígbà tó wà ní ilé tàbí ní ilé ìwòsàn.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 14 àti 15 hàn án.