MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àǹfààní Tá A Ní Láti Kọ́ Àwọn Ibi Tí A Ti Ń Ṣe Ìjọsìn Tòótọ́ Ká sì Máa Bójú Tó Wọn
Ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti ìnáwó kí wọ́n tó lè kọ́ Tẹ́ńpìlì ní Ísírẹ́lì. Síbẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ìtara kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìkọ́lé náà. (1Kr 29:2-9; 2Kr 6:7, 8) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń bójú tó tẹ́ńpìlì náà lẹ́yìn tí wọ́n kọ́ ọ tán fi hàn bóyá wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (2Ọb 22:3-6; 2Kr 28:24; 29:3) Lóde òní, àwa Kristẹni máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun wa láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ, a máa ń mú kí wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní, a sì máa ń ṣàbójútó wọn. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́ lọ́nà yìí, ohun tí à ń ṣe yìí sì jẹ́ ara iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa sí i.—Sm 127:1; Iṣi 7:15.
ARA OHUN TÁ A LÈ ṢE NI PÉ . . .
Ká máa tún àwọn ibi tá a bá lò tàbí jókòó sí nípàdé ṣe ká tó lọ sílé. Tí a kò bá ní lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí àwọn ìdí kan, ká rí i dájú pé àyíká ibi tá a jókòó sí wà ní mímọ́ tónítóní.
Ká máa kópa nínú iṣẹ́ ìmọ́tótó àti àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a máa ń ṣe déédéé. Àgbájọ ọwọ́ la fi ń sọ̀yà, tá a bá ń pawọ́ pọ̀ ṣe é, iṣẹ́ náà á dínkù, ayọ̀ wa á sì kún.—lv ojú ìwé 92 àti 93 ìpínrọ̀ 18.
Ká máa fowó ṣètìlẹyìn. Kódà, inú Jèhófà dùn sí ìtìlẹ́yìn tó tọkàn wá tó dà bí ‘ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an’ tá a bá fún un.—Mk 12:41-44.
Ká máa yọ̀ǹda ara wa tí ipò wa bá gbà bẹ́ẹ̀ láti máa kọ́ àwọn ilé tí ètò Ọlọ́run ń lò, ká sì máa ṣàtúnṣe wọn. Kì í ṣe dandan ká ti nírìírí lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé ká tó lè yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ yìí.