ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 33-36
Jèhófà Mọyì Ojúlówó Ìrònúpìwàdà
Bíi Ti Orí Ìwé
MÁNÁSÈ
Jèhófà jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Ásíríà mú un, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ mú un lọ sí Bábílónì
KÍ WỌ́N TÓ MÚ UN
Ó ṣe pẹpẹ fún àwọn ọlọ́run èké
Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rúbọ
Ó ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ sílẹ̀
Ó mú kí ìbẹ́mìílò tan dé gbogbo orílẹ̀-èdè náà
LẸ́YÌN TÍ WỌ́N TÚ U SÍLẸ̀
Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi
Ó gbàdúrà sí Jèhófà; ó rú ẹbọ
Ó mú àwọn pẹpẹ tó ṣe fún àwọn ọlọ́run èké kúrò
Ó sọ fún àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pé kí wọ́n máa sin Jèhófà
JÒSÁYÀ
JÁLẸ̀ ÌṢÀKÓSO RẸ̀
Ó wá Jèhófà
Ó mú ìjọsìn èké kúrò ní ilẹ̀ Júdà àti Jerúsálẹ́mù
Ó tún ilé Jèhófà ṣe; ó rí ìwé Òfin