ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb16 March ojú ìwé 7
  • Ìràpadà Mú Kí Àjíǹde Ṣeé Ṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìràpadà Mú Kí Àjíǹde Ṣeé Ṣe
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojúlówó Ìrètí Fáwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé A Ń kẹ́dùn, A Kò Wà Láìní Ìrètí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ohun Kan Ṣoṣo Tó Máa Fòpin sí Ikú!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú Ṣì Máa Jíǹde!
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
mwb16 March ojú ìwé 7

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìràpadà Mú Kí Àjíǹde Ṣeé Ṣe

Ìrántí Ikú Jésù máa ń fún wa láǹfààní láti ronú lórí àwọn ìbùkún tí ìràpadà máa jẹ́ ká rí gbà lọ́jọ́ iwájú, irú bí àjíǹde. Jèhófà ò fẹ́ ká máa kú rárá. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ikú èèyàn ẹni wà lára ohun tó máa ń dunni jù lọ. (1Kọ 15:26) Ó dun Jésù nígbà tó rí i tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ Lásárù. (Jo 11:33-35) Torí pé Jésù jọ Baba rẹ̀ délẹ̀délẹ̀, ó dá wa lójú pé ó máa dun Jèhófà tó bá ń rí i tá à ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn wa kan tó kú. (Jo 14:7) Ó ń wu Jèhófà gan-an láti jí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dìde nínú ikú, ó yẹ kó máa wu àwa náà bẹ́ẹ̀.—Job 14:14, 15.

Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ọlọ́run ètò, a lè retí pé àjíǹde máa wà létòlétò. (1Kọ 14:33, 40) Dípò ká máa lọ síbi ìsìnkú, ó ṣeé ṣe kí ètò wà láti máa kí àwọn tó ti kú káàbọ̀. Ǹjẹ́ o máa ń ronú nípa àjíǹde ní pàtàkì jù lọ nígbà tó o bá ń ṣọ̀fọ̀? (2Kọ 4:17, 18) Ṣé o máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe pèsè ìràpadà tó sì jẹ́ ká rí i nínú Ìwé Mímọ́ pé àwọn òkú yóò jíǹde?—Kol 3:15.

  • Àwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ wo lo máa kọ́kọ́ fẹ́ rí nígbà àjíǹde?

  • Àwọn wo lára àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn lo máa fẹ́ rí kó o sì bá sọ̀rọ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́