ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 120-134
“Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ni Ìrànlọ́wọ́ Mi Ti Wá”
Orin Ìgòkè làwọn èèyàn máa ń pe Sáàmù 120 sí 134. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé orin yìí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fìdùnnú kọ nígbà tí wọ́n bá ń gba orí àwọn òkè ńlá Júdà lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún.
Jèhófà ń dáàbò bò wá bí . . .
olùṣọ́ àgùntàn tó wà lójúfò
òjìji tó ń dáàbò boni lọ́wọ́ oòrùn
jagunjagun tó jẹ́ arógunmásàá