September 19 Sí 25
SÁÀMÙ 135-141
Orin 59 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ọlọ́run Ṣẹ̀dá Wa Tìyanu-Tìyanu”: (10 min.)
Sm 139:14—Tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà, èyí á jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì àwọn ohun tó ṣe (w07 6/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
Sm 139:15, 16—Àwọn sẹ́ẹ̀lì àtàwọn èròjà tó ń pinnu bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe máa rí jẹ́ ká mọ bí ọgbọ́n àti agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó (w07 6/15 ojú ìwé 22 àti 23 ìpínrọ̀ 7 sí 11)
Sm 139:17, 18—Ọ̀nà tí Jèhófà gbà ṣẹ̀dá àwa èèyàn ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an; oríṣiríṣi èdè là ń sọ, bá a sì ṣe ń ronú yàtọ̀ síra (w07 6/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 12 àti 13; w06 9/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 8)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Sm 136:15—Òye wo ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká ní nípa ìwé Ẹ́kísódù? (it-1 ojú ìwé 783 ìpínrọ̀ 5)
Sm 141:5—Kí ni Dáfídì Ọba mọ̀? (w15 4/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 139:1-24
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) wp16.5 ojú ìwé 16
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) wp16.5 ojú ìwé 16—Pe ẹni náà wá sípàdé.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg ẹ̀kọ́ 8 ìpínrọ̀ 8—Ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè rí bó ṣe lè fi ohun tó kọ́ sílò.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Àwọn Nǹkan Tó Yẹ Kó O Yẹra fún Tó O Bá Ń Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì”: (15 min.) Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò àpilẹ̀kọ náà, jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò alápá-méjì nípa ọ̀nà tí kò tọ́ àti ọ̀nà tó tọ́ láti kọ́ni, èyí tó dá lé ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ojú ìwé 29, ìpínrọ̀ 7, kẹ́ ẹ sì jíròrò ohun tẹ́ ẹ wò nínú fídíò náà. Kí àwọn akéde náà máa fojú bá a lọ nínú ìwé wọn. Sọ fún àwọn ará pé kí wọ́n máa yẹra fún àwọn nǹkan yìí nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, èyí ò ní jẹ́ kí wọ́n lò tó àkókò tá a yàn fún iṣẹ́ náà.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí àti orí 1 ìpínrọ̀ 1 sí 10
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 30 àti Àdúrà