September 12 Sí 18
SÁÀMÙ 120-134
Orin 33 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ni Ìrànlọ́wọ́ Mi Ti Wá”: (10 min.)
Sm 121:1, 2—Torí pé Jèhófà ló dá ohun gbogbo, èyí mú ká gbẹ́kẹ̀ lé e (w04 12/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 3)
Sm 121:3, 4—Jèhófà kì í fọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣeré rárá (w04 12/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 4)
Sm 121:5-8—Jèhófà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ (w04 12/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 5 sí 7)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Sm 123:2—Ẹ̀kọ́ wo ni àkàwé nípa “ojú àwọn ìránṣẹ́” kọ́ wa? (w06 9/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 4)
Sm 133:1-3—Kí ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tí a lè rí kọ́ nínú sáàmù yìí? (w06 9/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 127:1–129:8
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Àwòrán iwájú ìwé ìròyìn wp16.5 tó wà lójú ìwé 2—Wàásù fún ẹnì kan tó ń bínú.
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kókó iwájú ìwé ìròyìn wp16.5 —Pe ẹni náà wá sípàdé.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg ẹ̀kọ́ 8 ìpínrọ̀ 6—Ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè rí bó ṣe lè fi ohun tó kọ́ sílò.
Ọ̀pọ̀ Nǹkan Ni Jèhófà Ti Ṣe fún Mi: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò yìí. Ó wà lórí ìkànnì jw.org/yo.Ọ̀pọ̀ Nǹkan Ni Jèhófà Ti Ṣe fún Mi. (Lọ sí NÍPA WA > OHUN TÁ À Ń ṢE.) Ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni Jèhófà ṣe ran Crystal lọ́wọ́, kí sì lèyí mú kó ṣe? Kí ló máa ń ṣe nígbà tí èrò òdì bá ń kó ìbànújẹ́ bá a? Kí ni ìrírí Crystal kọ́ ẹ?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia Ìparí, ìpínrọ̀ 1 sí 13
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 119 àti Àdúrà