ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ORIN SÓLÓMỌ́NÌ 1-8
Ọmọbìnrin Ṣúlámáítì Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere Tá A Lè Tẹ̀ Lé
Kí ló mú kí ọ̀dọ́bìnrin yìí jẹ́ àpẹẹrẹ tó tayọ fún àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà?
Ó hùwà ọgbọ́n láti dúró dìgbà tó máa fi rí ẹni tí wọ́n á jọ nífẹ̀ẹ́ ara wọn tọkàntọkàn
Kò jẹ́ kí ohun táwọn míì ń sọ mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti kọ ẹnu ìfẹ́ sí i
Ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, ó sì níwà mímọ́
Kò jẹ́ kí góòlù tàbí ọ̀rọ̀ dídùn kó sí òun lórí
Bi ara rẹ pé:
‘Èwo lára àwọn ànímọ́ Ṣúlámáítì ni mo máa fara wé?’