MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Lo Ìwé “Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run” Láti Dénú Ọkàn Àwọn Èèyàn
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ mọ àwọn ìlànà Jèhófà kí wọ́n sì máa fi wọ́n sílò, kí wọ́n báa lè ṣe ìjọsìn tí Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà. (Ais 2:3, 4) Ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run,” tó jẹ́ ìwé kejì tá a máa ń fi kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lẹ́kọ̀ọ́ máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè fí àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò. (Heb 5:14) Torí náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti dénú ọkàn wọn nígbà tá a bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n báa lè rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn.—Ro 6:17.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Múra sílẹ̀ dáadáa, kó o sì ronú nípa ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ nílò. Béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kó o mọ èrò rẹ̀ àti bí ohun tẹ́ ẹ kọ́ ṣe rí lára rẹ̀.—Owe 20:5; be ojú ìwé 259
Lo àwọn àpótí tó wà nínú ìwé náà kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lè mọ pé ó ṣe pàtàkì láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì
Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ọ̀ràn tó dá lórí ẹ̀rí ọkàn, àmọ́ má ṣe pinnu fún un.—Ga 6:5
Lo ọgbọ́n kó o lè mọ̀ bóyá akẹ́kọ̀ọ́ rẹ nílò ìrànlọ́wọ́ kó lè máa fi ìlànà Bíbélì pàtó kan sílò. Kó o sì fún un ní ìṣírí kó lè ṣe àtúnṣe nítorí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà.—Owe 27:11; Jo 14:31