ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 February ojú ìwé 2
  • February 6-12

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • February 6-12
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 February ojú ìwé 2

February 6-12

AÍSÁYÀ 47-51

  • Orin 120 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • “Jèhófà Máa Bù Kún Wa Tá A Bá Ṣègbọràn Sí I”: (10 min.)

    • Ais 48:17​—Ìjọsìn tòótọ́ dá lórí ṣíṣe ìgbọràn sí àwọn ìtọ́ni tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run (ip-2 131 ¶18)

    • Ais 48:18​—Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé wa (ip-2 131 ¶19)

    • Ais 48:19​—Ṣíṣe ìgbọràn máa jẹ́ ká rí ìbùkún tí kò lópin (ip-2 132 ¶20-21)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Ais 49:6​—Báwo ni Mèsáyà ṣe jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìkan ló ti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? (w07 1/15 9 ¶9)

    • Ais 50:1​—Kí nìdí tí Jèhófà fi béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ibo wá ni ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá yín wà?” (it-1 643 ¶4-5)

    • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

    • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 51:12-23

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò tó dá lórí “Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò.” Jẹ́ kí àwọn ará wo àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Lóṣù February, àwọn ará tún lè lo ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! tàbí ìwé The Origin of Life​—Five Questions Worth Asking tí wọ́n bá pàdé ọmọ iléwèé tí wọ́n ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n, àmọ́ tó ń fẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà. (Wo àpótí náà “The Origin of Life​—Five Questions Worth Asking.”)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 89

  • Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (7 min.) Ẹ tún lè jíròrò ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú Ìwé Ọdọọdún. (yb16 144-145)

  • Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà​—Máa Ṣègbọràn sí Jèhófà: (8 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ wo fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà​—Máa Ṣègbọràn sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà? (Owe 27:11) Àwọn ọ̀nà wo làwọn ọmọdé ti gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí Jèhófà? Àwọn ọ̀nà wo làwọn àgbàlagbà ti gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí Jèhófà?

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 8 ¶1-7 àti àpótí“Ìhìn Rere Lédè Tó Ju Ẹgbẹ̀ta Lé Àádọ́rin”

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 98 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́