ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp20 No. 3 ojú ìwé 4-5
  • Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa, Ó Sì Ń Bójú Tó Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa, Ó Sì Ń Bójú Tó Wa
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • 1. ẸLẸ́DÀÁ WA Ń MÚ KÍ OÒRÙN RÀN
  • 2. ẸLẸ́DÀÁ WA Ń MÚ KÍ ÒJÒ RỌ̀
  • 3. ẸLẸ́DÀÁ WA Ń PÈSÈ OÚNJẸ ÀTI AṢỌ
  • Ọ̀pá Tín-ín-rín Kanlẹ̀ ó Kànrun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Máa Wá Ìjọba Ọlọ́run, Má Ṣe Wá Àwọn Nǹkan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Mọ Irú Ẹni Tí Ẹlẹ́dàá Rẹ Jẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ẹni Tí Ó Dá Ohun Gbogbo
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
wp20 No. 3 ojú ìwé 4-5
Oòrùn ń ràn sórí àwọn òkè.

Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa, Ó sì Ń Bójú Tó Wa

1. ẸLẸ́DÀÁ WA Ń MÚ KÍ OÒRÙN RÀN

Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí tí kò bá sí oòrùn? Oòrùn ló ń fún àwọn igi lágbára tí wọ́n fi ń mú ewé, òdòdó, èso, àwọn ẹ̀pà àti irúgbìn jáde. Òun ló tún máa ń jẹ́ káwọn igi fi gbòǹgbò wọn fa omi láti ilẹ̀ lọ sára àwọn ewé tí omi náà á sì lọ sínú afẹ́fẹ́.

Àwòrán oko kan tí wọ́n ti ń ṣọ̀gbìn ewé tí ì, tó wà níbi òkè.

2. ẸLẸ́DÀÁ WA Ń MÚ KÍ ÒJÒ RỌ̀

Ẹ̀bùn pàtàkì látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òjò jẹ́, ó sì ń mú kí ilẹ̀ mú oríṣiríṣi oúnjẹ jáde. Ọlọ́run ń fún wa ní òjò látọ̀run àti àkókò èso, ìyẹn ń jẹ́ ká gbádùn oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn, ó sì ń mú kí ọkàn wa yọ̀.

Ẹyẹ kan bà lé ẹ̀ka igi, ó fẹ́ jẹ èso kan tó ń já bọ̀ látorí igi.

3. ẸLẸ́DÀÁ WA Ń PÈSÈ OÚNJẸ ÀTI AṢỌ

Ọ̀pọ̀ àwọn bàbá máa ń wá bí wọ́n á ṣe pèsè oúnjẹ àti aṣọ fún ìdílé wọn. Wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ó ní: “Kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run; wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí jù wọ́n lọ ni?”​—Mátíù 6:25, 26.

“Kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn òdòdó lílì inú pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà . . . ; àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí. Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko pápá láṣọ . . . , ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ?”​—Mátíù 6:28-30.

Nítorí pé Ọlọ́run pèsè oúnjẹ àti aṣọ fún wa, ó dájú pé ó máa jẹ́ ká rí àwọn ohun mìíràn tá a nílò. Tá a bá ń wá bá a ṣe máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run á fi èrè sí iṣẹ́ wa kí àwọn ohun ọ̀gbìn wa lè méso jáde tàbí kó pèsè iṣẹ́ tó máa jẹ́ ká lè rówó ra àwọn ohun tá a nílò.​—Mátíù 6:​32, 33.

Ó dájú pé a máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an tá a bá ronú nípa oòrùn, òjò, àwọn ẹyẹ àti òdòdó. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa sọ bí Ọlọ́run ṣe ń bá aráyé sọ̀rọ̀.

Ẹlẹ́dàá wa ń “mú kí oòrùn rẹ̀ ràn . . . ó sì ń mú kí òjò rọ̀.”​—MÁTÍÙ 5:45

Ẹlẹ́dàá wa nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ń bójú tó wa. Ọlọ́run dà bíi bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ ìdílé rẹ̀ tó sì ń bójú tó wọn. Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run jẹ́ Olùpèsè tó lawọ́ gan-an, ó “mọ àwọn ohun tí ẹ nílò, kódà kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”​—Mátíù 6:8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́