Bí oníṣòwò kan ṣe lè lo akọ̀wé rẹ̀ láti kọ lẹ́tà, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run ṣe lo àwọn èèyàn olóòótọ́ kan láti kọ Ìwé Mímọ́
Ẹlẹ́dàá Wa Jẹ́ Ká Mọ Àwọn Ohun Rere Tó Fẹ́ Ṣe
Láyé àtijọ́, Ọlọ́run máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì àtàwọn wòlíì. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ní kí wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ohun rere tó fẹ́ ṣe sílẹ̀. Àwọn ohun rere tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe yìí kan ọjọ́ ọ̀la wa. Ibo la ti lè kà nípa àwọn ohun rere tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe?
Àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ wà nínú Ìwé Mímọ́. (2 Tímótì 3:16) Báwo ni Ọlọ́run ṣe lo àwọn wòlíì láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà? (2 Pétérù 1:21) Ọlọ́run fi èrò rẹ̀ sọ́kàn àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́, wọ́n wá kọ èrò náà sílẹ̀. Àwa èèyàn náà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí oníṣòwò bá lo akọ̀wé rẹ̀ láti kọ lẹ́tà kan, ọ̀dọ̀ oníṣòwò náà la máa gbà pé lẹ́tà náà ti wá. Lọ́nà kan náà, bí Ọlọ́run tiẹ̀ lo àwọn èèyàn láti kọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni àwọn Ìwé Mímọ́ náà ti wá.
Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN WÀ FÚN GBOGBO ÈÈYÀN
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an, ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn máa kà á, kí wọ́n sì lóye rẹ̀. Lónìí, “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èdè” ló ń gbọ́ “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” Ọlọ́run ní fàlàlà. (Ìfihàn 14:6, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Ìwé Mímọ́ ti wà ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000), bóyá lódindi tàbí lápá kan. Kò sí ìwé kankan láyé tí wọ́n tẹ̀ jáde lédè tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run ló mú kí èyí ṣeé ṣe.