MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Kí Nìdí Tó O Fi Mọyì Ìjọsìn Mímọ́?
Ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn níṣìírí gan-an, torí pé ó jẹ́ kí wọ́n nírètí pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò. Ní àkókò òpin tá a wà yìí, ìjọsìn mímọ́ ti ‘fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá,’ àwa náà sì wà lára àwọn tó ń wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀. (Ais 2:2) Ǹjẹ́ o máa ń ronú nígbà gbogbo nípa àǹfààní tó o ní láti mọ Jèhófà, tó o sì ń sìn ín?
ÈRÈ TÓ WÀ NÍNÚ ÌJỌSÌN MÍMỌ́:
À ń jẹ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí, tó ń jẹ́ ká rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ, à ń kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò nípa bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa, a sì ní ìrètí tó dájú.—Ais 48:17, 18; 65:13; Ro 15:4
A wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn.—Sm 133:1; Jo 13:35
Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, a sì ń fi ayọ̀ ṣiṣẹ́ ìwàásù náà.—Iṣe 20:35; 1Kọ 3:9
“Àlàáfíà Ọlọ́run” máa ń fún wa lókun nígbà ìṣòro.—Flp 4:6, 7
A ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.—2Ti 1:3
A ní “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.”—Sm 25:14
Àwọn ọ̀nà wo ni mo lè gbà fi hàn pé mo mọyì ìjọsìn mímọ́?