ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 46-48
Ohun Tí Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Máa Gbádùn Tí Wọ́n Bá Kúrò Nígbèkùn
Ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn ní ìṣírí, ó sì tún fi dá wọn lójú pé wọ́n ṣì máa kúrò nígbèkùn gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ ṣe sọ. Ìjọsìn mímọ́ ni gbogbo àwọn tí Jèhófà ti bù kún á máa ṣe.
Ìran yẹn fi hàn pé nǹkan máa wà létòlétò, àwọn èèyàn á fọwọ́ sowọ́ pọ̀, Jèhófà sì máa dáàbò bò wọ́n
Ilẹ̀ ọlọ́ràá tó ń mú èso jáde
Ìdílé kọ̀ọ̀kan ló máa gba ogún
Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í pín ilẹ̀ fún àwọn èèyàn, wọ́n á kọ́kọ́ ya apá ibi tó dára gan-an sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọrẹ” fún Jèhófà
Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé ìjọsìn Jèhófà ni mo kà sí pàtàkì jù nígbèésí ayé mi? (w06 4/15 27-28 ¶13-14)