ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb18 February ojú ìwé 7
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Máa Lo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Máa Lo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Múná Dóko
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Máa Ṣe Ojúṣe Rẹ Gẹ́gẹ́ Bí Ajíhìnrere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Lo Ìbéèrè Bó Ṣe Yẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Máa Lo Ìjìnlẹ̀ Òye Àti Ìyíniléròpadà Nígbà Tóo Bá Ń Kọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
mwb18 February ojú ìwé 7

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Máa Lo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: “Ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn,” ìbéèrè sì dà bí korobá tí èèyàn lè fi fa omi náà jáde. (Owe 20:5) Ìbéèrè ló máa ń jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ wa lè dá sí ohun tá à ń sọ. Tá a bá farabalẹ̀ lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́, èyí á jẹ́ ká mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ wa yé ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ tàbí kò yé e. Jésù lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́. Báwo la ṣe lè fara wé e?

Jésù ń bi ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìbéèrè

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Lo ìbéèrè tó máa jẹ́ káwọn èèyàn sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Jésù lo oríṣiríṣi ìbéèrè tó gbéṣẹ́ kó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Mt 16:​13-16; be 238 ¶3-5) Irú àwọn ìbéèrè wo lo lè béèrè táá jẹ́ kó o mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn?

  • Lo ìbéèrè tó ń tọ́ni sọ́nà. Nígbà tí Jésù fẹ́ tún èrò Pétérù ṣe, ó béèrè ìbéèrè, ó sì tún sọ àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìdáhùn, kó lè tọ́ Pétérù sọ́nà láti dórí èrò tó tọ́. (Mt 17:​24-26) Àwọn ìbéèrè wo lo lè béèrè láti tọ́ ẹnì kan sọ́nà kó lè dórí èrò tó tọ́?

  • Gbóríyìn fún olùgbọ́ rẹ. Lẹ́yìn tí akọ̀wé kan “dáhùn pẹ̀lú làákàyè,” Jésù gbóríyìn fún un. (Mk 12:34) Báwo lo ṣe lè gbóríyìn fún ẹnì kan tó dáhùn ìbéèrè kan?

Bọ̀wọ̀ fúnni. A ò ní ọlá àṣẹ tí Jésù ní. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn èèyàn, pàápàá àwọn àgbàlagbà, àwọn tí a kò mọ̀ rí, àti àwọn tó wà ní ipò àṣẹ.​—1Pe 2:17.

WO APÁ ÀKỌ́KỌ́ NÍNÚ FÍDÍÒ NÁÀ ṢE IṢẸ́ TÍ JÉSÙ ṢE​—MÁA KỌ́NI, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí nìdí tí kò fi yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yìí tá a bá ń kọ́ni, kódà tí ohun tá à ń sọ bá tiẹ̀ jóòótọ́?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe kọjá pé ká kàn ṣàlàyé ọ̀rọ̀ nìkan?

WO APÁ KEJÌ NÍNÚ FÍDÍÒ NÁÀ, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni arákùnrin náà ṣe lo ìbéèrè lọ́nà tó gbéṣẹ́?

  • Àwọn apá míì wo nínú ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ la lè fara wé?

Ìkẹ́kọ̀ọ́ sú ọkùnrin kan torí pé olùkọ́ rẹ̀ kò kọ́ ọ lọ́nà tó gbéṣẹ́; ẹ̀kọ́ òtítọ́ yé ọkùnrin kan dáadáa torí pé olùkọ́ rẹ̀ kọ́ ọ lọ́nà tó gbéṣẹ́

Ipa wo ni ẹ̀kọ́ wa ń ní lórí àwọn míì? (Lk 24:32)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́