MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Tẹ̀ Lé Ìṣísẹ̀ Kristi Pẹ́kípẹ́kí
Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé, ní pàtàkì tá a bá ń kojú àdánwò tàbí inúnibíni. (1Pe 2:21-23) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n bú Jésù, síbẹ̀ kò gbẹ̀san nígbà tí wọ́n ṣàìdáa sí i. (Mk 15:29-32) Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á? Ó pinnu láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Jo 6:38) Ó tún pọkàn pọ̀ sórí “ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀.”—Heb 12:2.
Tí wọ́n bá hùwà tí kò dáa sí wa torí ohun tá a gbà gbọ́, kí ló yẹ ká ṣe? Kristẹni tòótọ́ kì í “fi ibi san ibi.” (Ro 12:14, 17) Tá a bá fara wé bí Kristi ṣe fara da ìnira, èyí á jẹ́ ká láyọ̀ torí pé inú Ọlọ́run dùn sí wa.—Mt 5:10-12; 1Pe 4:12-14.
WO FÍDÍÒ NÁÀ ORÚKỌ JÈHÓFÀ LÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo ni Arábìnrin Pötzingera ṣe fi ọgbọ́n lo àkókò rẹ̀ nígbà tí wọ́n fi í sínú yàrá àdágbé lọ́gbà ẹ̀wọ̀n?
Ìyà wo ni Arákùnrin àti Arábìnrin Pötzinger fara dà nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tí wọ́n wà?
Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara dà á?
Tó o bá ń jìyà, máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi pẹ́kípẹ́kí
a Wọ́n tún lè pe orúkọ yìí ní Poetzinger.