MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣe Ohun Tá Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Rẹ Lágbára Sí I
Jèhófà ò fọwọ́ kékeré mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó. Ó sọ pé àwọn tọkọtaya gbọ́dọ̀ ṣe ara wọn lọ́kan. (Mt 19:5, 6) Láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Àmọ́ ìyẹn ò sọ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò níṣòro nínú ìgbéyàwó wọn, torí kò sí ìgbéyàwó tó dáa tán. Tí ìṣòro bá dé, àwọn kan gbà pé ìpínyà tàbí ìkọ̀sílẹ̀ ló máa yanjú ìṣòro náà, àmọ́ àwa Kristẹni ò gbọ́dọ̀ gba irú èrò bẹ́ẹ̀ láyè. Kí ni tọkọtaya lè ṣe láti mú kí ìgbéyàwó wọn lágbára sí i?
Ohun márùn-ún yìí ṣe pàtàkì.
Má ṣe máa tage pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ, bákàn náà yẹra fún eré ìnàjú tó lè gbé ìṣekúṣe sí ẹ lọ́kàn, torí wọ́n lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó rẹ.—Mt 5:28; 2Pe 2:14.
Jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ máa lágbára sí i, kó o sì pinnu pé wàá túbọ̀ máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.—Sm 97:10.
Máa sapá kí ìwà ẹ lè dáa sí i, kó o sì máa ṣe àwọn nǹkan kéékèèké láti ran ẹnì kejì rẹ lọ́wọ́.—Kol 3:8-10, 12-14.
Ẹ máa bá ara yín sọ̀rọ̀ déédéé, kẹ́ ẹ sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.—Kol 4:6.
Máa fìfẹ́ hàn sí ẹnì kejì rẹ déédéé, má sì máa ro tara ẹ nìkan tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀.—1Kọ 7:3, 4; 10:24.
Bí àwa Kristẹni ṣe ń fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó, ṣe là ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀.
WO FÍDÍÒ NÁÀ A GBỌ́DỌ̀ ‘FI ÌFARADÀ SÁRÉ’—MÁA TẸ̀ LÉ ÒFIN ERÉ SÍSÁ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbéyàwó lè dùn níbẹ̀rẹ̀, àwọn ìṣòro wo ló ṣì lè yọjú?
Báwo ni ìlànà Bíbélì ṣe lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ tó bá ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn mọ́?
Máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò kí ìgbéyàwó rẹ lè láyọ̀
Àwọn ìlànà wo ni Jèhófà fẹ́ kí tọkọtaya máa tẹ̀ lé?
Kí ìgbéyàwó tó lè láyọ̀, kí ni tọkọtaya gbọ́dọ̀ máa ṣe?