MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jẹ́ Kó Dá Ẹ Lójú Pé Ìfẹ́ Tí Jèhófà Ní sí Ẹ Kò Ní Yẹ̀ Láé
Kò sí àní-àní pé o ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. (Ais 43:4) Ó fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀, ó sì mú kó o wà nínú ètò rẹ̀. Bó o ṣe ya ara ẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi ti mú kó o di ti Jèhófà. Torí náà, ó máa tójú ẹ torí pé àyànfẹ́ rẹ̀ lo jẹ́. Kódà, kò ní fi ẹ́ sílẹ̀ lásìkò tó o bá kojú ìṣòro. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó máa lo ètò rẹ̀ láti fìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹ.—Sm 25:10.
Tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tí ètò Jèhófà ń ṣe tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì bí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa lónìí.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌRÒYÌN IṢẸ́ ÌGBÌMỌ̀ OLÙṢEKÒKÁÁRÍ 2019, LẸ́YÌN NÁÀ Ẹ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Ètò wo ni Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí sọ pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ̀ọ̀kan ṣe láti pèsè ìrànwọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?
Báwo ni ètò Jèhófà ṣe pèsè ìrànwọ́, tí wọ́n sì fún àwọn ará nítọni nígbà tí àjálù ṣẹlẹ̀ ní Indonẹ́ṣíà àti Nàìjíríà?
Kí ló wú ẹ lórí nínú ohun tí ètò Ọlọ́run ṣe lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Corona?