ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
“Mo Ti Ń Gbádùn Iṣẹ́ Ìwàásù Báyìí!”
ÌLÚ Balclutha lórílẹ̀-èdè New Zealand ni mo dàgbà sí. Nígbà tí mo wà ní kékeré, mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, mo sì ń gbádùn ẹ̀kọ́ òtítọ́. Inú mi máa ń dùn tá a bá ń lọ sípàdé, ọkàn mi sì máa ń balẹ̀ níbẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú máa ń tì mí, mo máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kódà, ẹ̀rù kì í bà mí láti wàásù fáwọn ọmọléèwé mi àtàwọn míì. Inú mi dùn gan-an pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Torí náà, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlá (11), mo ya ara mi sí mímọ́, mo sì ṣèrìbọmi.
MI Ò GBÁDÙN IṢẸ́ ÌSÌN MI MỌ́
Nígbà tí mo pé nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13), àjọṣe èmi pẹ̀lú Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn. Ó máa ń ṣe mí bíi pé àwọn ọmọ ilé ìwé mi ń jayé orí wọn torí wọ́n lómìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n, àmọ́ èmi ń fìyà jẹ ara mi. Lójú mi, ó dà bíi pé òfin táwọn òbí mi fún mi àtàwọn ìlànà Bíbélì ti nira jù àti pé ìjọsìn Jèhófà gan-an ti le jù. Mo mọ̀ pé Jèhófà wà lóòótọ́, àmọ́ mi ò fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn ẹ̀ mọ́.
Kí wọ́n má bàa rí mi bí aláìṣiṣẹ́mọ́, mo máa ń jáde òde ẹ̀rí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ọjọ́ tí mo bá jàjà lọ sóde ẹ̀rí, mi ò kì í múra sílẹ̀, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó ṣòro fún mi láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Torí náà, mi ò lẹ́ni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn wá mú kí iṣẹ́ ìwàásù sú mi, mi ò sì láyọ̀. Mo máa ń bi ara mi pé, ‘Báwo lẹnì kan á ṣe máa ṣe iṣẹ́ yìí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ táá sì ṣe é fún ọ̀pọ̀ ọdún táyé ò sì ní sú u?’
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17), ó wù mí gan-an láti lómìnira. Torí náà, mo di ẹrù mi, mo sì kó lọ sórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Inú àwọn òbí mi ò dùn pé mi ò ní gbé pẹ̀lú àwọn mọ́, ọkàn wọn ò sì balẹ̀. Ṣùgbọ́n, wọ́n gbà pé mi ò ní fi Jèhófà sílẹ̀.
Nígbà tí mo dé Ọsirélíà, ìjọsìn Jèhófà ò tiẹ̀ wá jọ mí lójú mọ́. Kódà, ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni mo máa ń lọ sípàdé. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ kan nínú ìjọ táwọn náà fẹ́ jayé orí wọn. A lè lọ sípàdé lónìí, ká sì lọ mutí ká tún jayé orí wa nílé ijó lọ́jọ́ kejì. Tí n bá ń ronú nípa bí ìgbésí ayé mi ṣe rí nígbà yẹn, mo rí i pé ṣekuṣẹyẹ ni mí. Ẹsẹ̀ mi kan wà nínú ayé, ìkejì sì wà nínú òtítọ́. Síbẹ̀ mi ò láyọ̀.
MO KẸ́KỌ̀Ọ́ PÀTÀKÌ KAN LỌ́NÀ TÍ MI Ò LÉRÒ
Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méjì, mo lo àkókò díẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin kan. Láìmọ̀, arábìnrin yìí mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi. Àwa arábìnrin márùn-ún la jọ ń gbélé. A wá sọ pé kí alábòójútó àyíká àti ìyàwó ẹ̀ tó ń jẹ́ Tamara wá lo ọ̀sẹ̀ kan nílé wa. Lásìkò tí ọkọ ẹ̀ bá ń bójú tó iṣẹ́ ìjọ, Tamara máa ń wà pẹ̀lú wa, àá jọ máa ṣeré, àá sì jọ máa rẹ́rìn-ín, ìyẹn mú kí n fẹ́ràn ẹ̀ gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì rọrùn bá sọ̀rọ̀. Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé ẹni tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó báyìí lè dùn-ún bá ṣeré.
Tamara nítara gan-an. Bó ṣe nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tó sì fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù wú mi lórí. Inú ẹ̀ máa ń dùn bó ṣe ń fi gbogbo ọkàn ṣiṣẹ́ Jèhófà, àmọ́ èmi ò láyọ̀ torí pé ìwọ̀nba ni mò ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà. Bó ṣe ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà mú kí n ronú nípa ìgbésí ayé mi. Àpẹẹrẹ ẹ̀ jẹ́ kí n ronú lórí òtítọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ni pé, Jèhófà fẹ́ kí gbogbo wa máa “fi ayọ̀” sin òun.—Sm. 100:2.
OHUN TÍ MO ṢE TÓ JẸ́ KÍ N PA DÀ NÍFẸ̀Ẹ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Ó wù mí kí n ní irú ayọ̀ tí Tamara ní, àmọ́ kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, mo gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà ńlá kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn rárá, ó sì gba ọ̀pọ̀ àkókò, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe díẹ̀díẹ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ fún òde ẹ̀rí, mo sì máa ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ látìgbàdégbà. Ìyẹn jẹ́ kọ́kàn mi túbọ̀ balẹ̀ lóde ẹ̀rí kí n sì máa fìgboyà sọ̀rọ̀. Bí mo ṣe túbọ̀ ń lo Bíbélì lóde ẹ̀rí, bẹ́ẹ̀ ni mo túbọ̀ ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù. Kò pẹ́ sígbà yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣooṣù.
Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ń ṣe dáadáa nínú òtítọ́, tí wọ́n sì ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn Jèhófà láìka ọjọ́ orí wọn sí. Àpẹẹrẹ tó dáa tí wọ́n fi lélẹ̀ jẹ́ kí n ronú nípa ohun tí mo fẹ́ fayé mi ṣe, kí n sì máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an, nígbà tó sì yá, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Inú mi dùn, ọkàn mi sì balẹ̀ nínú ìjọ. Kí n sòótọ́, ìsinsìnyí gan-an lara tù mí jù.
MO PÀDÉ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ TÁ A JỌ MÁA BÁRA WA KALẸ́
Ọdún kan lẹ́yìn náà, mo pàdé Alex. Onínúure ni, ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni nígbà yẹn, ó sì ti wà lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún mẹ́fà. Bákan náà, ìgbà kan wà tó sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ fúngbà díẹ̀ lórílẹ̀-èdè Màláwì. Àpẹẹrẹ àtàtà làwọn míṣọ́nnárì tó wà níbẹ̀ jẹ́ fún Alex, wọ́n sì gbà á níyànjú pé kó máa fi ire Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀.
Èmi àti Alex ṣègbéyàwó lọ́dún 2003, a sì jọ ń bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún wa lọ látìgbà yẹn. Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn yìí, Jèhófà sì ti bù kún wa gan-an.
JÈHÓFÀ BÙ KÚN WA LÁWỌN Ọ̀NÀ MÍÌ
A wà lóde ẹ̀rí nílùú Gleno, lórílẹ̀-èdè Timor-Leste
Lọ́dún 2009, ètò Ọlọ́run ní ká lọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Timor-Leste, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn erékùṣù tó wà ní Indonéṣíà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú wa dùn, ó yà wá lẹ́nu, bẹ́ẹ̀ lẹ̀rù tún bà wá. Oṣù márùn-ún lẹ́yìn ìyẹn, a gúnlẹ̀ sí Dili tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà.
Àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí gba pé ká ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nígbèésí ayé wa. Bí àpẹẹrẹ, àṣà àti èdè wọn yàtọ̀. Bákan náà, oúnjẹ wọn àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan níbẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí tiwa. Lóde ẹ̀rí, a sábà máa ń pàdé àwọn tí àtijẹ àtimu ṣòro fún, àwọn tí ò kàwé àtàwọn tí wọ́n ti fìyà jẹ. A tún rí ọ̀pọ̀ àwọn tójú wọn ti rí màbo, tọ́kàn wọn ò sì balẹ̀ torí ogun àti ìwà ìkà.a
A gbádùn iṣẹ́ ìsìn wa gan-an. Ẹ jẹ́ kí n sọ ìrírí kan fún yín. Lọ́jọ́ kan, mo pàdé ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13) kan tó ń jẹ́ Maria.b Inú ẹ̀ ò dùn rárá, ìdí ni pé ọdún mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn ni màmá ẹ̀ kú, ẹ̀ẹ̀kan lọ́gbọ̀n ló sì máa ń rí bàbá ẹ̀. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀, ìgbésí ayé Maria ò lójú. Mo rántí ìgbà kan tó ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún mi, ṣe ló bú sẹ́kún, àmọ́ ohun tó ń sọ ò yé mi torí mi ò tíì gbọ́ èdè ẹ̀ dáadáa. Mo bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n mọ ohun tí mo lè sọ táá fún un níṣìírí. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan fún un. Láàárín ọdún mélòó kan, mo rí bí òtítọ́ ṣe tún ayé Maria ṣe. Kódà, ìrísí ẹ̀ yí pa dà, ó sì ń láyọ̀. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi, ó sì ti láwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí, inú Maria ń dùn pé òun wà láàárín àwọn èèyàn Jèhófà, ìgbésí ayé ẹ̀ sì ti lójú.
Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ìwàásù gan-an ní Timor-Leste. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ju ọdún mẹ́wàá tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn akéde tó wà níbẹ̀ ṣèrìbọmi. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Àwọn míì sì ń ṣiṣẹ́ sìn ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè. Inú mi máa ń dùn tí n bá ń rí bí wọ́n ṣe ń fìtara kọrin nípàdé, tí mò ń rí bí wọ́n ṣe ń láyọ̀, tí mo sì ń rí bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
Èmi àti Alex ń lọ pín ìwé ìkésíni fún Ìrántí Ikú Kristi ní ìpínlẹ̀ tí a kì í ṣe déédéé
MO GBÁDÙN ÌGBÉSÍ AYÉ MI GAN-AN
Ohun kan ni pé bí nǹkan ṣe rí ní Timor-Leste yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe rí ní Ọsirélíà. Síbẹ̀, mo gbádùn ìgbésí ayé mi gan-an. Nígbà míì, a máa ń wọ mọ́tò tí èrò máa kúnnú ẹ̀ bámú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á kó àwọn ẹrù míì bí ẹja gbígbẹ àti ẹ̀fọ́ tí wọ́n rà lọ́jà sínú ẹ̀. Àwọn ìgbà míì sì wà tá a máa lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé kékeré kan tó ń móoru, tí ilẹ̀ á dọ̀tí, táwọn adìyẹ á sì máa sá kiri. Láìka àwọn nǹkan yẹn sí, a gbádùn iṣẹ́ ìsìn wa gan-an.
À ń lọ sóde ẹ̀rí
Tí mo bá ń ronú àwọn nǹkan tí mo ti ṣe sẹ́yìn, mo máa ń dúpẹ́ pé àwọn òbí mi ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti kọ́ mi ní òtítọ́, wọn ò sì pa mí tì lásìkò tí mi ò fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Jèhófà. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 22:6 ló ṣẹ sí mi lára torí pé inú àwọn òbí mi ń dùn pé èmi àti Alex fi ìgbésí ayé wa ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àtọdún 2016 la ti ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká láwọn ibi tí ẹ̀ka Australasia ń bójú tó.
Mò ń fi fídíò Kọ́lá àti Tósìn han àwọn ọmọ kan ní Timor-Leste, inú wọn sì ń dùn
Ó máa ń yà mí lẹ́nu pé ìgbà kan wà tí iṣẹ́ ìwàásù máa ń sú mi. Àmọ́ ní báyìí, mò ń gbádùn ẹ̀ gan-an! Mo ti wá rí i pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí wa, tá a bá sin Jèhófà tọkàntọkàn nìkan la máa tó ní ayọ̀ tòótọ́. Ó ti tó ọdún méjìdínlógún (18) báyìí témi àti Alex ti jọ ń ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kí n má parọ́, àwọn ọdún yẹn ni mo láyọ̀ jù nígbèésí ayé mi. Mo ti wá rí i báyìí pé òótọ́ lohun tí Dáfídì sọ fún Jèhófà pé: “Gbogbo àwọn tó fi ọ́ ṣe ibi ààbò á máa yọ̀; ìgbà gbogbo ni wọ́n á máa kígbe ayọ̀. . . . Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ yóò sì máa yọ̀ nínú rẹ.”—Sm. 5:11.
Inú wa dùn gan-an bá a ṣe ń kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
a Láti ọdún 1975, ohun tó lé ní ogún (20) ọdún làwọn èèyàn fi jagun lórílẹ̀-èdè Timor-Leste kí wọ́n lè gba òmìnira.
b A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.