ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w21 October ojú ìwé 29-31
  • 1921—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1921—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • WỌ́N WÀÁSÙ LÁÌBẸ̀RÙ
  • ÌDÁKẸ́KỌ̀Ọ́ ÀTI ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ ÌDÍLÉ
  • A ṢE ÌWÉ TUNTUN KAN!
  • IṢẸ́ ṢÌ PỌ̀ TÁ A MÁA ṢE
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Ṣe Ìfẹ́ Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • 1922—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Àwọn Ìpinnu Tó Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìran Méje Tó Sin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
w21 October ojú ìwé 29-31

1921 Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn

“KÍ NI iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ ká dáwọ́ lé lọ́dún yìí?” Ìbéèrè yìí ni Ilé Ìṣọ́ January 1, 1921 (lédè Gẹ̀ẹ́sì) bi àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ti gbára dì. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Àìsáyà 61:​1, 2 ló dáhùn ìbéèrè náà. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn rán wọn létí iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n máa ṣe, ó ní: “Jèhófà ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ . . . , láti kéde ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà àti ọjọ́ ẹ̀san Ọlọ́run wa.”

WỌ́N WÀÁSÙ LÁÌBẸ̀RÙ

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbọ́dọ̀ nígboyà kí wọ́n tó lè wàásù. Ìdí ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere fáwọn oníwà pẹ̀lẹ́, kí wọ́n sì kéde “ọjọ́ ẹ̀san” fáwọn èèyàn burúkú.

Arákùnrin J. H. Hoskin tó gbé ní Kánádà wàásù láìbẹ̀rù bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kojú àtakò. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1921, ó kojú àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì kan. Nígbà tí Arákùnrin Hoskin bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé: “Kò yẹ ká máa bá ara wa jà lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, tí èrò wa ò bá tiẹ̀ ṣọ̀kan lórí àwọn nǹkan kan, ìyẹn ò ní ká gbéná wojú ara wa.” Àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ kọ́ nìyẹn. Arákùnrin Hoskin sọ pé: “Ìṣẹ́jú díẹ̀ la ṣì fi sọ̀rọ̀ tí àlùfáà náà fìbínú gbá ilẹ̀kùn, ńṣe làyà mi já, àfi bíi pé gíláàsì ilẹ̀kùn náà máa bọ́ fọ́ sílẹ̀.”

Àlùfáà náà pariwo mọ́ mi pé: “Kí ló dé tó ò lọ bá àwọn tí kì í ṣe Kristẹni sọ̀rọ̀? Arákùnrin Hoskin ò sọ nǹkan kan, àmọ́ bó ṣe ń kúrò níbẹ̀, ó ń sọ fún ara ẹ̀ pé, ‘Mo tiẹ̀ rò pé Kristẹni lẹni tí mò ń bá sọ̀rọ̀!’

Nígbà tí àlùfáà náà ń wàásù nínú ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ lọ́jọ́ kejì, ó sọ ohun tí ò dáa nípa mi. Arákùnrin Hoskin sọ pé: “Ó kìlọ̀ fáwọn ọmọ ìjọ ẹ̀ pé kí wọ́n máa sá fún mi. Ó ní èmi ni ẹlẹ́tàn tó burú jù lọ ní ìlú yẹn àti pé ńṣe ló yẹ kí wọ́n yìnbọn pa mí.” Arákùnrin Hoskin kò jẹ́ kí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun, ó ń wàásù nìṣó, àwọn èèyàn sì ń tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo gbádùn iṣẹ́ ìwàásù tí mo ṣe níbẹ̀ gan-an. Kódà, àwọn kan lára àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ sọ pé, ‘A mọ̀ pé èèyàn Ọlọ́run ni ẹ́!’ wọ́n sì sọ pé kí n jẹ́ káwọn mọ̀ tí mo bá nílò ohunkóhun.”

ÌDÁKẸ́KỌ̀Ọ́ ÀTI ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ ÌDÍLÉ

Kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè tẹ̀ síwájú, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan sínú ìwé ìròyìn The Golden Age.a Wọ́n gbé ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kan jáde tí wọ́n ń pè ní Juvenile Bible Study. Àpilẹ̀kọ yìí ní àwọn ìbéèrè táwọn òbí lè jíròrò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ètò Ọlọ́run dábàá pé kí àwọn òbí “bi àwọn ọmọ wọn ní ìbéèrè, kí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ ibi tí wọ́n ti máa rí ìdáhùn náà nínú Bíbélì.” Ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa Bíbélì ni: “Ìwé mélòó ló wà nínú Bíbélì?” Ìbéèrè míì ni: “Ṣé gbogbo àwọn Kristẹni ló máa kojú inúnibíni?” Irú àwọn ìbéèrè yìí máa ń jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ nígboyà láti wàásù.

A tún gbé ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kan jáde tá a pè ní Advanced Studies in the Divine Plan of the Ages. Àpilẹ̀kọ yìí ní àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́ àgbàlagbà lè ronú jinlẹ̀. Inú ìdìpọ̀ àkọ́kọ́ ìwé Studies in the Scriptures la sì ti mú àwọn ìbéèrè náà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí ló jàǹfààní látinú wọn. Àmọ́ ìwé ìròyìn The Golden Age ti December 21, 1921 kéde pé wọn ò ní gbé àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yẹn jáde mọ́. Àmọ́, kí nìdí tí wọ́n fi ṣe ìpinnu yẹn?

A ṢE ÌWÉ TUNTUN KAN!

Ìwé Duru Ọlọrun

Káàdì tó ń sọ ibi tí wọ́n máa kà

Káàdì tó ní àwọn ìbéèrè

Àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó ètò Ọlọ́run rí i pé ipele-ipele ló yẹ káwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Torí náà, ní November ọdún 1921, a ṣe ìwé kan tó ń jẹ́ Duru Ọlọrun. Àwọn tó gba ìwé Duru Ọlọrun bẹ̀rẹ̀ ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n ń fi ìwé náà ṣe fúnra wọn. Ìwé yìí ran àwọn tó kà á lọ́wọ́ láti mọ̀ pé “Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé káwọn èèyàn jogún ìyè àìnípẹ̀kun.” Báwo ni wọ́n ṣe ń fi ìwé náà dáni lẹ́kọ̀ọ́?

Tí ẹnì kan bá gba ìwé Duru Ọlọrun, wọ́n máa ń fi káàdì kékeré kan sínú rẹ̀ kó lè mọ ibi tó máa kà. Tó bá di ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e wọ́n máa fi káàdì míì ránṣẹ́ sí i. Àwọn ìbéèrè tó dá lórí ibi tó kà àti ibi tó máa kà lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e ló wà nínú káàdì náà.

Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni ìjọ tó wà nítòsí á máa fi káàdì tuntun ránṣẹ́ sí akẹ́kọ̀ọ́ náà. Ọ̀sẹ̀ méjìlá ni wọ́n á sì fi ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn àgbàlagbà tí ò lè lọ wàásù láti ilé délé tàbí àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ lókun nínú ìjọ ló máa ń fi káàdì náà ránṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Anna K. Gardnrer tó ń gbé ní Millvale lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Mo ní ẹ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Thayle tí kò lè rìn, àmọ́ nígbà tí wọ́n tẹ ìwé Duru Ọlọrun jáde, ìyẹn mú kọ́wọ́ ẹ̀ dí gan-an torí pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló ń fi káàdì ránṣẹ́ sáwọn èèyàn.” Tí ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà bá ti parí, ẹnì kan á lọ sọ́dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ náà láti ràn án lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì rẹ̀.

Arábìnrin Thayle Gardner wà lórí kẹ̀kẹ́ arọ

IṢẸ́ ṢÌ PỌ̀ TÁ A MÁA ṢE

Ní ìparí ọdún yẹn, Arákùnrin J. F. Rutherford fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ. Ó sọ pé: “Ìwàásù tá a ṣe lọ́dún yìí pọ̀ ju gbogbo èyí tá a ti ṣe láwọn ọdún tó ṣáájú, òun ló sì gbéṣẹ́ jù.” Ó fi kún un pé: “Iṣẹ́ ṣì pọ̀ tá a máa ṣe. Torí náà, ẹ gba àwọn míì níyànjú láti dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ pàtàkì yìí.” Ó sì dájú pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ohun tó sọ yẹn. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ó hàn gbangba pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi ìgboyà wàásù Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.

Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Nígboyà

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an torí pé wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́. Ṣe làwọn ọ̀rẹ́ tó nígboyà yìí dà bí ọ̀rẹ́ tá a “bí fún ìgbà wàhálà” bá a ṣe máa rí i nínú ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí.​—Òwe 17:17.

Ìjà kan ṣẹlẹ̀ ní Tuesday, May 31, 1921 nílùú Tulsa, Oklahoma, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn tí wọ́n dájọ́ fún ọkùnrin aláwọ̀ dúdú kan pé ó jẹ̀bi torí pé ó lu obìnrin aláwọ̀ funfun kan, wọ́n sọ ọkùnrin náà sẹ́wọ̀n. Ẹ̀yìn ìyẹn ni àwọn aláwọ̀ funfun tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) gbéjà ko àwọn aláwọ̀ dúdú tí ò tóyẹn, ni wọ́n bá fìjà pẹ́ẹ́ta. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ìjà náà ti dé agbègbè Greenwood táwọn èèyàn dúdú ń gbé. Ilé àti ṣọ́ọ̀bù tó ju ẹgbẹ̀rún kan ó lé irínwó (1,400) ni wọ́n dáná sun, àmọ́ wọ́n kọ́kọ́ jí ẹrù wọn kó kí wọ́n tó ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn oníròyìn sọ pé àwọn mẹ́rìndínlógójì (36) ló kú, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé ó ṣeé ṣe káwọn tó kú lé ní ọgọ́rùn-ún.

Aláwọ̀ dúdú ni Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń jẹ́ Richard J. Hill, agbègbè Greenwood ló sì ń gbé. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “A ṣèpàdé lálẹ́ ọjọ́ tíjà yẹn bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn tá a parí ìpàdé, a gbọ́ pé wọ́n ń yìnbọn láàárín ìlú. Kódà, nígbà tá a fẹ́ lọ sùn, a ṣì ń gbọ́ ìró ìbọn náà.” Nígbà tó máa fi di àárọ̀ ọjọ́ kejì, Wednesday, June 1, ìjà náà ti le gan-an. Ó tún sọ pé: “Àwọn kan wá bá wa, wọ́n sì sọ fún wa pé tá ò bá fẹ́ kí wọ́n pa wá, àfi ká yáa tètè máa lọ sí Gbọ̀ngàn Ìlú.” Torí náà, Arákùnrin Hill mú ìyàwó ẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn márààrún, wọ́n sì sá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìlú tó wà nílùú Tulsa. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àwọn aláwọ̀ dúdú lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló wà ní Gbọ̀ngàn Ìlú náà, àwọn ọlọ́pàá sì ń ṣọ́ wọn káwọn jàǹdùkú má bàa wá yọ wọ́n lẹ́nu.

Àkókò yẹn ni Arákùnrin Arthur Claus tó jẹ́ aláwọ̀ funfun gbé ìgbésẹ̀ akin. Ó ní: “Nígbà tí mo gbọ́ pé àwọn jàǹdùkú ti ń jà káàkiri ìlú Greenwood, wọ́n ń kó ẹrù àwọn èèyàn, wọ́n sì ń dáná sun ilé. Ohun tí mo ṣe ni pé mo sáré lọ wo Arákùnrin Hill ọ̀rẹ́ mi.”

Arákùnrin Arthur Claus fi ìwé Duru Ọlọrun kọ́ àwọn ọmọ mẹ́rìnlá (14) yìí lẹ́kọ̀ọ́

Nígbà tó dé ilé Arákùnrin Hill, ó rí ọkùnrin aláwọ̀ funfun kan tó ń gbé ládùúgbò yẹn tó gbé ìbọn dání. Ọ̀rẹ́ Arákùnrin Hill ni ọkùnrin aláwọ̀ funfun yìí, ó sì rò pé Arákùnrin Arthur wà lára àwọn jàǹdùkú náà. Ó wá pariwo mọ́ Arákùnrin Arthur pé: “Kí lò ń ṣe nínú ọgbà yẹn?”

Arákùnrin Arthur sọ pé: “Ká ní ìdáhùn tí mo fún un ò tẹ́ ẹ lọ́rùn ni, á ti yìnbọn fún mi. Mo jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀rẹ́ Arákùnrin Hill ni mí, mi ò sì ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá sílé ẹ̀.” Arákùnrin Arthur àti aládùúgbò yẹn ló ṣọ́ ilé Arákùnrin Hill táwọn jàǹdùkú yẹn ò fi ráyè wọbẹ̀.

Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Arákùnrin Arthur mọ̀ pé Arákùnrin Hill àti ìdílé ẹ̀ ti wà ní Gbọ̀ngàn Ìlú. Wọ́n sọ fún Arthur pé àwọn èèyàn dúdú tó wà níbẹ̀ ò lè kúrò níbẹ̀ àfi tí Ọ̀gágun Barrett tó ń bójú tó ibẹ̀ bá fọwọ́ sí i. Arákùnrin Arthur sọ pé: “Kò rọrùn rárá láti rí ọ̀gágun yẹn bá sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo sọ fún ọ̀gágun náà pé mo fẹ́ mú ìdílé náà kúrò níbẹ̀, ó bi mí pé: ‘Ṣé wàá ṣọ́ wọn dáadáa, ṣé wàá sì pèsè gbogbo ohun tí wọ́n nílò?’ Kíákíá ni mo sọ pé bẹ́ẹ̀ ni.”

Lẹ́yìn tí Arthur gbàwé àṣẹ, ó sáré lọ sí Gbọ̀ngàn Ìlú náà. Ó wá fi ìwé náà han ọlọ́pàá tó wà níbẹ̀, ìyẹn wá sọ pé: “Ọ̀gágun fúnra ẹ̀ ló tiẹ̀ fọwọ́ síwèé yìí! Ṣé o mọ̀ pé ìwọ lẹni àkọ́kọ́ tó máa wá mú èèyàn kúrò níbí?” Kò pẹ́ tí wọ́n fi rí Arákùnrin Hill àti ìdílé ẹ̀, ni gbogbo wọn bá fún ara wọn mọ́nú mọ́tò Arákùnrin Arthur, ó sì gbé wọn lọ sílé.

“Ìkan náà ni gbogbo wa nínú ètò Ọlọ́run”

Arákùnrin Claus rí i dájú pé nǹkan kan ò ṣe Arákùnrin Hill àti ìdílé ẹ̀. Nígbà táwọn míì rí ìgboyà àti ìfẹ́ ará tí Arákùnrin Claus ní, ó mórí wọn wú. Arákùnrin Arthur sọ pé: “Ọkùnrin aláwọ̀ funfun témi àti ẹ̀ jọ ṣọ́ ilé Arákùnrin Hill bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Àwọn míì tún nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere nígbà tí wọ́n rí i pé kò sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà láàárín wa àti pé ìkan náà ni gbogbo wa nínú ètò Ọlọ́run.”

a Ní 1937 a bẹ̀rẹ̀ sí í pe ìwé ìròyìn The Golden Age ní Consolation, nígbà tó sì di 1946 a bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Awake!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́