ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w23 December ojú ìwé 32
  • Ìrírí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrírí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fàánú Hàn sí Gbogbo Èèyàn
  • Máa Fàánú Hàn Bíi Ti Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • “Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Ẹ Ní Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Máa Ṣàánú Fáwọn Ẹlòmíì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
w23 December ojú ìwé 32

Ìrírí

Máa Fàánú Hàn sí Gbogbo Èèyàn

Lọ́jọ́ kan, arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè New Zealand wo fídíò tá a pe àkòrí ẹ̀ ní ‘Ẹ Máa Ṣìkẹ́ Ara Yín.’ Fídíò yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé Jèhófà máa ń káàánú wa nìkan ni, ó tún máa ń fàánú hàn sí wa. (Àìsá. 63:7-9) Arábìnrin yẹn wá pinnu pé òun á wá bí òun ṣe máa fàánú hàn sáwọn èèyàn. Nígbà tó lọ sọ́jà lọ́jọ́ yẹn kan náà, ó rí obìnrin kan tí ò nílé, ó sì bi í pé ṣé òun lè ra oúnjẹ fún un. Obìnrin náà gbà pé kó ra oúnjẹ fún òun. Nígbà tí arábìnrin yẹn gbé oúnjẹ náà dé, ó fi ìwé Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin? wàásù fún obìnrin náà.

Ni obìnrin náà bá bú sẹ́kún. Ó ṣàlàyé fún arábìnrin yẹn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí òun, àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn lòun ti kúrò nínú òtítọ́. Ó wá sọ pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, òun bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ láti pa dà sínú òtítọ́. Arábìnrin yẹn fún un ní Bíbélì, ó sì ṣètò bá á ṣe máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́.a

Àwa náà lè jẹ́ aláàánú bíi ti Jèhófà, ká máa fàánú hàn sí gbogbo èèyàn títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wa àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ. A tún lè fi hàn pé a jẹ́ aláàánú tá a bá ń wá bá a ṣe máa wàásù fáwọn èèyàn.

a Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, wo àpilẹ̀kọ náà “Ẹ Pa Dà Sọ́dọ̀ Mi” nínú Ilé Ìṣọ́ June 2020.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́