ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 100-101
  • Wọ́n Máa Ń Pè É ní Bible Brown

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Máa Ń Pè É ní Bible Brown
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìfẹ́ Kì Í Kùnà Láé”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • 1923—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Orílẹ̀-Èdè Sierra Leone Di Àrímáleèlọ fún Mi
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Nípa Lórí Ìgbésí Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 100-101

SIERRA LEONE ÀTI GUINEA

Wọ́n Máa Ń Pè É ní Bible Brown

William R. Brown

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1879

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1908

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Òun ló mú ipò iwájú nígbà tí iṣẹ́ ìwàásù bẹ̀rẹ̀ ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà.

LỌ́DÚN 1907, nígbà tí William lọ ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń kọ́ Ipadò ìlú Panama, ó gbọ́ àsọyé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ìyẹn àsọyé Isaiah Richards tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí wọ́n ṣe ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Orí àwòrán tí wọ́n pè ní Chart of the Ages ni ìwàásù náà dá lé, wọ́n máa ń fi àwòrán yìí ṣàlàyé àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni William gba ẹ̀kọ́ òtítọ́, ó sì pa dà sí orílẹ̀-èdè Jàmáíkà kó lè lọ fi kọ́ màmá rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ obìnrin. Kò sì pẹ́ tí àwọn náà fi di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ìgbà kan wà tí Arákùnrin Brown ṣiṣẹ́ sìn ní ìlú Panama, lórílẹ̀-èdè Panama. Ibẹ̀ ló ti pàdé Arákùnrin Evander J. Coward, tó jẹ́ aṣojú àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa ń rìnrìn àjò káàkiri láti sọ àsọyé, ohun tó gbé e wá sílẹ̀ Panama nìyẹn. Ọ̀rọ̀ Arákùnrin Coward máa ń rinlẹ̀, ó sì máa ń wọni lọ́kàn gan-an, èrò máa ń rọ́ wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nígbà tó kíyè sí i pé William ní ìtara fún ẹ̀kọ́ òtítọ́, ó ní kó tẹ̀ lé òun lọ sí erékùṣù Trinidad káwọn lè jọ máa wàásù.

Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá tó tẹ̀ lé e, William ń rìnrìn àjò káàkiri àwọn erékùṣù West Indies, ó ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ó sì ń ran àwọn àwùjọ kéékèèké lọ́wọ́. Lọ́dún 1920, ó fẹ́ arábìnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Antonia. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó, William àti Antonia wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí erékùṣù kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Montserrat, ní erékùṣù Leeward. Wọ́n sì ń fi àwòrán Photo-Drama of Creation [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] han àwọn èèyàn. Wọ́n tún wàásù ní erékùṣù Barbados, Dominica àti Grenada. Ẹnu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni wọ́n ti lo àsìkò ìsinmi oníyọ̀tọ̀mì tí àwọn alárédè máa ń ṣe lẹ́yìn ìgbéyàwó.

Ọdún méjì lẹ́yìn náà, William kọ̀wé sí Arákùnrin Joseph F. Rutherford, tó ń bójú tó iṣẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà ní àkókò yẹn, ó ní: “Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè jẹ́rìí kúnnákúnná fún ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní àwọn erékùṣù Caribbean, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ti di ọmọ ẹ̀yìn níbẹ̀. Ṣé kí n pa dà lọ máa bẹ̀ wọ́n wò?” Láàárín ọjọ́ bíi mélòó kan, Arákùnrin Rutherford fèsì pé: “Orílẹ̀-èdè Sierra Leone ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ni kó o lọ, ìwọ, ìyàwó àti ọmọ rẹ.”

Ní ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] tí Arákùnrin Brown àti ìdílé rẹ̀ fi sìn ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, kò sígbà kankan tó tẹ́ ẹ lọ́rùn pé kó kàn jókòó sínú ọ́fíìsì. Òde ẹ̀rí ló máa ń wù ú pé kó wà. Àwọn èèyàn sì máa ń pè é ní Bible Brown torí pé ó máa ń tẹnu mọ́ bí Bíbélì ti ṣe pàtàkì tó.

Nígbà tí Arákùnrin William Brown pé ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rin [71] lọ́dún 1950, òun àti ìyàwó rẹ̀ pa dà sí orílẹ̀-èdè Jàmáíkà, wọ́n sì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Arákùnrin William ṣe aṣáájú-ọ̀nà títí tó fi parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lọ́dún 1967. Ó mà fẹ́ràn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà o! Ó máa ń wò ó bí ọ̀kan lára ohun tó dára jù téèyàn lè láǹfààní láti ṣe.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́