Bòlífíà: Wọ́n ń kọ́ ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè Aymara ní ìlú El Alto
Àwọn ohun pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún tó kọjá
NÍGBÀ tí Bíbélì ń ṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run máa gbé ṣe nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀, Áísáyà 9:7 sọ pé: “Ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.” Bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba yẹn ṣe fi ìtara tó lé kenkà hàn fún ìjọsìn tòótọ́ jálẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 2:17) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé náà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù bá a ṣe ń fi ìtara wàásù káwọn èèyàn lè wá jadùn ìfẹ́ Jèhófá, Bàbá wa ọ̀run. Àwọn ìròyìn tó tẹ̀ lé e yìí fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.
El salvador: Àpéjọ agbègbè 2015