ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 2/22 ojú ìwé 13-15
  • Àwọn Eré Ìdárayá Ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ Wọ́n Ha Dára fún Mi Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Eré Ìdárayá Ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ Wọ́n Ha Dára fún Mi Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Eré Ìdárayá—Àwọn Àǹfààní Rẹ̀
  • Òkìkí, Àlùbáríkà, àti Ìgbajúmọ̀
  • Àwọn Afìdírẹmi
  • Ó Ha Yẹ Kí N Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ Eléré Ìdárayá Bí?
    Jí!—1996
  • Ìfọkànsin Ọlọ́run Tàbí Eré Ìdárayá
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Eré Ìdárayá?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Eré Ìdárayá Àwọn Èwe—Ìwà Ipá Tuntun Tó Ń tàn Kálẹ̀
    Jí!—2002
Jí!—1996
g96 2/22 ojú ìwé 13-15

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Àwọn Eré Ìdárayá Ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ Wọ́n Ha Dára fún Mi Bí?

“Mo nífẹ̀ẹ́ eré ìdárayá. Ó máa ń mú ara mi yá gágá. Mo sì gbádùn wíwà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi.”—Sandy, ọmọ ọdún 14.

“ÌMÓRÍYÁ!” “Ìrunisókè!” “Bíborí!” Ìwọ̀nyí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tí àwọn èwe United States àti Kánádà sọ pé ó fà á tí àwọ́n fi máa ń kópa nínú àwọn eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́, nígbà tí a ṣèwádìí lọ́wọ́ wọn. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ àwọn èwe máa ń ṣàjọpín ìtara ọkàn wọn.

Fún àpẹẹrẹ, wo United States. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Your Child in Sports, láti ọwọ́ Lawrence Galton ti sọ, “lọ́dọọdún, 20 mílíọ̀nù lára àwọn èwe ilẹ̀ America, láti ọmọ ọdún mẹ́fà sókè ni wọ́n ń kópa, tàbí gbìyànjú láti kópa, nínú àwọn eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́.” Nígbà tí ó sì jẹ́ pé ni ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, kìkì àwọn ọkùnrin nìkan ló wà nínú àwọn eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́, ọ̀pọ̀ jaburata àwọn ọmọdébìnrin ti ń ṣíjú sí eré baseball, eré bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀, àti bíbá ara wọn díje lórí pápá ìgbábọ́ọ̀lù pàápàá.

Bóyá ìwọ náà fẹ́ràn eré ìdárayá, o sì lérò pé dídara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan yóò jẹ́ ohun tí ń mórí yá. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn òbí, olùkọ́, tàbí àwọn olùdánilẹ́kọ̀ọ́ eré ìdárayá ń fún ọ ní ìṣírí púpọ̀—bóyá kí wọ́n tilẹ̀ máa fagbára mú ọ pàápàá—láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun yòówù kí ọ̀ràn náà jẹ́, kíkó wọnú eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ máa ń béèrè fún yíya àkókò àti agbára tí ó pọ̀ sọ́tọ̀ fún un. Nígbà náà, ó bọ́gbọ́n mu pàápàá láti mọ díẹ̀ lára àwọn àǹfààní àti àléébù rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, jẹ́ kí a wo díẹ̀ lára àwọn àǹfààní rẹ̀.

Eré Ìdárayá—Àwọn Àǹfààní Rẹ̀

Bibeli sọ pé: “Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti ara ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀.” (1 Timoteu 4:8) Ó sì dájú pé àwọn ọ̀dọ́ lè jàǹfààní láti inú lílo ara wọn. Ní United States, àwọn ọ̀dọ́ tí iye wọn pọ̀ jọjọ ní ń jìyà lọ́wọ́ ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀, ẹ̀jẹ̀ ríru, àti àpọ̀jù èròjà cholesterol. Ṣíṣe eré ìmárale déédéé lè ṣe púpọ̀ láti dín irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ kù. Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn American Health ti sọ, àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n máa ń ṣe eré ìmárale déédéé “máa ń ní agbára àtimí àti ìṣàngeere ẹ̀jẹ̀ ju àwọn ọ̀dọ́ ajókòógẹlẹtẹ sójú kan [aláìfara-ṣiṣẹ́] lọ. Àwọn tí wọ́n sábà máa ń ṣe eré ìmárale tún máa ń ṣe dáradára nínú eré ìdárayá, wọn kì í sanra ju bí ó ṣe yẹ lọ.” Àwọn olùṣèwádìí tún sọ pé, eré ìmárale lè yọni nínú másùnmáwo, ó lè dín àárẹ̀ ara kù, ó sì lè mú kí oorun rẹ sunwọ̀n sí i.

Ó dùn mọ́ni nínú pé, ìwé Your Child in Sports sọ pé: “Ó ti hàn kedere pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣòro ìlera tí àwọn àgbàlagbà ń ní máa ń pilẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n wà léwe.” Ọ̀pọ̀ àwọn dókítà wá tipa bẹ́ẹ̀ ronú pé àǹfààní tí ó wà nínú ṣíṣe eré ìmárale déédéé lè nasẹ̀ dé ìgbà tí ènìyàn bá dàgbà. Òǹkọ̀wé Mary C. Hickey ròyìn pé: “Ìwádìí ti ṣàwárí pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ tí ń ṣe eré ìdárayá ṣe ṣámúṣámú bí wọ́n bá dàgbà.”

Ọ̀pọ̀ ènìyàn lérò pé, àwọn àǹfààní pàtàkì míràn wà nínú kíkópa nínú àwọn eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Bàbá kan sọ nípa ọmọkùnrin rẹ̀ tí ń gbá bọ́ọ̀lù pé: ‘Kì í jẹ́ kí ó máa fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri òpópónà. Ó ń kọ́ ọ bí ó ṣe lè mú ìgbésí ayé rẹ̀ wá sábẹ́ àkóso.’ Àwọn mìíràn lérò pé kíkópa nínú eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ń kọ́ èwe kan láti lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn—òye iṣẹ́ tí ó lè ní àwọn àǹfààní ayérayé. Eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ tún ń kọ́ àwọn èwe láti tẹ̀ lé ìlànà, láti ní ìkóra-ẹni-níjàánu, láti mọ bí a ṣe ń jẹ́ aṣíwájú rere, àti láti lè ní ìtẹ́lọ́rùn tí wọ́n bá ṣàṣeyọrí tàbí tí wọ́n bá kùnà. Dókítà George Sheehan sọ pé: “Àwọn eré ìdárayá jẹ́ ọ̀nà àtikẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọ̀dọ́. Wọ́n máa ń jẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìrírí àwọn ohun tí wọ́n sábà máa ń gbọ́ lẹ́nu àwọn olùkọ́ wọn ní tààràtà: ìgboyà, òye iṣẹ́, ìfọkànsìn.”—Current Health, September 1985.

Ó kéré tán, wíwà nínú ẹgbẹ́ kan tí ó borí lè pa kún iyì ara ẹni ẹnì kan. Eddie, tí ó jẹ́ ọ̀dọ́, sọ pé: “Bí mo bá ń gé àwọn ènìyàn légèé tàbí tí mo bá ń ju bọ́ọ̀lù wọlé, mo máa ń yangàn nípa ara mi gan-an.”

Òkìkí, Àlùbáríkà, àti Ìgbajúmọ̀

Bí ó ti wù kí ó rí, ní ti àwọn èwe mìíràn, ohun tí ó fà wọ́n mọ́ra ní ti gidi nínú àwọn eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ni jíjèrè ojú rere àti ìkanisí láti ọ̀dọ̀ àwọn ojúgbà wọn. Gordon, ọmọ ọdún 13, ṣàlàyé pé: “Gbogbo ìgbà tí o bá ṣe ohun tí ó dára, gbogbo ènìyàn yóò máa yìn ọ́.”

Ìwé Teenage Stress, láti ọwọ́ Susan àti Daniel Cohen, gbà pé: “Bí ó bá jọ pé ọ̀nà gidi kan wà tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbajúmọ̀, ní pàtàkì fún àwọn ọmọdékùnrin, eré ìdárayá ni. . . . Ó ṣòro kí a tó rí gbajúgbajà nínú ẹgbẹ́ eléré bọ́ọ̀lù tàbí ti bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ tí a kò kà sí.” Ìwádìí kan fi bí àwọn eléré ìdárayá ṣe ní iyì ara ẹni tó hàn. Wọ́n bi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ léèrè bóyá wọ́n fẹ́ pé kí a ṣèrántí àwọn fún jíjẹ́ gbajúgbajà eléré ìdárayá, akẹ́kọ̀ọ́ tí ó mòye, tàbí fún jíjẹ́ ẹni tí ó gbajúmọ̀ jù lọ. Láàárín àwọn ọmọdékùnrin, jíjẹ́ “gbajúgbajà eléré ìdárayá” ni yíyàn àkọ́kọ́.

Pé agbábọ́ọ̀lù kan tàbí agbábọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ kan ń rí ọ̀wọ̀ gbà ju ọ̀mọ̀wé kan lọ kò yani lẹ́nu lọ títí bí o bá ronú nípa àfiyèsí oníjọsìn tí àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde dà sórí àwọn tí ń fi eré ìdárayá ṣiṣẹ́ ṣe. Púpọ̀ lára ìpolongo náà dá lórí owó oṣù gọbọi tí wọ́n ń gbà àti irú ìgbésí ayé alájẹẹ̀wẹ̀yìn tí wọ́n ń gbé. Abájọ nígbà náà tí ọ̀pọ̀ àwọn èwe, ní pàtàkì àwọn tí wọ́n wà láàárín àwọn ìlú ńlá elérò, lè wo eré ìdárayá ní ilé ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́ bí òkúta ìtìsẹ̀ kọjá sínú aásìkí—ọ̀nà àtijàbọ́ kúrò nínú ipò òṣì!

Ó ṣeni láàánú pé, ìfojúsọ́nà náà kì í ṣẹnuure ní ti gidi. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Current Health tí ó ní àkọlé náà “Àwọn Eléré Ìdárayá Mélòó Ló Rọ́wọ́ Mú?” fúnni ní àwọn ìṣirò amúniṣe-wọ̀ọ̀ díẹ̀. Ó ròyìn pé: “Ó lé ní mílíọ̀nù 1 àwọn ọmọdékùnrin [ní United States] tí ń gbá bọ́ọ̀lù ní ilé ẹ̀kọ́ gíga; ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àwọn 500,000 tí ń gbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀; nǹkan bí 400,000 sì ń kópa nínú eré baseball. Láti ilé ẹ̀kọ́ gíga sí kọ́lẹ́ẹ̀jì, iye àwọn olùkópa ń lọ sílẹ̀ gan-an. Kìkì nǹkan bí 11,000 eléré ìdárayá lápapọ̀ ní ń kópa nínú bọ́ọ̀lù gbígbá, bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀, àti eré baseball ní kọ́lẹ́ẹ̀jì.” Láti ibẹ̀, ìṣirò náà túbọ̀ wá burú sí i. “Kìkì nǹkan bí ìpín 8 nínú ọgọ́rùn-ún [lára àwọn eléré ìdárayá ní kọ́lẹ́ẹ̀jì] ni àwọn ẹgbẹ́ eléré ìdárayá àfiṣiṣẹ́ṣe tilẹ̀ máa ń mú, tí ìpín 2 nínú ọgọ́rùn-ún péré sì máa ń fọwọ́ sí ìwé àdéhùn fífi ṣeṣẹ́ ṣe.” Àpilẹ̀kọ náà wá ránni létí pé: “Kódà, fífọwọ́ sí ìwé àdéhùn fífi ṣeṣẹ́ ṣe kò túmọ̀ sí pé eléré ìdárayá náà yóò rí ipò kan wọ̀ nínú ẹgbẹ́ náà.”

Nígbà náà, nínú gbogbo rẹ̀, “ọ̀kan péré lára àwọn 12,000 eléré ìdárayá ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ni yóò di ẹni tí ń fi ṣiṣẹ́ ṣe.” Ìyẹ́n lè ṣàìfi ibì kan dára ju ẹtì jíjẹ tẹ́tẹ́ lọ́tìrì lọ! Ṣùgbọ́n ó kéré tán, o lè ṣe kàyéfì pé, ṣé eléré ìdárayá kan kò lè rí ẹ̀bùn ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ kọ́lẹ́ẹ̀jì gbà fún gbogbo wàhálà rẹ̀ ni? Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ẹtì rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ dára tó. Gẹ́gẹ́ bí ìwé On the Mark, láti ọwọ́ Richard E. Lapchick àti Robert Malekoff ti sọ, “lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn eléré ìdárayá ní ilé ẹ̀kọ́ gíga . . . , 1 péré lára 50 ni yóò rí ẹ̀bùn ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ gbà kí wọ́n lè ṣe eré ìdárayá ní kọ́lẹ́ẹ̀jì.” Ìṣirò amúnisoríkọ́ mìíràn ni pé: “Lára àwọn agbábọ́ọ̀lù tí wọ́n mú ipò iwájú tí wọ́n rí ẹ̀bùn ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ gbà nínú àwọn eré ìdárayá tí ń mówó wá gan-an bíi bọ́ọ̀lù gbígbá àti bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀, ohun tí kò tó ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún ni yóò lè kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní kọ́lẹ́ẹ̀jì lẹ́yìn ọdún mẹ́rin.”

Ní ti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn eléré, àlá dídi eléré ìdárayá tí ó lọ́rọ̀, tí ó sì lókìkí wulẹ̀ jẹ́ àlá asán—àlá tí kò lè ṣẹ.

Àwọn Afìdírẹmi

Bí o bá gbé àwọn ìfojúsọ́nà nípa ìlera sísàn, ìyípadà ìwà, àti ìgbajúmọ̀ tí ń pọ̀ sí i yẹ̀ wò, dídara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eléré ìdárayá lè dà bí ohun bíbọ́gbọ́nmu láti ṣe. Ṣùgbọ́n kí o tó kánjú lọ kópa nínú àwọn eré àfidánniwò, ronú nípa ohun tí a sọ nínú ìwé ìròyìn Ladies’ Home Journal pé: “Àwọn èwe púpọ̀ sí i ń lọ forúkọ sílẹ̀ níbi eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ lóde òní ju bí àwọn ti ìran ìṣáájú mìíràn ti ṣe lọ. Ìròyìn búburú ibẹ̀ ni pé: Iye tí ó pọ̀ jọjọ ní ń fi ètò eré ìdárayá wọ̀nyí sílẹ̀.” A fa ọ̀rọ̀ Ọmọ̀wé Vern Seefeldt, ògbógi nínú kókó ọ̀rọ̀ yìí, yọ nígbà tí ó sọ pé: “Nígbà tí wọn yóò bá fi di ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ìpín márùnléláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èwe tí wọ́n ti kópa nínú eré ìdárayá kan rí yóò ti fi í sílẹ̀.”

Wo Kánádà, níbi tí eré ìdárayá bọ́ọ̀lù àfigigbá lórí yìnyín ti gbajúmọ̀ gidigidi. Nínú ìsọ̀wọ́ àwọn aláṣenajú eré bọ́ọ̀lù àfigigbá kan, ìpín 53 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn 600,000 eléré ni kò tí ì tó ọmọ ọdún 12. Bí ó ti wù kí ó rí, ìpín 11 nínú ọgọ́rùn-ún péré ni ó lé ní ọmọ ọdún 15. Kí ló fa èyí? Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀dọ́ ni wọ́n ti jáwọ́ nígbà tí wọ́n dé ọjọ́ orí yẹn. Èé ṣe tí àwọn púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fi ń jáwọ́?

Àwọn olùṣèwádìí sọ pé irú àwọn tí ń fi eré ìdárayá sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ sábà máa ń sọ ìdí ṣákálá kan tí ó yani lẹ́nu fún lílọ kúrò wọn pé: Àwọn eré àṣedárayá náà kì í mórí yá mọ́. Ní tòótọ́, kíkópa nínú eré ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ kan lè jẹ́ ohun ìdáwọ́lé tí ń tánni lókun, tí ó sì ń gba àkókò. Ìwé ìròyìn Seventeen sọ fún àwọn tí ń kà á pé wíwulẹ̀ gbìyànjú díje fún ipò kan nínú ẹgbẹ́ kan lè kan ṣíṣiṣẹ́ “wákàtí mẹ́ta lóòjọ́, fún ọjọ́ márùn-ún lọ́sẹ̀ . . . fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì.” Bí o bá la ìrírí agbonijìgì yẹn já, tí o sì di ara ẹgbẹ́ náà, o ṣì ní wákàtí púpọ̀ sí i láti lò fún ṣíṣe eré ìmárale àṣedánrawò àti àwọn eré àṣekọ́ra lọ́jọ́ iwájú. Ohun kan náà ní ń ṣẹlẹ̀ sí mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ àwọn obìnrin agbábọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ tí ń lo ohun tí ó lé ní wákàtí mẹ́ta lóòjọ́ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nínú eré àṣedárayá rẹ̀. O lè lo àkókò yẹn láti ṣe ohun tí ó túbọ̀ mọ́yán lórí sí i.

Ó dájú pé ọ̀pọ̀ àwọn èwe kò ka iṣẹ́ àṣetúnṣe atánnilókun náà sí. Wọ́n ń gbádùn ìmóríyá àti ìpèníjà dídi ògbóṣáṣá nínú òye eré ìdárayá wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ìdí mìíràn tún wà tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn èwe ṣe ń fi eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ sílẹ̀. O yẹ kí o mọ̀ wọ́n, kí o lè pinnu bóyá kí o dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan ni tàbí kí o má ṣe bẹ́ẹ̀. Bí Owe 13:16 ti sọ, “gbogbo amòye ènìyàn ní ń fi ìmọ̀ ṣiṣẹ́.” Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan lọ́jọ́ iwájú yóò tipa bẹ́ẹ̀ máa bá ìjíròrò yìí lọ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

‘Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn agbábọ́ọ̀lù tí wọ́n ń mú ipò iwájú ní yunifásítì, tí wọ́n rí ẹ̀bùn ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ gbà nídìí eré ìdárayá ni kò lè kẹ́kọ̀ọ́ jáde’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ìgbajúmọ̀ àwọn eléré ìdárayá máa ń fa àfiyèsí ọ̀pọ̀ àwọn èwe mọ́ àwọn eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́