ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 3/22 ojú ìwé 21-23
  • Ó Ha Yẹ Kí N Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ Eléré Ìdárayá Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Yẹ Kí N Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ Eléré Ìdárayá Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíborí Lọ́nàkọnà Kẹ̀?
  • Fífi Ìwà Rere Dúnàádúrà
  • Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ti Ara Tàbí Èṣe Ti Ara?
  • Àwọn Kókó Abájọ Mìíràn Tí A Ní Láti Yẹ̀ Wò
  • Ṣíṣe Ìpinnu Tí Ó Mọ́gbọ́n Dání
  • Àwọn Eré Ìdárayá Ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ Wọ́n Ha Dára fún Mi Bí?
    Jí!—1996
  • Eré Ìdárayá Àwọn Èwe—Ìwà Ipá Tuntun Tó Ń tàn Kálẹ̀
    Jí!—2002
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Eré Ìdárayá?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìfọkànsin Ọlọ́run Tàbí Eré Ìdárayá
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
Jí!—1996
g96 3/22 ojú ìwé 21-23

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ó Ha Yẹ Kí N Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ Eléré Ìdárayá Bí?

ÀPILẸ̀KỌ kan nínú ìwé ìròyìn Seventeen béèrè pé: “Kí ló ṣe bàbàrà nípa wíwà nínú ẹgbẹ́ eléré ìdárayá kan?” Àpilẹ̀kọ náà dáhùn pé: “Ẹ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ fún góńgó kan náà, nítorí náà, ẹ óò sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí gan-an. Ẹ óò tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa àjọṣepọ̀ ẹ̀dá, irú bí ọ̀nà tí ẹ lè gbà yanjú ìṣòro láàárín ẹgbẹ́ kan, bí a kò ṣe ní máa rinkinkin mọ́ nǹkan, tí a sì ń gba tẹni rò, àti bí a ṣe lè máa juwọ́ sílẹ̀.”

Nípa bẹ́ẹ̀, ó jọ pé ṣíṣe eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ní àwọn àǹfààní kan, tí kì í ṣe pé àbárèbábọ̀ gbogbo rẹ̀ náà kàn ni ìmóríyá àti ìmárale.a Àwọn kan tilẹ̀ sọ pé ṣíṣe eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ń ranni lọ́wọ́ láti mú ìwà kan dàgbà. Ìyẹn ló fà á tí ẹgbẹ́ àwọn èwe kan tí ń gbá baseball fi ní àkọlé náà, “Ìwà, Ìgboyà, Ìṣòtítọ́.”

Ìṣòro tí ó wà níbẹ̀ ni pé, eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ kì í kúnjú ìwọ̀n irú àwọn ìgbèrò rere bẹ́ẹ̀ yẹn. Ìwé Kidsports sọ pé: “Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, àwọn èwe tí nǹkan tètè máa ń ṣí lórí ń kọ́ bí a ṣe ń búra, rẹ́ni jẹ, báni jà, halẹ̀ mọ́ni, àti bí a ṣe ń pa àwọn ẹlòmíràn lára.”

Bíborí Lọ́nàkọnà Kẹ̀?

Àpilẹ̀kọ kan sọ nínú ìwé ìròyìn Seventeen pé: “Apá búburú kan wà níbi eré ìdárayá, òun ni kí àwọn ènìyàn kó ìjẹ́pàtàkì ńláǹlà jọ sórí bíborí.” Èyí jẹ́ òdì kejì ohun tí Bibeli sọ gan-an pé: “Ẹ máṣe jẹ́ kí a di olùgbéra-ẹni-lárugẹ, ní ríru ìdíje sókè pẹlu ara wa lẹ́nìkínní kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nìkínní kejì.” (Galatia 5:26) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdíje ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lẹ́tù ráńpẹ́ kan lè mú kí eré ìdárayá kan dùn mọ́ni, kí ó sì gbádùn mọ́ni, ẹ̀mí ìdíje tí ó ré kọjá ààlà lè gbé ìdojúùjà koni dìde—kí ó má sì jẹ́ kí eré náà múni lórí yá mọ́.

Jon, tí ó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù fún ilé ẹ̀kọ́ gíga kan tẹ́lẹ̀ rí, rántí pé: “A ní olùdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó jẹ́ agbawèrèmọ́ṣẹ́ gidi; ó máa ń kébòòsí, ó sì máa lọgun mọ́ wa . . . Mo máa ń fòyà láti lọ síbi ìdánrawò eré. . . . Mo máa ń nímọ̀lára bí ẹni pé mo wà nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àwọn olùdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ń ṣeni ṣìbáṣìbo, ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń gbé ìtẹnumọ́ tí ó pọ̀ karí bíborí. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn eléré ìdárayá . . . máa ń dé orí kókó kan tí ìnira gógó tí kò ṣeé pa mọ́ra nípa kíkẹ́sẹ járí yóò ti fún ayọ̀ dídíje pa.” Kí ló lè jẹ́ àbájáde rẹ̀?

Ìwé ìròyìn Science News ròyìn nípa ìwádìí kan tí ó fi hàn pé láàárín àwọn agbábọ́ọ̀lù ẹlẹ́sẹ̀ àti bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ ní kọ́lẹ́ẹ̀jì, “ìpín 12 nínú ọgọ́rùn-ún ló ròyìn pé àwọ́n ní ìṣòro nínú, ó kéré tán, agbègbè méjì nínú agbègbè ìṣòro márùn-ún: wàhálà ọpọlọ, wàhálà ara, ìṣòro yíyẹra fún oògùn líle tàbí ọtí líle, ìlòkúlò ọpọlọ àti ti ara, àti àìṣedáradára tó ní ilé ẹ̀kọ́.” Nípa ohun kan náà, ìwé On the Mark ròyìn pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn tó ní nǹkan í ṣe pẹ̀lú eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ni yóò gbà pé ìṣòro gidi nípa ìlòkulò oògùn líle nínú eré ìdárayá wà ní ìpele gbogbo.”

Fífi Ìwà Rere Dúnàádúrà

Ìkìmọ́lẹ̀ ti bíborí tún lè mú kí ọ̀dọ́ agbábọ́ọ̀lù kan fi àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n bíbọ́gbọ́n mu ti híhùwà tí ó tọ́ àti àìlábòsí kan dúnàádúrà. Ìwé Your Child in Sports sọ pé: “Ní ayé eré ìdárayá ti òde òní, kì í wulẹ̀ ṣe pé bíborí dára nìkan ni; òun ni ohun kan ṣoṣo tí ó nítẹ̀ẹ́wọ́gbà. Kì í ṣe pé pípàdánù burú nìkan ni, àmọ́ kò ní ìtẹ́wọ́gbà.”

Òtítọ́ kíkorò míràn ni pé: Àwọn olùdánilẹ́kọ̀ọ́ sábà máa ń fi àwọn agbábọ́ọ̀lù sábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ láti ṣe àwọn tí wọ́n ń bá díje léṣe. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Psychology Today sọ pé: “Láti jẹ́ eléré ìdárayá tí ó gbayì, o ní láti jẹ́ ẹni burúkú. Tàbí kí ó jẹ́ pé ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn eléré ìdárayá, àwọn olùdánilẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn olólùfẹ́ eré ìdárayá gbà gbọ́ nìyẹn.” Ẹnì kan tí ń fi bọ́ọ̀lù gbígbá ṣiṣẹ́ ṣe ṣàpèjúwe irú ẹni tí òún jẹ́ gan-an gẹ́gẹ́ bí “olóhùn pẹ̀lẹ́, agbatẹnirò àti ẹni bí ọ̀rẹ́.” Ṣùgbọ́n tí ó bá dórí pápá ìṣeré, ó máa ń yí padà di oníjàgídíjàgan. Nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe ìwà rẹ̀ lórí pápá ìṣiré, ó wí pé: “Mo máa ń ṣìkà, mo sì máa ń bínú nígbà náà. . . . Mo rorò gan-an. N kò bọ̀wọ̀ fún àwọn aláwèé tí mo máa ń rọ́ lù rárá.” Àwọn olùdánilẹ́kọ̀ọ́ sábà máa ń fún irú ìwà bẹ́ẹ̀ níṣìírí.

Bibeli gba àwọn Kristian nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inúrere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú, ìwàtútù, ati ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” (Kolosse 3:12) Ṣé o lè mú irú ànímọ́ bẹ́ẹ̀ dàgbà bí o bá ń gbọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan ń sọ láti rọ̀ ọ́ láti ṣe àwọn abánidíje rẹ léṣe, kí o gún wọn mọ́lẹ̀, kí o sọ apá kan ara wọn di aláìwúlò? Robert ọmọ ọdún 16 jẹ́wọ́ pé: “Mo ti kópa nínú eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Kò sí ohun tí ó kàn ọ́ nípa ẹni yòówù kí o ṣe léṣe, bí ẹ bá ṣáà ti lè borí.” Nísinsìnyí tí ó ti di Kristian tí a batisí, ojú ìwòye rẹ̀ ti yí padà. Ó wí pé: “N kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ láé.”

Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ti Ara Tàbí Èṣe Ti Ara?

Bákan náà, a kò tún ní gbójú fo àwọn ewu ti ara tí ó wà nínú rẹ̀ dá. Lótìítọ́, àwọn eré ìdárayá ní ewu nínú kódà nígbà tí a bá ń ṣe wọ́n pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ fún ète ìmóríyá pàápàá. Ṣùgbọ́n àwọn ewu ibẹ̀ máa ń pọ̀ sí i nígbà tí a bá dá àwọn èwe lẹ́kọ̀ọ́ láti gbìyànjú láti kópa bíi ti àwọn tí ń fi ṣiṣẹ́ ṣe.

Ìwé Your Child in Sports sọ pé: “Àwọn tí ń fi bọ́ọ̀lù gbígbá ṣiṣẹ́ ṣe lè ní ìpalára. Ṣùgbọ́n wọ́n ní òye iṣẹ́ gan-an, wọ́n rí ara gbà á sí, wọ́n jẹ́ àgbàlagbà tí ó dàgbà dénú, tí ó máa ń fínnúfíndọ̀ kó sínú ewu fífarapa, tí a sì máa ń sanwó fún wọn dáadáa fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Síwájú sí i, wọ́n sábà máa ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó dára jù lọ, irú èyí tí a máa ń fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn amọṣẹ́dunjú, ohun èèlò tí ó dára jù lọ, àti ìtọ́jú ìṣègùn dídára jù lọ tí ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn. . . . Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kò ní irú àǹfààní bẹ́ẹ̀.” A wí fún àwọn Kristian láti ‘fi ara wọn fún Ọlọrun ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.’ (Romu 12:1) Kò ha yẹ kí o ronú dáadáa lórí kíkó ara rẹ sínú àwọn ewu tí kò bọ́gbọ́n mu tàbí tí kò pọn dandan bí?

Àwọn Kókó Abájọ Mìíràn Tí A Ní Láti Yẹ̀ Wò

Kódà nígbà tí ó bá jọ pé àwọn ewu ìlera ibẹ̀ kò tó nǹkan, eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ ṣì máa ń gba àsìkò ẹni. Àwọn àkókò ìdánrawò lè ṣàìdín àkókò ìgbafẹ́ rẹ kù nìkan ṣùgbọ́n wọ́n tún lè gba ọ̀pọ̀ jù lọ lára àkókò tí ó yẹ kí o yà sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́ ilé. Ìwé ìròyìn Science News ròyìn pé àwọn eléré ìdárayá ní kọ́lẹ́ẹ̀jì máa ń ní ìtẹ̀sí láti gbé “ipò tí ó rẹlẹ̀ díẹ̀” ju ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí ń kópa nínú àwọn eré ẹ̀yìn àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn lọ. Ní pàtàkì jù, o lè rí i pé ṣíṣeré pẹ̀lú ẹgbẹ́ eléré ìdárayá kan yóò mú kí ó ṣòro láti lépa ohun tí Bibeli pè ní “awọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù”—ire ti ẹ̀mí. (Filippi 1:10) Bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ṣé dídara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan yóò béèrè pé kí n máa pa àwọn ìpàdé Kristian jẹ, tàbí yóò ha pààlà sí bí mo ṣe ń ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìwàásù bí?’

Tún fi tìṣọ́ratìṣọ́ra ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tí ó lè jẹ́ ìyọrísí lílo wákàtí púpọ̀ pẹ̀lú àwọn èwe àti àwọn àgbàlagbà tí wọn kò ṣàjọpín ojú ìwòye rẹ nípa ìwà rere, ọ̀rọ̀ rere, tàbí ìdíje. Ó ṣe tán, Bibeli ti sọ ọ́ pé “awọn ẹgbẹ́ búburú a máa ba awọn àṣà-ìhùwà wíwúlò jẹ́.” (1 Korinti 15:33) Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa àpilẹ̀kọ kan tí ó wà ní ìdojúkọ ojú ewé kejì ìwé agbéròyìnjáde The New York Times tí ó wí pé: “Iyàrá ìmúra . . . ni ibi tí àwọn ọkùnrin ti máa ń sọ̀rọ̀ ìṣekúṣe nípa ara àwọn obìnrin láìfibò, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń yangàn nípa ‘bí wọ́n ṣe pa obìnrin láyò’ àti àwọn yẹ̀yẹ́ nípa lílu àwọn obìnrin.” Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣe sí nípa tẹ̀mí bí o bá yàn láti wà nínú irú àyíká bẹ́ẹ̀?—Fi wé Jakọbu 3:18.

Ṣíṣe Ìpinnu Tí Ó Mọ́gbọ́n Dání

Ìwọ́ ha ti ń ronú nípa dídara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eléré ìdárayá kan bí? Nígbà náà, bóyá ohun tí a ti ń sọ bọ̀ yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ro ohun tí yóò ná ọ wò. Máa ronú nípa ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn nígbà tí o bá ń ṣe ìpinnu rẹ. (1 Korinti 10:24, 29, 32) Dájúdájú, a kò lè gbé àṣẹ oníkùmọ̀ kan kalẹ̀, níwọ̀n bí ipò nǹkan ti yàtọ̀ síra káàkiri àgbáyé. Ní àwọn apá ibì kan, a tilẹ̀ lè béèrè pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kópa nínú eré ìdárayá. Ṣùgbọ́n bí o bá ń ṣe ìyè méjì, jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ tàbí pẹ̀lú Kristian kan tí ó dàgbà dénú.

Ọ̀pọ̀ àwọn èwe Kristian ti ṣe ìpinnu dan-indan-in láti má ṣe kópa nínú àwọn eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Èyí kò rọrùn bí o bá jẹ́ olùfẹ́ eré ìdárayá, tí o sì máa ń gbádùn eré ìdárayá! Ìkìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olùkọ́, àwọn olùdánilẹ́kọ̀ọ́, àti àwọn òbí lè pa kún ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì náà. Jimmy ọ̀dọ́ jẹ́wọ́ pé: “Ìjàkadì gbáà ni ó jẹ́ fún mi láti má ṣe kópa. Gbajúgbajà eléré ìdárayá ni bàbá mi tí í ṣe aláìgbàgbọ́ jẹ́ nígbà tí ó ṣì ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Ìṣòro ńlá ni ó máa ń jẹ́ fún mi nígbà míràn láti má dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eléré kan.” Síbẹ̀síbẹ̀, ìtìlẹ́yìn àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ àti àwọn Kristian tí wọ́n dàgbà dénú nínú ìjọ lè ṣe púpọ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ. Jimmy sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ mọ́mì mi. Mo máa ń ní ìsoríkọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nígbà tí àwọn ènìyàn bá ń tì mí sí ṣíṣe eré ìdárayá. Ṣùgbọ́n ó sábà máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti rán mi létí àwọn góńgó pàtàkì tí mo ń lépa nínú ìgbésí ayé.”

Eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ lè kọ́ àwọn olùkópa ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti bí a ṣeé yanjú ìṣòro. Ṣùgbọ́n àǹfààní púpọ̀ wà láti kẹ́kọ̀ọ́ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣiṣẹ́ láàárín ìjọ Kristian. (Fi wé Efesu 4:16.) Eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ tún lè jẹ́ ohun amóríyá, ṣùgbọ́n kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà tí o bá wà nínú ẹgbẹ́ eléré kan kí o tó gbádùn wọn. A lè gbádùn eré ìdárayá kan ní ẹ̀yìnkùlé tàbí ní ọgbà ìtura àdúgbò kan pẹ̀lú àwọn Kristian tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ wa. Jíjáde lọ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdílé rẹ lè pèsè àwọn àǹfààní síwájú sí i fún eré tí ó gbámúṣé. Greg, ọmọ ọdún 16, sọ pé: “Ó máa ń dára jù láti bá àwọn mìíràn láti ìjọ ẹni ṣeré. Nítorí kí ó lè mú orí yá ni a fi ń ṣe é, ìwọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sì ni!”

Lóòótọ́, ó ṣeé ṣe kí ṣíṣeré lẹ́yìnkùlé máà mú irú ìwúrí tí a máa ń rí nígbà tí ẹgbẹ́ kan bá borí wá. Àmọ́, má ṣe gbàgbé pé lábẹ́ ipò dídára jù lọ, “ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti ara ṣàǹfààní fún [kìkì] ohun díẹ̀; ṣugbọn ìfọkànsìn Ọlọrun ṣàǹfààní fún ohun gbogbo.” (1 Timoteu 4:8) Mú ìfọkànsìn Ọlọrun dàgbà, ìwọ yóò sì jẹ́ olùborí ní ti gidi lójú Ọlọrun!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Eré Ìdárayá Ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́—Wọ́n Ha Dára fún Mi Bí?” tí ó jáde nínú ìtẹ̀jáde wa ti February 22, 1996.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

“A ní olùdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó jẹ́ agbawèrèmọ́ṣẹ́ gidi; ó máa ń kébòòsí, ó sì máa ń lọgun mọ́ wa . . . Mo máa ń fòyà láti lọ síbi ìdánrawò eré”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn olùdánilẹ́kọ̀ọ́ sábà máa ń tẹnu mọ́ bíborí—kódà bí ó bá túmọ̀ sí ṣíṣe àwọn ẹlòmíràn léṣe

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́