ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 53
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Eré Ìdárayá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Eré Ìdárayá?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àǹfààní wo ló lè ṣe ẹ́?
  • Ìpalára wo ló lè ṣe fún ẹ?
  • Ìfọkànsin Ọlọ́run Tàbí Eré Ìdárayá
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Ó Ha Yẹ Kí N Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹgbẹ́ Eléré Ìdárayá Bí?
    Jí!—1996
  • Àwọn Eré Ìdárayá Ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ Wọ́n Ha Dára fún Mi Bí?
    Jí!—1996
  • Eré Ìdárayá Àwọn Èwe—Ìwà Ipá Tuntun Tó Ń tàn Kálẹ̀
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 53
Àwọn ọ̀dọ́ kan ń gbá bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Eré Ìdárayá?

Eré ìdárayá lè ṣe ẹ́ láǹfààní tàbí kó pa ẹ́ lára. Irú eré tó o bá ṣe, bó o bá ṣe ṣe é àti bí àkókò tó o fi ṣe eré ọ̀hún bá ṣe pọ̀ tó ló máa pinnu.

  • Àǹfààní wo ló lè ṣe ẹ́?

  • Ìpalára wo ló lè ṣe fún ẹ??

  • Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Àǹfààní wo ló lè ṣe ẹ́?

Tó o bá ń ṣe eré ìdárayá, ó máa jẹ́ kí ìlera rẹ dáa. Bíbélì sọ pé, “Eniyan a máa rí anfaani. . .tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá.” (1 Tímótì 4:8, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Ryan sọ pé, “Eré ìdárayá máa ń mú kí ara jí pépé, torí èèyàn máa sá síbí sá sọ́hùn-ún. Ó dáa ju kéèyàn kàn jókòó sínú ilé kó máa gbá géèmù.”

Eré ìdárayá máa jẹ́ kó o lè bá àwọn ẹlòmíì ṣiṣẹ́ pọ̀, kó o sì máa kó ara ẹ níjàánu. Bíbélì lo àpèjúwe kan tó dá lórí eré ìdárayá láti fi kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ kan. Ó sọ pé: “Gbogbo àwọn sárésáré nínú eré ìje ní ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣoṣo ní ń gba ẹ̀bùn náà.” Ó wá sọ pé: “Olúkúlùkù ènìyàn tí ń kó ipa nínú ìdíje a máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 9:​24, 25) Kí la rí kọ́? Kéèyàn tó lè ṣe eré ìdárayá kan bí wọ́n ṣe ń ṣe é, ó gba kéèyàn kó ara rẹ̀ níjàánu, kó sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó kù. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Abigail sọ pé òun fara mọ́ ọn, ó ní, “Eré ìdárayá ti jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn míì, ká sì gbọ́ra wa yé.”

Eré ìdárayá máa ń mú káwọn èèyàn túbọ̀ rẹ́. Eré ìdárayá máa ń gba pé káwọn èèyàn ṣe nǹkan pọ̀. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jordan sọ pé, “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí eré ìdárayá tí ò ní gba pé káwọn tó ń ṣe é bára wọn díje lọ́nà kan ṣá, àmọ́ téèyàn ò bá mú un le kankan, tó kà á sí pé òun àtàwọn ọ̀rẹ́ òun kàn ń gbafẹ́ ni, ó máa jẹ́ kí gbogbo wọn gbádùn ẹ̀ gan-an, wọ́n á sì túbọ̀ rẹ́.”

Ìpalára wo ló lè ṣe fún ẹ?

Irú eré ìdárayá tó ò ń ṣe. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”​—Sáàmù 11:5.

Àwọn eré ìdárayá kan wà tó máa gba pé kéèyàn hùwà ipá. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Lauren kíyè sí i pé: “Ohun tó máa ń wà lọ́kàn àwọn tó máa ń kan ẹ̀ṣẹ́ ni pé kí wọ́n lu ẹnì kejì bolẹ̀. Àmọ́ àwa Kristẹni kì í jà, torí náà, ṣé ó yẹ ká máa wo àwọn tí wọ́n ń kó ẹ̀ṣẹ́ bora wọn, ká lá à ń gbafẹ́?”

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé o ti ń rò ó pé kò sóhun tó burú nínú kó o máa ṣe eré ìdárayá oníwà ipá tàbí kó o máa wò ó, kó o máa wá sọ lọ́kàn ẹ pé o ò lè torí ìyẹn lọ máa hùwà ipá? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, rántí ohun tí Sáàmù 11:5 sọ, pé Jèhófà kórìíra ẹni tó “nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá,” kì í ṣe ẹni tó ń ṣe é nìkan.

Bó o ṣe ń ṣe é. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ má ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.’​—Fílípì 2:3.

Ó dájú pé tó bá ti jẹ́ pé àwùjọ méjì ló jọ ń ṣe eré kan, wọ́n á bára wọn díje lọ́nà kan ṣá. Àmọ́ tọ́rọ̀ bá ti ń di pé ‘dandan ni kí n borí,’ eré ọ̀hún ò ní dùn mọ́. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Brian sọ pé, “Tá a bá ń ṣeré ìdárayá, téèyàn ò bá ṣọ́ra, kò ní mọ ìgbà tó máa bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹnì kejì díje. Béèyàn bá ṣe ń mọ eré náà ṣe ló yẹ kó túbọ̀ sapá láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.”

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Chris sọ pé, “Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la máa ń gbá bọ́ọ̀lù, a sì máa ń ṣèṣe.” Torí náà, bi ara rẹ pé, ‘Àwọn nǹkan wo ló lè mú kẹ́ ẹ ṣèṣe tẹ́ ẹ bá ń ṣeré ìdárayá? Kí ni mo lè ṣe ká má bàa ṣèṣe?’

Àkókò tó o fi ṣe eré náà. Bíbélì sọ pé: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:​10.

Mọ ohun tó yẹ kó o fi sí ipò àkọ́kọ́, ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ló yẹ kó wà nípò àkọ́kọ́. Ọ̀pọ̀ géèmù ló máa ń gba èèyàn lákòókò, ì báà jẹ́ pé ṣe lèèyàn ń wò ó tàbí ó ń gbá a. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Daria sọ pé, “Mọ́mì mi máa ń bá mi jà torí mo máa ń pẹ́ nídìí géèmù, wọ́n á ní nǹkan gidi ló yẹ kí n máa fi àkókò yẹn ṣe.”

Ẹnì kan ń rọ́ iyọ̀ sínú oúnjẹ

Téèyàn bá gbájú mọ́ eré ìdárayá ju bó ṣe yẹ lọ, ṣe ló máa dà bí ẹni ń rọ́ iyọ̀ sí oúnjẹ

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Táwọn òbí ẹ bá ń gbà ẹ́ nímọ̀ràn nípa ohun tó yẹ kó o fi sípò àkọ́kọ́, ṣé o máa ń fetí sí wọn? Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Trina sọ pé: “Témi àtàwọn àbúrò mi bá ń wo eré ìdárayá, tá a wá torí ìyẹn pa iṣẹ́ pàtàkì tó yẹ ká ṣe tì, mọ́mì máa rán wa létí pé yálà a wo àwọn tó ń ṣeré yẹn tàbí a ò wò wọ́n, wọ́n ń gba owó tiwọn. Wọ́n á wá bi wá pé, ‘Àmọ́ ta ló ń sanwó fún ẹ̀yin?’ Ohun tí mọ́mì ní lọ́kàn mi pé àwọn tó ń ṣeré ìdárayá ti níṣẹ́ tiwọn. Àmọ́ tá ò bá ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá wa, tá a sì pa àwọn ojúṣe míì tì, a ò ní lè bójú tó ara wa lọ́jọ́ iwájú. Kókó ọ̀rọ̀ mọ́mì ni pé kò yẹ ká jẹ́ kí eré ìdárayá gbà wá lọ́kàn, yálà à ń ṣe é ni tàbí à ń wò ó.”

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ RẸ SỌ

Abigail

“Yàtọ̀ sí pé eré ìdárayá jẹ́ ọ̀nà tá a fi lè ṣe eré ìmárale, ó tún máa ń múnú ẹni dùn, ó sì máa ń mú kéèyàn gbádùn ayé. Ó máa ń kọ́ni pé èèyàn lè borí ìdíje tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀, ó sì máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé kò dín iyì ẹni kù béèyàn ò tiẹ̀ borí.”​—Abigail.

Deven

“Mo fẹ́ràn eré ìdárayá, àmọ́ àwọn nǹkan míì wà tó ṣe pàtàkì sí mi jùyẹn lọ. Ohun témi máa ń ṣe ni pé, tí mo bá ti ṣe àwọn iṣẹ́ tó yẹ kí n ṣe, màá wá fi eré dára yá. Ó máa ń sún mi ṣiṣẹ́, ó sì máa ń jẹ́ kí n mọ àwọn ohun tó yẹ kí n kà sí pàtàkì.”​—Deven.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́