ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 6/22 ojú ìwé 3-4
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ fún Ìsinmi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ fún Ìsinmi?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìsinmí Ní Àyè Tirẹ̀
  • Ìrìn Àjò, Òun Fúnra Rẹ̀ Jẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́
  • Ìmúrasílẹ̀ Tí Ó Yẹ
  • Gbádùn Ìsinmi Láìkábàámọ̀!
    Jí!—1996
  • Bí O Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Ewu Àkókò Ìsinmi
    Jí!—1998
  • Ohun Tí Ó Yẹ Kí O Ṣọ́ra Fún
    Jí!—1996
Jí!—1996
g96 6/22 ojú ìwé 3-4

Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ fún Ìsinmi?

ÌGBÀ ẹ̀ẹ̀rùn ní Àríwá Ìlàjì Ayé kù fẹ́ẹ́fẹ́ẹ́. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn yóò máa lọ fún ìsinmi láìpẹ́. Àmọ́, kì í ṣe ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn nìkan ni a máa ń lọ fún ìsinmi. Ìrìn àjò afẹ́ ti di òwò àṣeyípo ọdún, tí ń mú ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là wá lọ́dọọdún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùre ìsinmi ń rìnrìn àjò láàárín orílẹ̀-èdè wọn, ìrìn àjò òkèèrè, tí a fi mọ sáàárín àwọn ọlọ́rọ̀ nígbà kan, ti wá di tọ̀mútọ̀gbọ̀.

Iye àkókò ìsinmi tí àwọn agbanisíṣẹ́ máa ń fúnni yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Ní 1979, ìpín 2 péré nínú ọgọ́rùn-ún lára agbo àwọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Germany ni ó gba ìsinmi ọ̀sẹ̀ mẹ́fà, àmọ́, ní báyìí àwọn púpọ̀ ló ń gbà á. Ìpíndọ́gba àkókò ìsinmi fún àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ní Ìwọ̀ Oòrùn Europe lé ní ọ̀sẹ̀ márùn-ún.

Ìsinmí Ní Àyè Tirẹ̀

Látilẹ̀ wá ni ìsinmí ti túmọ̀ sí ohun tí ó yàtọ̀ gédégédé sí ìtumọ̀ rẹ̀ lónìí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ṣàlàyé pé: “Lílo ìsinmi lóde òní . . . ni a fà yọ láti inú kàlẹ́ńdà ìsìn Róòmù ìgbàanì lọ́nà àṣà tó jẹ́ òdì kejì sí ohun tí ó túmọ̀ sí. Ó lé ní 100 ọjọ́ nínú ọdún tí wọ́n fi ń ṣe àjọ̀dún tí wọ́n yà sí mímọ́ fún onírúurú àwọn ọlọ́run àti abo ọlọ́run ilẹ̀ Róòmù. Ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún mímọ́ ọlọ́wọ̀, tí ó tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọjọ́ mímọ́, àwọn ènìyàn máa ń sinmi lẹ́nu ìgbòkègbodò àṣetúnṣe ojoojúmọ́ wọn. Àwọn ọjọ́ tí wọn kò kà sí mímọ́ ọlọ́wọ̀ ni wọ́n ń pè ní dies vacantes, ọjọ́ ọwọ́dilẹ̀, tí àwọn ènìyàn fi máa ń ṣiṣẹ́.” Kàkà kí ó jẹ́ ọjọ́ iṣẹ́, “àwọn ọjọ́ ọwọ́dilẹ̀” òde òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.

Àwọn ará Germany fẹ́ràn láti máa pe àkókò ìsinmi ni “ọ̀sẹ̀ dídára jù lọ lọ́dún.” Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn aláṣekúdórógbó lè ka “àwọn ọjọ́ ọwọ́dilẹ̀” òde òní sí èyí tí ọwọ́ ti dilẹ̀ ní tòótọ́, tí kò ní ìgbòkègbodò gúnmọ́ kan. Síbẹ̀síbẹ̀, èyí yóò jẹ́ ojú ìwòye aláṣejù. Ojú ìwòye wíwà déédéé fàyè gba ọgbọ́n tí ó wà nínú kíkúrò lẹ́nu ìgbòkègbodò àṣetúnṣe ẹni lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ní ṣíṣe ohun tí ó yàtọ̀, kí a sì ní ìdẹ̀ra.

Apá títọ̀nà nípa ìsinmi ni a fìdí ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ nínú ìwádìí kan tí a ṣe ní 1991 láàárín àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ òwò ní Europe, 78 nínú 100 lára wọ́n sọ pé ìsinmi “ṣe pàtàkì pátápátá gbáà láti dènà ìsúni.” Odindi ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin wọ́n lérò pé ìsinmi ń mú kí ọ̀nà ìṣiṣẹ́ ẹní sunwọ̀n sí i, ohun tí ó sì lé ní ìdá méjì nínú mẹ́ta sọ pé ìsinmí ń mú kí agbára ìronúwòye sunwọ̀n sí i. Lọ́nà tí ó túbọ̀ fara hàn dáradára, ìpín 64 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin àti ìpín 41 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú gbólóhùn náà pé: “Ìwàdéédéé èrò ìmọ̀lára mi yóò dojú rú bí n kò bá lọ fún ìsinmi déédéé.”

Ìrìn Àjò, Òun Fúnra Rẹ̀ Jẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́

Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí ó jẹ́ oníṣègùn àti òǹkọ̀wé ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, Thomas Fuller, kọ̀wé pé: “Ẹni tí ń rìnrìn àjò déédéé, yóò mọ ohun púpọ̀.” Ìrìn àjò ń jẹ́ kí a lè mọ àwọn ènìyàn níbòmíràn, kí a kọ́ nípa àṣà àti ọ̀nà ìgbésí ayé wọn. Rírìnrìn àjò ní àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé ibẹ̀ kò tó tiwa lè kọ́ wa láti mọrírì ohun tí a ní, ó sì lè ta ìmọ̀lára ìfọ̀ràn-rora-ẹni-wò jí nínú wa fún àwọn ènìyàn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lálùbáríkà tó wa.

Bí a bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìrìn àjò lè ṣàtúnṣe àwọn èrò òdì, kí ó sì lé ẹ̀tanú jìnnà. Ó ń pèsè àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́, ó kéré tán, díẹ̀ nínú èdè tuntun kan ní tààràtà láti orísun rẹ̀, láti gbìyànjú oríṣiríṣi oúnjẹ tí ó lè gbádùn mọ́ wa lẹ́nu, tàbí láti fi àpẹẹrẹ ẹwà inú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá kún àkójọ fọ́tò, àkójọ fọ́tò sinimá ara ògiri, tàbí ibi àwọn àkójọ fídíò ti ìdílé wa.

Dájúdájú, láti jàǹfààní jù lọ, a gbọ́dọ̀ ṣe púpọ̀ sí i ju rírìnrìn àjò lọ. Arìnrìn àjò afẹ́ tí ó re àjò ìdajì ayé kìkì láti lọ há mọ́ hòtẹ́ẹ̀lì kan láàárín àwọn arìnrìn àjò afẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀—tí ọ̀pọ̀ lára wọ́n jẹ́ ará ìlú rẹ̀—láti lúwẹ̀ẹ́ nínú ìkùdu ìlúwẹ̀ẹ́ tàbí etíkun hòtẹ́ẹ̀lì náà, àti láti máa jẹ irú oúnjẹ kan náà tí ó ń jẹ nílé, kì yóò rí ohun púpọ̀ kọ́. Ó mà ṣe o! Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí a gbọ́, ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn arìnrìn àjò máa ń kùnà láti ní ọkàn-ìfẹ́ jíjinlẹ̀ nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sí tàbí nínú àwọn ènìyàn ibẹ̀.

Ìmúrasílẹ̀ Tí Ó Yẹ

Samuel Johnson, aláròkọ àti eléwì ti ọ̀rúndún kejìdínlógún, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé ẹni tí ń rìnrìn àjò “gbọ́dọ̀ mú ìmọ̀ dání lọ, bí ó bá fẹ́ láti mú ìmọ̀ wálé.” Nítorí náà, bí o bá ní ìdí láti rìnrìn àjò, múra sílẹ̀ fún ìrìn àjò rẹ. Kà nípa ibi tí o ń lọ kí o tó gbéra. Wéwèé ohun tí o fẹ́ láti rí, kí o sì pinnu ohun tí o fẹ́ láti ṣe. Nígbà náà, múra sílẹ̀ bí ó ti yẹ. Fún àpẹẹrẹ, bí o bá fẹ́ láti rin ìrìn ìgbafẹ́ ní etíkun tàbí pọ́n àwọn òkè ńláńlá, kó bàtà àti aṣọ tí ó yẹ dání.

Má ṣe gbìyànjú láti kó ohun púpọ̀ jù kún ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ kí o wá di pé gbogbo másùnmáwo ìgbésí ayé ojoojúmọ́ lo kó wọnú ìsinmi rẹ. Fi àkókò púpọ̀ tí a kò wéwèé fún ohunkóhun sílẹ̀ láti ṣe àwọn ohun àìròtẹ́lẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní gidi ti lílọ fún ìsinmi ni níní àkókò láti ronú kí a sì ṣàṣàrò láìsí ìkìmọ́lẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ híhá gádígádí, nínímọ̀lára wíwà lómìnira kúrò nínú másùnmáwo àti ìkálọ́wọ́kò ti ṣíṣiṣẹ́ bí agogo.

Ìsinmi tí ó lérè gidigidi tilẹ̀ lè ní iṣẹ́ àṣekára nínú. Lápapọ̀, ṣíṣe ohun tí ó yàtọ̀ ni kọ́kọ́rọ́ sí ìsinmi tí ó gbámúṣé. Fún àpẹẹrẹ, àjọ kan ní United States, tí kì í ṣe fún ète ìṣòwò, tí ń jẹ́ Àkókò Ìsinmi Ìyọ̀ọ̀da-Ara-Ẹni, ṣètò fún àwọn tí wọ́n yọ̀ọ̀da ara wọn láti lo àkókò ìsinmi fún títún àwọn igbó ọba tàbí ẹgàn orílẹ̀-èdè ṣe. Olùyọ̀ọ̀da ara ẹni kan sọ pé òún ṣiṣẹ́ kárakára, síbẹ̀síbẹ̀ òún gbádùn rẹ̀ gan-an débi pé òún pinnu láti tún padà wá lẹ́yìn ọdún kan.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń lo àkókò ìsinmi fún rírìnrìn àjò lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ àwọn Kristẹni tàbí láti tẹ̀ síwájú sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìtagbangba wọn. Àwọn kan ń lo àkókò ìsinmi wọn láti ṣiṣẹ́ ní orílé-iṣẹ́ tàbí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n sì ń gbádùn ìrírí náà. Lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí máa ń kọ lẹ́tà ìmọrírì fún àǹfààní yìí.

Bẹ́ẹ̀ ni, àkókò ìsinmi lè jẹ́ èyí tí ó lárinrin jù lọ, àní ọ̀sẹ̀ dídára jù lọ láàárín ọdún. Abájọ tí àwọn ọmọ máa ń ṣírò ọjọ́ tí ìsinmi yóò bẹ̀rẹ̀! Síbẹ̀, àwọn ohun kan wà tí ó yẹ kí o ṣọ́ra fún. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò ṣàlàyé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́