Gbádùn Ìsinmi Láìkábàámọ̀!
NÍGBÀ tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ ọmọ America kan, tí ń gbé Europe nísinsìnyí, nípa bí ó ṣe gbádùn ìbẹ̀wò rẹ̀ sí ibi ìsinmi kan tí ó gbajúmọ̀, ó dáhùn pé: “Ó ní láti jẹ́ pé ó ti lẹ́wà kí àwọn ènìyàn tó dé.” O ha ti ní irú ìmọ̀lára rẹ̀ yìí rí? Àwọn hòtẹ́ẹ̀lì àti ilé ijó dísíkò tí ó tò lọ, etíkun tí ó kún àkúnya, tí a ba àyíká rẹ̀ jẹ́, àti àwọn rédíò tí ń bú gbẹ̀ẹ̀, kì í ṣe ohun tí gbogbo ènìyàn lè rò mọ́ ibi ìsinmi tí ó gbádùn mọ́ni.
Ó bani nínú jẹ́ pé, ìsinmi kì í sábà rí bí a ti fojú sọ́nà fún un. Dípò sísọ agbára wa dọ̀tun, wọ́n máa ń lò wá lépo dà nù ni; dípò fífún wa lókun, nígbà míràn, wọ́n máa ń mú wa fẹ́ ìsinmi sí i ni. Nípa bẹ́ẹ̀, ìbéèrè náà wá bá a mu pé, Báwo ni a ṣe lè gbádùn ìsinmi láìkábàámọ̀?
Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì
Bí àwọn èròjà oúnjẹ wa, àwọn ìsinmi ń mú àwọn ìyọrísí dídára jù lọ wá tí a bá lò wọ́n níwọ̀nba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbésí ayé arìnrìn àjò lemọ́lemọ́ tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo lè dà bí èyí tí ń fani mọ́ra, kò sí ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kì í sì í yọrí sí ayọ̀ tòótọ́.
Ní pàtàkì, ni ìsopọ̀ pẹ̀lú ìsinmi, níná owó ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe kókó. Fi tìṣọ́ratìṣọ́ra ṣètò kí o tó gbéra, sì gbìyànjú láti má ṣe ná ju iye tí o wéwèé. Yẹra fún jíjuwọ́ sílẹ̀ fún àwọn ìfilọni àrà ọ̀tọ̀ tí àwọn ilé iṣẹ́ aṣojú ìrìn àjò tí ń rọ̀ ọ́ láti “gbádùn nísinsìnyí, kí o sì sanwó tó bá yá” ń ṣe.
Bákan náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn ewu ọjọ́ iwájú gbà ọ́ lọ́kàn débi tí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́nà àdánidá àti ìgbáládùn tí ń mú kí ìsinmi wuni gan-an yóò fi di èyí tí a tẹ̀ rì. Ní àfikún, ìwọ̀ntúnwọ̀nsì tí ó wà déédéé kan mímọ ewu gíga jù lọ tí ó lè mú kí a kábàámọ̀ ìsinmi wa. Kò ní ohunkóhun láti ṣe pẹ̀lú ìjàm̀bá, àìsàn, tàbí ìwà ọ̀daràn ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ipò ìbátan ara ẹni.
Mímú Àjọṣepọ̀ Rere Dàgbà
Àkókò ìsinmi pẹ̀lú ìdílé tàbí àwọn ọ̀rẹ́ lè mú ìdè ìfẹ́ lókun. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àkókò ìsinmi lè fa ìpalára nínú ipò ìbátan kan, tí ó lè ṣòro láti ṣàtúnṣe tí ó bá yá. Akọ̀ròyìn Lance Morrow sọ pé: “Ewu gidi tí ó wà nínú ìsinmi wà nínú agbára rẹ̀ láti pa gbogbo hílàhílo ìdílé pọ̀ di ìran àpéwò. . . . Nígbà tí àwọn ènìyàn bá ń ṣiṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn, wọ́n ní iṣẹ́, ipa, ọ̀rẹ́ àti iṣẹ́ àṣetúnṣe láti gba ara wọn lọ́wọ́ rẹ̀, kí wọ́n sì fi ara fún èrò ìmọ̀lára pátápátá. Ní àyíká ilé tí a ń lò fún ète ìsinmi, àwọn ọ̀ràn ìdílé tí a ti bò mọ́lẹ̀ fún 20 ọdún lè hú jáde tipátipá.”
Nítorí náà, kí o tó lọ fún ìsinmi, pinnu láti mú kí ó jẹ́ ìrírí alárinrin. Rántí pé ohun tí olúkúlùkù fẹ́ lọ́kàn yàtọ̀. Àwọn ọmọ lè máa wá ìrírí tí ó mìnrìngìndìn, àwọn òbí sì lè máa wá ìdẹ̀ra. Ṣe tán láti jọ̀wọ́ àwọn ohun tí o nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ ní ti ohun tí ó yẹ láti ṣe àti ibi tí ó yẹ láti lọ. Bí ó bá tọ́, tí ó sì bọ́gbọ́n mu, gbà láti fàyè gba ẹnì kọ̀ọ̀kan láti lépa ohun tí ó fa ọkàn ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ra jù lọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kọ́ láti ṣàmúlò àwọn ànímọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run lójoojúmọ́ jálẹ̀ ọdún, kò sì gbọdọ̀ ṣòro láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ nígbà ìsinmi rẹ.—Gálátíà 5:22, 23.
Níwọ̀n bí wíwà ní ipò ìbátan rere pẹ̀lú ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ ti ṣe pàtàkì, ipò ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọ́run tilẹ̀ ṣe pàtàkì jù lọ. Nígbà ìsinmi, a sábà máa ń pàdé àwọn ènìyàn tí wọn kò ṣàjọpín ojú ìwòye Kristẹni wa nípa Ọlọ́run àti àwọn ohun tí ó béèrè fún. Kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú wọn—bóyá lílọ sí àwọn ibi eré ìnàjú tí ń gbé ìbéèrè dìde pẹ̀lú wọn látìgbàdégbà—lè ṣamọ̀nà sí àwọn ìyọrísí tí ó kún fún àbámọ̀. Rántí pé Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà. Àwọn ẹgbẹ́ búburú a máa ba àwọn àṣà ìhùwà wíwúlò jẹ́.”—Kọ́ríńtì Kìíní 15:33.
Nígbà tí o bá lọ fún ìsinmi, bí o bá ṣàkíyèsí nínú ara rẹ, ìfẹ́ ọkàn láti yẹra fún àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n àti àṣà Kristẹni, fi ọgbọ́n kojú irú àìlera bẹ́ẹ̀, sì béèrè fún ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá láti gbógun ti ìfẹ́ ọkàn yẹn!
Kí Ni A Ń Gbé Lárugẹ?
Àwọn ènìyàn tí wọn kò mú ìgbésí ayé wọn bá àwọn ìlànà Kristẹni mu lè lérò pé bí àwọ́n bá wà ní àkókò ìsinmi, kò sí ìwà tí àyè kò gbà. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Europe, òwò ńlá ni ìrìn àjò nítorí ìbálòpọ̀, àwọn ilé iṣẹ́ aṣojú arìnrìn àjò kan tilẹ̀ ń gbé e lárugẹ. Ìwé agbéròyìnjáde The European kọ pé, ‘tipẹ́tipẹ́ ni gbogbo ènìyàn ti mọ ohun tí ń dójú tini tí àwọn ọkùnrin ilẹ̀ Europe ń ṣe ní àwọn ìlú ńlá kan tí a ń wọ̀ sí ní Éṣíà.’ Nígbà tí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Germany náà, Der Spiegel, ń tọ́ka sí orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà, ó fojú díwọ̀n pé nǹkan bí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn àlejò ọkùnrin ni wọ́n jẹ́ “arìnrìn àjò nítorí ìbálòpọ̀.”
Àwọn obìnrin arìnrìn àjò afẹ́ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin ẹlẹgbẹ́ wọn. Ọkọ̀ òfuurufú ilẹ̀ Germany tí a háyà, tí ó jẹ́ àkànṣe fún fífò lọ sí agbègbè Caribbean, fojú díwọ̀n pé ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn obìnrin tí ń wọ ọkọ̀ rẹ̀ ní ń lọ fún ìsinmi níbẹ̀ fún ète tààràtà ti ìbálòpọ̀ tí kò tọ́. Ìwé agbéròyìnjáde The European fa ọ̀rọ̀ akọ̀ròyìn Germany kan yọ, tí ó sọ pé: “Wọ́n rí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rírọrùn tí kò sì díjú láti ṣeré amóríyá—eré àṣedárayá ṣíṣàjèjì.”
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò wo ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ṣíṣètẹ́wọ́gbà láti ṣeré amóríyá. Ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn ìlànà Kristẹni, ó sì kún fọ́fọ́ fún ewu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi gbogbo ni àwọn ènìyàn ti mọ ewu rẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn wulẹ̀ ń gbìyànjú láti yẹra fún àwọn àbájáde rẹ̀ dípò kí wọ́n kọ ṣíṣe é. Àpẹẹrẹ kan ni ti ìpolówó ọjà tí a ń rí nínú àwọn ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Germany tí ń fi agbòòrùn kan àti àga etíkun méjì tí ó ṣófo hàn. Àkọlé ibẹ̀ kà pé: “Re àjò láìséwu, má sì ṣe gbé àrùn AIDS bọ̀.”
Àbáyọrí arínilára kan nípa ìrìn àjò nítorí ìbálòpọ̀ ni ti ìṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọmọdé. Lọ́nà tí ó gbàfiyèsí, ní 1993, ìjọba ilẹ̀ Germany gbé òfin kan jáde tí ń mú kí àwọn ará Germany tí wọ́n bá jẹ̀bi níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọdé yẹ fún ìjìyà—kódà nígbà tí wọ́n bá lọ fún ìsinmi ní àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè. Bí ó ti wù kí ó rí, títí di ìsinsìnyí, àwọn àbájáde rere kò tó nǹkan. Bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe ti jẹ́ orísun ìbànújẹ́ tí ń peléke sí i—ó sì ṣì jẹ́ bẹ́ẹ̀—ní àwùjọ ènìyàn.
Jẹ́ Kí Ìsinmi Jẹ́ Àkókò Tí Ó Lérè
Kíkàwé, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti lílọ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni jẹ́ ìgbòkègbodò alárinrin, tí ó lérè fún àwọn Kristẹni tòótọ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ń tiraka láti rí àkókò tí ó tó láti ṣe nǹkan dé ìwọ̀n àyè tí wọ́n bá fẹ́. Ìgbà wo ló tún lè dára jù láti ṣàṣeyọrí èyí ju ìgbà tí ènìyàn bá wà ní ìsinmi, tí wọn kò sí lábẹ́ ìkálọ́wọ́kò líle koko tí agogo fi wọ́n sí?
Lótìítọ́, ìsinmi tí ó tẹ́ni lọ́rùn, tí ó sì mú ọwọ́ ẹni dí lè ṣàìfàyè gbà ọ́ láti lépa àwọn ire ti Kristẹni tó bí o ti máa ń ṣe. Àmọ́, kí ló dé tí o kò gbìyànjú láti fi, ó kéré tán, àyè díẹ̀ sílẹ̀ fún ìgbòkègbodò tẹ̀mí? Èyí yóò ṣì fi àyè sílẹ̀ fún fàájì. Ní ti gidi, àwọn kan tilẹ̀ lo àǹfààní àfikún àkókò tí wọ́n ní nígbà ìsinmi, láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, “aláyọ̀ ni àwọn wọnnì tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3.
Láìpẹ́, ìwọ pẹ̀lú lè fẹ́ láti lọ fún ìsinmi. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, rí i dájú pé o gbádùn rẹ̀! Má dààmú jù nípa àwọn ewu tí ó lè wà níwájú, àmọ́, lo àwọn ìṣọ́ra yíyẹ. Fi àwọn àbá bí èyí tí ó wà nínú àpótí ojú ìwé yìí sọ́kàn. Lẹ́yìn gbogbo rẹ̀, darí sílé pẹ̀lú ìtura, ìbàlẹ̀ ara, àti ìfojúsọ́nà láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìgbòkègbodò pàtàkì nínú ìgbésí ayé. Láìpẹ́ láìjìnnà, ìsinmi ti tán, àmọ́, díẹ̀ lára àwọn ìrántí ṣíṣeyebíye tí a ní máa ń wà lọ́kàn títí láé. Ẹ wo bí ó ti ṣeyebíye tó—ìsinmi tí a gbádùn láìkábàámọ̀!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Ìmọ̀ràn Díẹ̀ Nípa Ìsinmi
Gbógun Ti Ìwà Ọ̀daràn
1. Ṣètò kí ẹnì kan máa bójú tó nǹkan nílé.
2. Jìnnà sí àwọn agbègbè tí a sábà máa ń wò gẹ́gẹ́ bí ibi eléwu.
3. Wà lójúfò nítorí àwọn jáwójáwó, tọ́jú owó sí ibi tí ó láàbò ní ara rẹ, sì fi owó tí ó kù pa mọ́ sí ibi tí ó láàbò níbi tí o dé sí.
4. Ṣọ́ra fún àwọn àjèjì tí ń nawọ́ ìrànlọ́wọ́ tí a kò béèrè fún síni.
Dènà Ìjàm̀bá
1. Bí o bá ń wakọ̀, wà lójúfò, sì máa dúró sinmi léraléra.
2. Bí o bá wà ní hòtẹ́ẹ̀lì tàbí nínú ọkọ̀ òfuurufú, fìṣọ́ra kíyè sí àwọn ìṣètò fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì.
3. Fi àyè sílẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ bá gúnlẹ̀ láti mú ara bá ipò àdúgbò mu ṣáájú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ agbára.
4. Ní aṣọ, bàtà, àti àwọn ohun èèlò yíyẹ fún àwọn ìgbòkègbodò rẹ.
Rí I Pé O Kò Ṣàìsàn
1. Béèrè lọ́wọ́ dókítà rẹ fún ìmọ̀ràn nípa àìní fún àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tàbí egbòogi tí ó bá wà.
2. Gbé àpótí egbòogi tí ó ní àwọn egbòogi tí ó pọn dandan dání.
3. Sinmi dáadáa, sì ṣọ́ra nípa jíjẹ àti mímu rẹ.
4. Jẹ́ kí àwọn àkọsílẹ̀ nípa àìní rẹ ní ti ìtọ́jú àti ìdàníyàn ìlera máa wà lára rẹ ní gbogbo ìgbà.
Mú Àjọṣepọ̀ Láyọ̀
1. Fi ìfẹ́ àti ìgbatẹnirò hàn fún àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ.
2. Mú kí àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n àjọṣepọ̀ wà ní ipò gíga.
3. Má ṣe fàyè gba àwọn onísinmi mìíràn láti tì ọ́ gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí o kà sí èyí tí ń gbé ìbéèrè dìde.
4. Fi àkókò díẹ̀ sílẹ̀ láti bójú tó àwọn àìní tẹ̀mí.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Yan àwọn ìgbòkègbodò gbígbámúṣé tí o bá lọ fún ìsinmi